×

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin 60:10 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah Al-Mumtahanah ⮕ (60:10) ayat 10 in Yoruba

60:10 Surah Al-Mumtahanah ayat 10 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah Al-Mumtahanah ayat 10 - المُمتَحنَة - Page - Juz 28

﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا جَآءَكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ مُهَٰجِرَٰتٖ فَٱمۡتَحِنُوهُنَّۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِهِنَّۖ فَإِنۡ عَلِمۡتُمُوهُنَّ مُؤۡمِنَٰتٖ فَلَا تَرۡجِعُوهُنَّ إِلَى ٱلۡكُفَّارِۖ لَا هُنَّ حِلّٞ لَّهُمۡ وَلَا هُمۡ يَحِلُّونَ لَهُنَّۖ وَءَاتُوهُم مَّآ أَنفَقُواْۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّۚ وَلَا تُمۡسِكُواْ بِعِصَمِ ٱلۡكَوَافِرِ وَسۡـَٔلُواْ مَآ أَنفَقۡتُمۡ وَلۡيَسۡـَٔلُواْ مَآ أَنفَقُواْۚ ذَٰلِكُمۡ حُكۡمُ ٱللَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡۖ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ﴾
[المُمتَحنَة: 10]

Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba yin, ti won gbe ilu awon alaigbagbo ju sile fun aabo esin won, e bi won ni ibeere. Allahu nimo julo nipa igbagbo won. Nitori naa, ti e ba mo won si onigbagbo ododo, e ma se da won pada si odo awon alaigbagbo. Awon onigbagbo ododo lobinrin ko letoo si won. Awon alaigbagbo lokunrin ko si letoo si won. E fun (awon alaigbagbo lokunrin) ni owo ti won na (ni owo-ori obinrin naa). Ko si si ese fun eyin naa pe ki e fe won nigba ti e ba ti fun (awon obinrin wonyi) ni owo-ori won. E ma se fi owo-ori awon obinrin yin ti won je alaigbagbo mu won mole (gege bi iyawo yin lai je pe won gba ’Islam pelu yin). E beere ohun ti e na (ni owo-ori won lowo alaigbagbo lokunrin ti won sa lo ba). Ki awon (alaigbagbo lokunrin naa) beere ohun ti awon naa na (ni owo-ori won lowo eyin ti onigbagbo ododo lobinrin sa wa ba). Iyen ni idajo Allahu. O si n dajo laaarin yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon

❮ Previous Next ❯

ترجمة: ياأيها الذين آمنوا إذا جاءكم المؤمنات مهاجرات فامتحنوهن الله أعلم بإيمانهن فإن, باللغة اليوربا

﴿ياأيها الذين آمنوا إذا جاءكم المؤمنات مهاجرات فامتحنوهن الله أعلم بإيمانهن فإن﴾ [المُمتَحنَة: 10]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá ba yín, tí wọ́n gbé ìlú àwọn aláìgbàgbọ́ jù sílẹ̀ fún ààbò ẹ̀sìn wọn, ẹ bi wọ́n ní ìbéèrè. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, tí ẹ bá mọ̀ wọ́n sí onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin kò lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Ẹ fún (àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin) ní owó tí wọ́n ná (ní owó-orí obìnrin náà). Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà pé kí ẹ fẹ́ wọn nígbà tí ẹ bá ti fún (àwọn obìnrin wọ̀nyí) ní owó-orí wọn. Ẹ má ṣe fi owó-orí àwọn obìnrin yín tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mú wọn mọ́lẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó yín láì jẹ́ pé wọ́n gba ’Islām pẹ̀lú yín). Ẹ bèèrè ohun tí ẹ ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin tí wọ́n sá lọ bá). Kí àwọn (aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin náà) bèèrè ohun tí àwọn náà ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ ẹ̀yin tí onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin sá wá bá). Ìyẹn ni ìdájọ́ Allāhu. Ó sì ń dájọ́ láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek