يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا عَدُوِّي وَعَدُوَّكُمْ أَوْلِيَاءَ تُلْقُونَ إِلَيْهِم بِالْمَوَدَّةِ وَقَدْ كَفَرُوا بِمَا جَاءَكُم مِّنَ الْحَقِّ يُخْرِجُونَ الرَّسُولَ وَإِيَّاكُمْ ۙ أَن تُؤْمِنُوا بِاللَّهِ رَبِّكُمْ إِن كُنتُمْ خَرَجْتُمْ جِهَادًا فِي سَبِيلِي وَابْتِغَاءَ مَرْضَاتِي ۚ تُسِرُّونَ إِلَيْهِم بِالْمَوَدَّةِ وَأَنَا أَعْلَمُ بِمَا أَخْفَيْتُمْ وَمَا أَعْلَنتُمْ ۚ وَمَن يَفْعَلْهُ مِنكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ (1) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ota Mi ati ota yin ni ore ti e oo maa fi ife han si. Won kuku ti sai gbagbo ninu ohun ti o de ba yin ninu ododo. Won yo Ojise ati eyin naa kuro ninu ilu nitori pe, e gbagbo ninu Allahu, Oluwa yin. Ti eyin ba jade fun ogun nitori esin Mi ati nitori wiwa iyonu Mi, (se) eyin yoo tun maa ni ife koro si won ni! Emi si nimo julo nipa ohun ti e fi pamo ati ohun ti e fi han. Enikeni ti o ba se bee ninu yin, dajudaju o ti sina kuro loju ona taara |
إِن يَثْقَفُوكُمْ يَكُونُوا لَكُمْ أَعْدَاءً وَيَبْسُطُوا إِلَيْكُمْ أَيْدِيَهُمْ وَأَلْسِنَتَهُم بِالسُّوءِ وَوَدُّوا لَوْ تَكْفُرُونَ (2) Ti owo won ba ba yin, won maa di ota fun yin. Won yo si fi owo won ati ahon won nawo aburu si yin. Won si maa fe ki o je pe e di alaigbagbo |
لَن تَنفَعَكُمْ أَرْحَامُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُمْ ۚ يَوْمَ الْقِيَامَةِ يَفْصِلُ بَيْنَكُمْ ۚ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ (3) Awon ebi yin ati awon omo yin ko le se yin ni anfaani; ni Ojo Ajinde ni Allahu maa sepinya laaarin yin. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |
قَدْ كَانَتْ لَكُمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ فِي إِبْرَاهِيمَ وَالَّذِينَ مَعَهُ إِذْ قَالُوا لِقَوْمِهِمْ إِنَّا بُرَآءُ مِنكُمْ وَمِمَّا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ كَفَرْنَا بِكُمْ وَبَدَا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةُ وَالْبَغْضَاءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤْمِنُوا بِاللَّهِ وَحْدَهُ إِلَّا قَوْلَ إِبْرَاهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسْتَغْفِرَنَّ لَكَ وَمَا أَمْلِكُ لَكَ مِنَ اللَّهِ مِن شَيْءٍ ۖ رَّبَّنَا عَلَيْكَ تَوَكَّلْنَا وَإِلَيْكَ أَنَبْنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ (4) Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara (Anabi) ’Ibrohim ati awon t’o wa pelu re. Nigba ti won so fun ijo won pe: "Dajudaju awa yowo-yose kuro ninu oro yin ati ohun ti e n josin fun leyin Allahu. A tako yin. Ota ati ikorira si ti han laaarin wa titi laelae ayafi igba ti e ba to gbagbo ninu Allahu nikan soso. - Afi oro ti (Anabi) ’Ibrohim so fun baba re pe: "Dajudaju mo maa toro aforijin fun o, emi ko si ni ikapa kini kan fun o lodo Allahu. - Oluwa wa, Iwo l’a gbarale. Odo Re l’a seri pada si (nipa ironupiwada). Odo Re si ni abo eda |
رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا وَاغْفِرْ لَنَا رَبَّنَا ۖ إِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (5) Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun awon t’o sai gbagbo. Forijin wa, Oluwa wa. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon |
لَقَدْ كَانَ لَكُمْ فِيهِمْ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِّمَن كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الْآخِرَ ۚ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ اللَّهَ هُوَ الْغَنِيُّ الْحَمِيدُ (6) Dajudaju awokose rere ti wa fun yin ni ara won fun eni t’o n reti (esan) Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba peyin da, dajudaju Allahu, Oun ni Oloro, Eleyin |
۞ عَسَى اللَّهُ أَن يَجْعَلَ بَيْنَكُمْ وَبَيْنَ الَّذِينَ عَادَيْتُم مِّنْهُم مَّوَدَّةً ۚ وَاللَّهُ قَدِيرٌ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (7) O le je pe Allahu yoo fi ife si aarin eyin ati awon ti e mu ni ota ninu won (iyen, nigba ti won ba di musulumi). Allahu ni Alagbara. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
لَّا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ لَمْ يُقَاتِلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَلَمْ يُخْرِجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ أَن تَبَرُّوهُمْ وَتُقْسِطُوا إِلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ (8) Allahu ko ko fun yin nipa awon ti ko gbe ogun ti yin nipa esin, ti won ko si le yin jade kuro ninu ilu yin, pe ki e se daadaa si won, ki e si se deede si won. Dajudaju Allahu feran awon oluse-deede |
إِنَّمَا يَنْهَاكُمُ اللَّهُ عَنِ الَّذِينَ قَاتَلُوكُمْ فِي الدِّينِ وَأَخْرَجُوكُم مِّن دِيَارِكُمْ وَظَاهَرُوا عَلَىٰ إِخْرَاجِكُمْ أَن تَوَلَّوْهُمْ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُمْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ (9) Ohun ti Allahu ko fun yin nipa awon t’o gbogun ti yin ninu esin, ti won si le yin jade kuro ninu ilu yin, ti won tun se iranlowo (fun awon ota yin) lati le yin jade, ni pe (O ko fun yin) lati mu won ni ore. Enikeni ti o ba mu won ni ore, awon wonyen, awon ni alabosi |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا جَاءَكُمُ الْمُؤْمِنَاتُ مُهَاجِرَاتٍ فَامْتَحِنُوهُنَّ ۖ اللَّهُ أَعْلَمُ بِإِيمَانِهِنَّ ۖ فَإِنْ عَلِمْتُمُوهُنَّ مُؤْمِنَاتٍ فَلَا تَرْجِعُوهُنَّ إِلَى الْكُفَّارِ ۖ لَا هُنَّ حِلٌّ لَّهُمْ وَلَا هُمْ يَحِلُّونَ لَهُنَّ ۖ وَآتُوهُم مَّا أَنفَقُوا ۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيْكُمْ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَا آتَيْتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ ۚ وَلَا تُمْسِكُوا بِعِصَمِ الْكَوَافِرِ وَاسْأَلُوا مَا أَنفَقْتُمْ وَلْيَسْأَلُوا مَا أَنفَقُوا ۚ ذَٰلِكُمْ حُكْمُ اللَّهِ ۖ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (10) Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba yin, ti won gbe ilu awon alaigbagbo ju sile fun aabo esin won, e bi won ni ibeere. Allahu nimo julo nipa igbagbo won. Nitori naa, ti e ba mo won si onigbagbo ododo, e ma se da won pada si odo awon alaigbagbo. Awon onigbagbo ododo lobinrin ko letoo si won. Awon alaigbagbo lokunrin ko si letoo si won. E fun (awon alaigbagbo lokunrin) ni owo ti won na (ni owo-ori obinrin naa). Ko si si ese fun eyin naa pe ki e fe won nigba ti e ba ti fun (awon obinrin wonyi) ni owo-ori won. E ma se fi owo-ori awon obinrin yin ti won je alaigbagbo mu won mole (gege bi iyawo yin lai je pe won gba ’Islam pelu yin). E beere ohun ti e na (ni owo-ori won lowo alaigbagbo lokunrin ti won sa lo ba). Ki awon (alaigbagbo lokunrin naa) beere ohun ti awon naa na (ni owo-ori won lowo eyin ti onigbagbo ododo lobinrin sa wa ba). Iyen ni idajo Allahu. O si n dajo laaarin yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
وَإِن فَاتَكُمْ شَيْءٌ مِّنْ أَزْوَاجِكُمْ إِلَى الْكُفَّارِ فَعَاقَبْتُمْ فَآتُوا الَّذِينَ ذَهَبَتْ أَزْوَاجُهُم مِّثْلَ مَا أَنفَقُوا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ الَّذِي أَنتُم بِهِ مُؤْمِنُونَ (11) Ti kini kan lati odo awon iyawo yin ba bo mo yin lowo si odo awon alaigbagbo, ti e si kore ogun, e fun awon ti iyawo won sa lo ni iru odiwon ohun ti won na (ni owo-ori). Ki e si beru Allahu, Eni ti eyin ni igbagbo ododo ninu Re |
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ إِذَا جَاءَكَ الْمُؤْمِنَاتُ يُبَايِعْنَكَ عَلَىٰ أَن لَّا يُشْرِكْنَ بِاللَّهِ شَيْئًا وَلَا يَسْرِقْنَ وَلَا يَزْنِينَ وَلَا يَقْتُلْنَ أَوْلَادَهُنَّ وَلَا يَأْتِينَ بِبُهْتَانٍ يَفْتَرِينَهُ بَيْنَ أَيْدِيهِنَّ وَأَرْجُلِهِنَّ وَلَا يَعْصِينَكَ فِي مَعْرُوفٍ ۙ فَبَايِعْهُنَّ وَاسْتَغْفِرْ لَهُنَّ اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (12) Iwo Anabi, nigba ti awon onigbagbo ododo lobinrin ba wa ba o, ti won n se adehun fun o pe awon ko nii fi kini kan sebo si Allahu, awon ko nii jale, awon ko nii se sina, awon ko nii pa omo won, awon ko nii mu adapa iro wa, adapa iro ti won n mu wa laaarin owo won ati ese won (iyen ni gbigbe oyun oloyun fun oko won), awon ko si nii yapa re nibi nnkan daadaa, nigba naa ba won se adehun, ki o si ba won toro aforijin lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَوَلَّوْا قَوْمًا غَضِبَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ قَدْ يَئِسُوا مِنَ الْآخِرَةِ كَمَا يَئِسَ الْكُفَّارُ مِنْ أَصْحَابِ الْقُبُورِ (13) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu ijo kan ti Allahu ti binu si ni ore. Dajudaju won ti soreti nu nipa orun, gege bi awon alaigbagbo t’o wa ninu saree (se soreti nu nipa ike) |