Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 172 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿وَإِذۡ أَخَذَ رَبُّكَ مِنۢ بَنِيٓ ءَادَمَ مِن ظُهُورِهِمۡ ذُرِّيَّتَهُمۡ وَأَشۡهَدَهُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَلَسۡتُ بِرَبِّكُمۡۖ قَالُواْ بَلَىٰ شَهِدۡنَآۚ أَن تَقُولُواْ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ إِنَّا كُنَّا عَنۡ هَٰذَا غَٰفِلِينَ ﴾
[الأعرَاف: 172]
﴿وإذ أخذ ربك من بني آدم من ظهورهم ذريتهم وأشهدهم على أنفسهم﴾ [الأعرَاف: 172]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ādam, Ó fa àrọ́mọdọ́mọ wọn jáde láti (ìbàdí ní) ẹ̀yìn (bàbá ńlá) wọn, Ó sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí lórí ara wọn pé: “Ṣé Èmi kọ́ ni Olúwa yín ni?” Wọ́n sọ pé: “Rárá – (Ìwọ ni Olúwa wa) - a jẹ́rìí sí i.” Nítorí kí ẹ má baà sọ ní Ọjọ́ Àjíǹdé pé: "Dájúdájú àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa èyí |