Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 185 - الأعرَاف - Page - Juz 9
﴿أَوَلَمۡ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ وَأَنۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَدِ ٱقۡتَرَبَ أَجَلُهُمۡۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ ﴾
[الأعرَاف: 185]
﴿أو لم ينظروا في ملكوت السموات والأرض وما خلق الله من شيء﴾ [الأعرَاف: 185]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀? “ọ̀rọ̀ wo nínú ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ ikú wọn bá dé tàbí lẹ́yìn tí ọjọ́ Àjíǹde bá ṣẹlẹ̀? Bí wọ́n bá padà gba ọ̀rọ̀ al-Ƙu’ān gbọ́ lọ́jọ́ ikú wọn tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde kò lè wúlò fún wọn mọ́ ọ̀rọ̀ irọ́ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí al-Ƙur’ān ti mú ọ̀rọ̀ òdodo wá? Ṣé àwọn ìròrí ìgbà àìmọ́kan àti àwọn àṣà àìmọ́kan èyí tí ìran ẹnì kọ̀ọ̀kan jogún bá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá ńlá wọn tí wọn kì í ṣe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ṣé àwọn ìròrí wọn àti àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọn ni wọn yóò máa lò lẹ́yìn al-Ƙur’ān? Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:6 nítorí pé gbólóhùn t’ó ṣíwájú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa bí al-Ƙur’ān ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ òdodo. Èyí wá túmọ̀ sí pé |