Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 99 - التوبَة - Page - Juz 11
﴿وَمِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مَن يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ قُرُبَٰتٍ عِندَ ٱللَّهِ وَصَلَوَٰتِ ٱلرَّسُولِۚ أَلَآ إِنَّهَا قُرۡبَةٞ لَّهُمۡۚ سَيُدۡخِلُهُمُ ٱللَّهُ فِي رَحۡمَتِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴾
[التوبَة: 99]
﴿ومن الأعراب من يؤمن بالله واليوم الآخر ويتخذ ما ينفق قربات عند﴾ [التوبَة: 99]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó t’ó ń ná (fún ẹ̀sìn) di àwọn ìsúnmọ́ Allāhu àti (gbígba) àdùá (lọ́dọ̀) Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú òhun ni ìsúnmọ́ Allāhu fún wọn. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run |