Quran with Yoruba translation - Surah Al-An‘am ayat 122 - الأنعَام - Page - Juz 8
﴿أَوَمَن كَانَ مَيۡتٗا فَأَحۡيَيۡنَٰهُ وَجَعَلۡنَا لَهُۥ نُورٗا يَمۡشِي بِهِۦ فِي ٱلنَّاسِ كَمَن مَّثَلُهُۥ فِي ٱلظُّلُمَٰتِ لَيۡسَ بِخَارِجٖ مِّنۡهَاۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلۡكَٰفِرِينَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴾
[الأنعَام: 122]
﴿أو من كان ميتا فأحييناه وجعلنا له نورا يمشي به في الناس﴾ [الأنعَام: 122]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ǹjẹ́ ẹni tí (àfiwé rẹ̀) jẹ́ òkú (ìyẹn, aláìgbàgbọ́), tí A sọ di alààyè (nípa pé ó gba ’Islām), tí A sì fún un ní ìmọ́lẹ̀ (ìyẹn, ìmọ̀ ẹ̀sìn), tí ó sì ń lò ó láààrin àwọn ènìyàn, (ǹjẹ́) ó dà bí ẹni tí àfiwé tirẹ̀ jẹ́ (ẹni tí) ń bẹ nínú àwọn òkùnkùn (àìgbàgbọ́), tí kò sì jáde kúrò nínú rẹ̀? Báyẹn ni wọ́n ti ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ |