Quran with Yoruba translation - Surah Al-hadid ayat 13 - الحدِيد - Page - Juz 27
﴿يَوۡمَ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتُ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱنظُرُونَا نَقۡتَبِسۡ مِن نُّورِكُمۡ قِيلَ ٱرۡجِعُواْ وَرَآءَكُمۡ فَٱلۡتَمِسُواْ نُورٗاۖ فَضُرِبَ بَيۡنَهُم بِسُورٖ لَّهُۥ بَابُۢ بَاطِنُهُۥ فِيهِ ٱلرَّحۡمَةُ وَظَٰهِرُهُۥ مِن قِبَلِهِ ٱلۡعَذَابُ ﴾
[الحدِيد: 13]
﴿يوم يقول المنافقون والمنافقات للذين آمنوا انظرونا نقتبس من نوركم قيل ارجعوا﴾ [الحدِيد: 13]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ní ọjọ́ tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin yóò wí fún àwọn t’ó gbàgbọ́ pé: "Ẹ dúró fún wa ná, ẹ jẹ́ kí á mú nínú ìmọ́lẹ̀ yín." A óò sọ fún wọn pé: "Ẹ padà s’ẹ́yìn yín, kí ẹ lọ mú ìmọ́lẹ̀.” Wọ́n sì máa fi ògiri kan, t’ó ní ìlẹ̀kùn sáàrin wọn. Ìkẹ́ wà nínú rẹ̀, ìyà sì wà ní òde rẹ̀ ní ọwọ́ iwájú rẹ̀ |