×

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba fe kirun, 5:6 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah Al-Ma’idah ⮕ (5:6) ayat 6 in Yoruba

5:6 Surah Al-Ma’idah ayat 6 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ma’idah ayat 6 - المَائدة - Page - Juz 6

﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قُمۡتُمۡ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ فَٱغۡسِلُواْ وُجُوهَكُمۡ وَأَيۡدِيَكُمۡ إِلَى ٱلۡمَرَافِقِ وَٱمۡسَحُواْ بِرُءُوسِكُمۡ وَأَرۡجُلَكُمۡ إِلَى ٱلۡكَعۡبَيۡنِۚ وَإِن كُنتُمۡ جُنُبٗا فَٱطَّهَّرُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُم مِّنۡهُۚ مَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيَجۡعَلَ عَلَيۡكُم مِّنۡ حَرَجٖ وَلَٰكِن يُرِيدُ لِيُطَهِّرَكُمۡ وَلِيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴾
[المَائدة: 6]

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti e ba fe kirun, e we oju yin ati owo yin titi de igunpa. E fi omi pa ori yin. E we ese yin titi de kokose mejeeji. Ti e ba ni jannaba lara, e we iwe imora. Ti e ba je alaisan, tabi e n be lori irin-ajo tabi eni kan ninu yin de lati ile igbonse, tabi e sunmo obinrin, ti e o ba ri omi, nigba naa ki e fi erupe mimo se tayamomu. E fi pa oju yin ati owo yin lara re. Allahu ko fe lati ko wahala ba yin, sugbon O fe lati fo yin mo. O si fe se asepe idera Re fun yin nitori ki e le dupe

❮ Previous Next ❯

ترجمة: ياأيها الذين آمنوا إذا قمتم إلى الصلاة فاغسلوا وجوهكم وأيديكم إلى المرافق, باللغة اليوربا

﴿ياأيها الذين آمنوا إذا قمتم إلى الصلاة فاغسلوا وجوهكم وأيديكم إلى المرافق﴾ [المَائدة: 6]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ̀ ń bẹ lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek