Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 146 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿سَأَصۡرِفُ عَنۡ ءَايَٰتِيَ ٱلَّذِينَ يَتَكَبَّرُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَإِن يَرَوۡاْ كُلَّ ءَايَةٖ لَّا يُؤۡمِنُواْ بِهَا وَإِن يَرَوۡاْ سَبِيلَ ٱلرُّشۡدِ لَا يَتَّخِذُوهُ سَبِيلٗا وَإِن يَرَوۡاْ سَبِيلَ ٱلۡغَيِّ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلٗاۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ عَنۡهَا غَٰفِلِينَ ﴾
[الأعرَاف: 146]
﴿سأصرف عن آياتي الذين يتكبرون في الأرض بغير الحق وإن يروا كل﴾ [الأعرَاف: 146]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Èmi yóò ṣẹ́rí àwọn t’ó ń ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ kúrò níbi àwọn àmì Mi. Tí wọ́n bá sì rí gbogbo àmì, wọn kò níí gbà á gbọ́. Tí wọ́n bá rí ọ̀nà ìmọ̀nà, wọn kò níí mú un ní ọ̀nà. Tí wọ́n bá sì rí ọ̀nà ìṣìnà, wọn yóò mú un ní ọ̀nà. Ìyẹn nítorí pé wọ́n pe àwọn àmì Wa nírọ́; wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀ |