Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 150 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿وَلَمَّا رَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ غَضۡبَٰنَ أَسِفٗا قَالَ بِئۡسَمَا خَلَفۡتُمُونِي مِنۢ بَعۡدِيٓۖ أَعَجِلۡتُمۡ أَمۡرَ رَبِّكُمۡۖ وَأَلۡقَى ٱلۡأَلۡوَاحَ وَأَخَذَ بِرَأۡسِ أَخِيهِ يَجُرُّهُۥٓ إِلَيۡهِۚ قَالَ ٱبۡنَ أُمَّ إِنَّ ٱلۡقَوۡمَ ٱسۡتَضۡعَفُونِي وَكَادُواْ يَقۡتُلُونَنِي فَلَا تُشۡمِتۡ بِيَ ٱلۡأَعۡدَآءَ وَلَا تَجۡعَلۡنِي مَعَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ ﴾
[الأعرَاف: 150]
﴿ولما رجع موسى إلى قومه غضبان أسفا قال بئسما خلفتموني من بعدي﴾ [الأعرَاف: 150]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sì padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ fi rólé dè mí lẹ́yìn mi burú. Ṣé ẹ ti kánjú pa àṣẹ Olúwa yín tì ni?" Ó sì ju àwọn wàláà sílẹ̀, ó gbá orí arákùnrin rẹ̀ mú, ó sì ń wọ́ ọ mọ́ra. (Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi ò, dájúdájú àwọn ènìyàn ni wọ́n fojú tínrín mi, wọ́n sì fẹ́ẹ̀ pa mí. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ̀ mí. Má sì ṣe mú mi mọ́ ìjọ alábòsí.” |