بَرَاءَةٌ مِّنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى الَّذِينَ عَاهَدتُّم مِّنَ الْمُشْرِكِينَ (1) (Eyi ni) iyowo-yose lati odo Allahu ati Ojise Re si awon ti e se adehun fun ninu awon osebo |
فَسِيحُوا فِي الْأَرْضِ أَرْبَعَةَ أَشْهُرٍ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۙ وَأَنَّ اللَّهَ مُخْزِي الْكَافِرِينَ (2) Nitori naa, (eyin osebo) e rin (kiri) lori ile fun osu merin. Ki e si mo pe dajudaju eyin ko le moribo (ninu iya) Allahu. Ati pe dajudaju Allahu yoo doju ti awon alaigbagbo |
وَأَذَانٌ مِّنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى النَّاسِ يَوْمَ الْحَجِّ الْأَكْبَرِ أَنَّ اللَّهَ بَرِيءٌ مِّنَ الْمُشْرِكِينَ ۙ وَرَسُولُهُ ۚ فَإِن تُبْتُمْ فَهُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ ۖ وَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الَّذِينَ كَفَرُوا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ (3) Ikede kan lati odo Allahu ati Ojise Re si awon eniyan ni ojo Hajj Nla ni pe, “Dajudaju Allahu yowoyose (ninu oro) awon osebo. Ojise Re naa (yowoyose). Ti e ba ronu piwada, o si loore julo fun yin. Ti e ba gbunri, e mo pe dajudaju e o le moribo ninu (iya) Allahu.” Ki o si fun awon t’o sai gbagbo ni iro iya eleta-elero |
إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدتُّم مِّنَ الْمُشْرِكِينَ ثُمَّ لَمْ يَنقُصُوكُمْ شَيْئًا وَلَمْ يُظَاهِرُوا عَلَيْكُمْ أَحَدًا فَأَتِمُّوا إِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ إِلَىٰ مُدَّتِهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ (4) Ayafi awon ti e ba se adehun ninu awon osebo, leyin naa, ti won ko si fi ona kan kan ye adehun yin, ti won ko si satileyin fun eni kan kan le yin lori. Nitori naa, e pe adehun won fun won titi di asiko won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re) |
فَإِذَا انسَلَخَ الْأَشْهُرُ الْحُرُمُ فَاقْتُلُوا الْمُشْرِكِينَ حَيْثُ وَجَدتُّمُوهُمْ وَخُذُوهُمْ وَاحْصُرُوهُمْ وَاقْعُدُوا لَهُمْ كُلَّ مَرْصَدٍ ۚ فَإِن تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَخَلُّوا سَبِيلَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (5) Nitori naa, nigba ti awon osu owo ba lo tan , e pa awon osebo nibikibi ti e ba ti ba won. E mu won, e sede mo won, ki e si ba de won ni gbogbo ibuba. Ti won ba si ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, e yago fun won loju ona. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
وَإِنْ أَحَدٌ مِّنَ الْمُشْرِكِينَ اسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّىٰ يَسْمَعَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَعْلَمُونَ (6) Ti eni kan ninu awon osebo ba wa eto aabo wa sodo re, s’eto aabo fun un titi o fi maa gbo oro Allahu. Leyin naa, mu u de aye ifokanbale re. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko nimo |
كَيْفَ يَكُونُ لِلْمُشْرِكِينَ عَهْدٌ عِندَ اللَّهِ وَعِندَ رَسُولِهِ إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدتُّمْ عِندَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۖ فَمَا اسْتَقَامُوا لَكُمْ فَاسْتَقِيمُوا لَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ (7) Bawo ni adehun kan yoo se wa fun awon osebo lodo Allahu ati lodo Ojise Re yato si awon ti e ba se adehun nitosi Mosalasi Haram? Nitori naa, ti won ba duro deede pelu yin, e duro deede pelu won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re) |
كَيْفَ وَإِن يَظْهَرُوا عَلَيْكُمْ لَا يَرْقُبُوا فِيكُمْ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ يُرْضُونَكُم بِأَفْوَاهِهِمْ وَتَأْبَىٰ قُلُوبُهُمْ وَأَكْثَرُهُمْ فَاسِقُونَ (8) Bawo (ni adehun kan yoo se wa fun won) nigba ti o je pe ti won ba bori yin, won ko nii so okun ibi ati adehun. Won n fi enu won wi pe awon yonu si yin, okan won si ko o. Opolopo won si ni obileje |
اشْتَرَوْا بِآيَاتِ اللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا فَصَدُّوا عَن سَبِيلِهِ ۚ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (9) Won ta awon ayah Allahu ni owo pooku, won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Dajudaju awon (wonyi), ohun ti won n se nise buru |
لَا يَرْقُبُونَ فِي مُؤْمِنٍ إِلًّا وَلَا ذِمَّةً ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُعْتَدُونَ (10) Awon osebo ko nii so okun ibi ati adehun kan fun onigbagbo ododo kan. Awon wonyen, awon si ni olutayo enu-ala |
فَإِن تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَإِخْوَانُكُمْ فِي الدِّينِ ۗ وَنُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ (11) Nitori naa, ti won ba ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, nigba naa omo-iya yin ninu esin ni won. A n salaye awon ayah naa fun ijo t’o nimo |
وَإِن نَّكَثُوا أَيْمَانَهُم مِّن بَعْدِ عَهْدِهِمْ وَطَعَنُوا فِي دِينِكُمْ فَقَاتِلُوا أَئِمَّةَ الْكُفْرِ ۙ إِنَّهُمْ لَا أَيْمَانَ لَهُمْ لَعَلَّهُمْ يَنتَهُونَ (12) Ti won ba ru ibura won leyin adehun won, ti won si n soro aidara si esin yin, nigba naa e ja awon olori alaigbagbo logun - dajudaju ibura won ko ni itumo kan si won – ki won le jawo (nibi aburu) |
أَلَا تُقَاتِلُونَ قَوْمًا نَّكَثُوا أَيْمَانَهُمْ وَهَمُّوا بِإِخْرَاجِ الرَّسُولِ وَهُم بَدَءُوكُمْ أَوَّلَ مَرَّةٍ ۚ أَتَخْشَوْنَهُمْ ۚ فَاللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخْشَوْهُ إِن كُنتُم مُّؤْمِنِينَ (13) Se e o nii gbogun ti ijo kan t’o ru ibura won, ti won si gbero lati le Ojise kuro (ninu ilu); awon si ni won ko bere si gbogun ti yin ni igba akoko? Se e n paya won ni? Allahu l’O ni eto julo si pe ki e paya Re ti e ba je onigbagbo ododo |
قَاتِلُوهُمْ يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ بِأَيْدِيكُمْ وَيُخْزِهِمْ وَيَنصُرْكُمْ عَلَيْهِمْ وَيَشْفِ صُدُورَ قَوْمٍ مُّؤْمِنِينَ (14) E ja won logun. Allahu yoo je won niya lati owo yin. O maa yepere won. O maa ran yin lowo lori won. O si maa wo okan ijo onigbagbo ododo san |
وَيُذْهِبْ غَيْظَ قُلُوبِهِمْ ۗ وَيَتُوبُ اللَّهُ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (15) O tun maa ko ibinu okan won lo. O si maa gba ironupiwada lowo eni t’O ba fe. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
أَمْ حَسِبْتُمْ أَن تُتْرَكُوا وَلَمَّا يَعْلَمِ اللَّهُ الَّذِينَ جَاهَدُوا مِنكُمْ وَلَمْ يَتَّخِذُوا مِن دُونِ اللَّهِ وَلَا رَسُولِهِ وَلَا الْمُؤْمِنِينَ وَلِيجَةً ۚ وَاللَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ (16) Tabi e lero pe A oo fi yin sile lai je pe Allahu ti safi han awon t’o maa jagun esin ninu yin, ti won ko si ni ore ayo kan leyin Allahu, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo? Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |
مَا كَانَ لِلْمُشْرِكِينَ أَن يَعْمُرُوا مَسَاجِدَ اللَّهِ شَاهِدِينَ عَلَىٰ أَنفُسِهِم بِالْكُفْرِ ۚ أُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ وَفِي النَّارِ هُمْ خَالِدُونَ (17) Ko letoo fun awon osebo lati se amojuto awon mosalasi Allahu, nigba ti won je elerii si aigbagbo lori ara won. Awon wonyen ni ise won ti baje. Olusegbere si ni won ninu Ina |
إِنَّمَا يَعْمُرُ مَسَاجِدَ اللَّهِ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَأَقَامَ الصَّلَاةَ وَآتَى الزَّكَاةَ وَلَمْ يَخْشَ إِلَّا اللَّهَ ۖ فَعَسَىٰ أُولَٰئِكَ أَن يَكُونُوا مِنَ الْمُهْتَدِينَ (18) Eni ti o maa samojuto awon mosalasi Allahu ni eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si n kirun, t’o n yo Zakah, ko si paya (orisa kan) leyin Allahu. Awon wonyen ni won kuku wa ninu awon olumona |
۞ أَجَعَلْتُمْ سِقَايَةَ الْحَاجِّ وَعِمَارَةَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ كَمَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَجَاهَدَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ لَا يَسْتَوُونَ عِندَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (19) Se e maa se fifun alalaaji ni omi mu ati sise amojuto Mosalasi Haram ni ohun t’o dogba si eni t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, t’o si jagun soju ona (esin) Allahu? Won ko dogba lodo Allahu. Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
الَّذِينَ آمَنُوا وَهَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ أَعْظَمُ دَرَجَةً عِندَ اللَّهِ ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَائِزُونَ (20) Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won gbe ilu won ju sile, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu, won tobi julo ni ipo lodo Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere |
يُبَشِّرُهُمْ رَبُّهُم بِرَحْمَةٍ مِّنْهُ وَرِضْوَانٍ وَجَنَّاتٍ لَّهُمْ فِيهَا نَعِيمٌ مُّقِيمٌ (21) Oluwa won n fun won ni iro idunnu nipa ike lati odo Re pelu iyonu ati awon Ogba Idera kan ti idera gbere wa fun won ninu re |
خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عِندَهُ أَجْرٌ عَظِيمٌ (22) Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Dajudaju Allahu, odo Re ni esan nla wa |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا آبَاءَكُمْ وَإِخْوَانَكُمْ أَوْلِيَاءَ إِنِ اسْتَحَبُّوا الْكُفْرَ عَلَى الْإِيمَانِ ۚ وَمَن يَتَوَلَّهُم مِّنكُمْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ (23) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon baba yin ati awon arakunrin yin ni ore ayo bi won ba gbola fun aigbagbo lori igbagbo ododo. Enikeni t’o ba mu won ni ore ayo ninu yin, awon wonyen, awon ni alabosi |
قُلْ إِن كَانَ آبَاؤُكُمْ وَأَبْنَاؤُكُمْ وَإِخْوَانُكُمْ وَأَزْوَاجُكُمْ وَعَشِيرَتُكُمْ وَأَمْوَالٌ اقْتَرَفْتُمُوهَا وَتِجَارَةٌ تَخْشَوْنَ كَسَادَهَا وَمَسَاكِنُ تَرْضَوْنَهَا أَحَبَّ إِلَيْكُم مِّنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ وَجِهَادٍ فِي سَبِيلِهِ فَتَرَبَّصُوا حَتَّىٰ يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ (24) So pe: “Ti o ba je pe awon baba yin, awon omokunrin yin, awon arakunrin yin, awon iyawo yin ati awon ibatan yin pelu awon dukia kan ti e ti ko jo ati okowo kan ti e n beru pe ki o ma kuta ati awon ibugbe ti e yonu si, (ti iwonyi) ba wu yin ju Allahu ati Ojise Re pelu jija ogun soju ona (esin) Re, e maa reti (ikangun) nigba naa titi Allahu yoo fi mu ase Re wa. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje |
لَقَدْ نَصَرَكُمُ اللَّهُ فِي مَوَاطِنَ كَثِيرَةٍ ۙ وَيَوْمَ حُنَيْنٍ ۙ إِذْ أَعْجَبَتْكُمْ كَثْرَتُكُمْ فَلَمْ تُغْنِ عَنكُمْ شَيْئًا وَضَاقَتْ عَلَيْكُمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ ثُمَّ وَلَّيْتُم مُّدْبِرِينَ (25) Dajudaju Allahu ti se aranse fun yin ni opolopo oju ogun ati ni ojo (ogun) Hunaen, nigba ti pipo yin jo yin loju, (amo) ko ro yin loro kan kan; ile si fun mo yin tohun ti bi o se fe to. Leyin naa, e peyin da, e si n sa seyin |
ثُمَّ أَنزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ وَعَلَى الْمُؤْمِنِينَ وَأَنزَلَ جُنُودًا لَّمْ تَرَوْهَا وَعَذَّبَ الَّذِينَ كَفَرُوا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الْكَافِرِينَ (26) Leyin naa, Allahu so ifayabale Re kale fun Ojise Re ati fun awon onigbagbo ododo. O tun so awon omo ogun kan kale, ti e o foju ri won. O si je awon t’o sai gbagbo niya. Iyen si ni esan awon alaigbagbo |
ثُمَّ يَتُوبُ اللَّهُ مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (27) Leyin naa, Allahu yoo gba ironupiwada lowo eni t’O ba fe leyin iyen. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْمُشْرِكُونَ نَجَسٌ فَلَا يَقْرَبُوا الْمَسْجِدَ الْحَرَامَ بَعْدَ عَامِهِمْ هَٰذَا ۚ وَإِنْ خِفْتُمْ عَيْلَةً فَسَوْفَ يُغْنِيكُمُ اللَّهُ مِن فَضْلِهِ إِن شَاءَ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (28) Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju egbin ni awon osebo. Nitori naa, won ko gbodo sunmo Mosalasi Haram leyin odun won yii. Ti e ba n beru osi, laipe Allahu maa ro yin loro ninu ola Re, ti O ba fe. Dajudaju Allahu ni Onimo, Ologbon |
قَاتِلُوا الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَلَا بِالْيَوْمِ الْآخِرِ وَلَا يُحَرِّمُونَ مَا حَرَّمَ اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَلَا يَدِينُونَ دِينَ الْحَقِّ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ حَتَّىٰ يُعْطُوا الْجِزْيَةَ عَن يَدٍ وَهُمْ صَاغِرُونَ (29) E gbogun ti awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, awon ti ko se ni eewo ohun ti Allahu ati Ojise Re se ni eewo ati awon ti ko se esin ododo ninu awon ti A fun ni tira. (E gbogun ti won) titi won yoo fi maa fi owo ara won san owo-ori ni eni yepere |
وَقَالَتِ الْيَهُودُ عُزَيْرٌ ابْنُ اللَّهِ وَقَالَتِ النَّصَارَى الْمَسِيحُ ابْنُ اللَّهِ ۖ ذَٰلِكَ قَوْلُهُم بِأَفْوَاهِهِمْ ۖ يُضَاهِئُونَ قَوْلَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِن قَبْلُ ۚ قَاتَلَهُمُ اللَّهُ ۚ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ (30) Awon yehudi wi pe: "‘Uzaer ni omo Allahu." Awon nasara si wi pe: "Mosih ni omo Allahu." Iyen ni oro won ni enu won. Won n fi jo oro awon t’o sai gbagbo siwaju (won). Allahu fi won gegun-un. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo |
اتَّخَذُوا أَحْبَارَهُمْ وَرُهْبَانَهُمْ أَرْبَابًا مِّن دُونِ اللَّهِ وَالْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَمَا أُمِرُوا إِلَّا لِيَعْبُدُوا إِلَٰهًا وَاحِدًا ۖ لَّا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۚ سُبْحَانَهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ (31) Won mu awon alufaa won (ninu yehudi) ati awon alufaa won (ninu nasara) ni oluwa leyin Allahu. (Won tun mu) Mosih omo Moryam (ni oluwa leyin Allahu). Bee si ni A o pa won lase kan tayo jijosin fun Olohun, Okan soso. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O mo tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
يُرِيدُونَ أَن يُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَيَأْبَى اللَّهُ إِلَّا أَن يُتِمَّ نُورَهُ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ (32) Won fe fi enu won pa imole (esin) Allahu, Allahu yo si ko (fun won) titi O fi maa pe imole (esin) Re, awon alaigbagbo ibaa korira re |
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ (33) (Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (esin ’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re |
۞ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ كَثِيرًا مِّنَ الْأَحْبَارِ وَالرُّهْبَانِ لَيَأْكُلُونَ أَمْوَالَ النَّاسِ بِالْبَاطِلِ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ اللَّهِ ۗ وَالَّذِينَ يَكْنِزُونَ الذَّهَبَ وَالْفِضَّةَ وَلَا يُنفِقُونَهَا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ (34) Eyin ti e gbagbo ni ododo, opolopo ninu awon alufaa (ninu yehudi) ati awon alufaa (ninu nasara), won kuku n fi ona eru je dukia awon eniyan ni, won si n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Awon t’o si n ko wura ati fadaka jo, won ko si na an fun esin Allahu, fun won ni iro iya eleta-elero |
يَوْمَ يُحْمَىٰ عَلَيْهَا فِي نَارِ جَهَنَّمَ فَتُكْوَىٰ بِهَا جِبَاهُهُمْ وَجُنُوبُهُمْ وَظُهُورُهُمْ ۖ هَٰذَا مَا كَنَزْتُمْ لِأَنفُسِكُمْ فَذُوقُوا مَا كُنتُمْ تَكْنِزُونَ (35) Ni ojo ti A oo maa yo (wura ati fadaka naa) ninu ina Jahanamo, A o si maa fi jo iwaju won, egbe won ati eyin won. (A si maa so pe): "Eyi ni ohun ti e ko jo fun emi ara yin. Nitori naa, e to ohun ti e ko jo wo |
إِنَّ عِدَّةَ الشُّهُورِ عِندَ اللَّهِ اثْنَا عَشَرَ شَهْرًا فِي كِتَابِ اللَّهِ يَوْمَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ مِنْهَا أَرْبَعَةٌ حُرُمٌ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ ۚ فَلَا تَظْلِمُوا فِيهِنَّ أَنفُسَكُمْ ۚ وَقَاتِلُوا الْمُشْرِكِينَ كَافَّةً كَمَا يُقَاتِلُونَكُمْ كَافَّةً ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ (36) Dajudaju onka awon osu lodo Allahu n je osu mejila ninu akosile ti Allahu ni ojo ti O ti da awon sanmo ati ile. Merin ni osu owo ninu re. Iyen ni esin t’o fese rinle. Nitori naa, e ma sabosi si ara yin ninu awon osu owo. Ki gbogbo yin si gbogun ti awon osebo gege bi gbogbo won se n gbogun ti yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re) |
إِنَّمَا النَّسِيءُ زِيَادَةٌ فِي الْكُفْرِ ۖ يُضَلُّ بِهِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُحِلُّونَهُ عَامًا وَيُحَرِّمُونَهُ عَامًا لِّيُوَاطِئُوا عِدَّةَ مَا حَرَّمَ اللَّهُ فَيُحِلُّوا مَا حَرَّمَ اللَّهُ ۚ زُيِّنَ لَهُمْ سُوءُ أَعْمَالِهِمْ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ (37) Alekun ninu aigbagbo ni didajo si awon osu owo (lati owo awon osebo). Won n fi ko isina ba awon t’o sai gbagbo (nipa pe) won n se osu owo kan ni osu eto (fun ogun jija) ninu odun kan, won si n bu owo fun osu (ti ki i se osu owo) ninu odun (miiran, won ko si nii jagun ninu re) nitori ki won le yo onka osu ti Allahu se ni owo sira won. Won si tipase bee se ni eto ohun ti Allahu se ni eewo. Won se ise aburu won ni oso fun won. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا مَا لَكُمْ إِذَا قِيلَ لَكُمُ انفِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ اثَّاقَلْتُمْ إِلَى الْأَرْضِ ۚ أَرَضِيتُم بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا مِنَ الْآخِرَةِ ۚ فَمَا مَتَاعُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا فِي الْآخِرَةِ إِلَّا قَلِيلٌ (38) Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki ni o mu yin ti o fi je pe nigba ti A ba so fun yin pe ki e jade (lati jagun) loju ona (esin) Allahu, (igba naa ni) e maa kandi mole! Se e yonu si isemi aye (yii) ju ti orun ni? Igbadun isemi aye (yii) ko si je kini kan ninu ti orun afi die |
إِلَّا تَنفِرُوا يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا وَيَسْتَبْدِلْ قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّوهُ شَيْئًا ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (39) Afi ki e tu jade (sogun esin) ni Allahu ko fi nii je yin niya eleta-elero ati pe ni ko fi nii fi ijo to yato si yin paaro yin. E ko si le fi kini kan ko inira ba (Allahu). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
إِلَّا تَنصُرُوهُ فَقَدْ نَصَرَهُ اللَّهُ إِذْ أَخْرَجَهُ الَّذِينَ كَفَرُوا ثَانِيَ اثْنَيْنِ إِذْ هُمَا فِي الْغَارِ إِذْ يَقُولُ لِصَاحِبِهِ لَا تَحْزَنْ إِنَّ اللَّهَ مَعَنَا ۖ فَأَنزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَيْهِ وَأَيَّدَهُ بِجُنُودٍ لَّمْ تَرَوْهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ الَّذِينَ كَفَرُوا السُّفْلَىٰ ۗ وَكَلِمَةُ اللَّهِ هِيَ الْعُلْيَا ۗ وَاللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ (40) Afi ki e ran an lowo, Allahu kuku ti ran an lowo nigba ti awon t’o sai gbagbo le e jade (kuro ninu ilu). O si je okan ninu awon meji.1 Nigba ti awon mejeeji wa ninu ogbun, ti (Anabi) si n so fun olubarin re pe: "Ma se banuje, dajudaju Allahu wa pelu wa."2 Nigba naa, Allahu so ifayabale Re kale fun un. O fi awon omo ogun kan ti e o foju ri ran an lowo. O si mu oro awon t’o sai gbagbo wale. Oro Allahu, ohun l’o si leke. Allahu si ni Alagbara, Ologbon |
انفِرُوا خِفَافًا وَثِقَالًا وَجَاهِدُوا بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنفُسِكُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ (41) E tu jade (fun ogun esin) pelu okun ati iroju. Ki e si fi awon dukia yin ati emi yin jagun fun esin Allahu. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo |
لَوْ كَانَ عَرَضًا قَرِيبًا وَسَفَرًا قَاصِدًا لَّاتَّبَعُوكَ وَلَٰكِن بَعُدَتْ عَلَيْهِمُ الشُّقَّةُ ۚ وَسَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَوِ اسْتَطَعْنَا لَخَرَجْنَا مَعَكُمْ يُهْلِكُونَ أَنفُسَهُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ (42) Ti o ba je pe nnkan igbadun (oro ogun) arowoto ati irin-ajo ti ko jinna (l’o pe won si ni), won iba tele o. Sugbon irin-ajo ogun Tabuk jinna loju won. Won yo si maa fi Allahu bura pe: “Ti o ba je pe a lagbara ni, awa iba jade (fun ogun esin) pelu yin.” – Won si n ko iparun ba emi ara won (nipa sise isobe-selu.) – Allahu si mo pe dajudaju opuro ni won |
عَفَا اللَّهُ عَنكَ لِمَ أَذِنتَ لَهُمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكَ الَّذِينَ صَدَقُوا وَتَعْلَمَ الْكَاذِبِينَ (43) Allahu ti samojukuro fun o. Ki lo mu o yonda fun won (pe ki won duro sile? Iwo iba ma se bee) titi oro awon t’o sododo yoo fi han si o kedere. Iwo yo si mo awon opuro |
لَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ أَن يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ (44) Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin ko nii toro iyonda lodo re lati ma fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re) |
إِنَّمَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَارْتَابَتْ قُلُوبُهُمْ فَهُمْ فِي رَيْبِهِمْ يَتَرَدَّدُونَ (45) Awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, dipo lilo si oju-ogun) ni awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin; okan won si n seyemeji. Nitori naa, won n daamu kiri nibi iseye-meji won |
۞ وَلَوْ أَرَادُوا الْخُرُوجَ لَأَعَدُّوا لَهُ عُدَّةً وَلَٰكِن كَرِهَ اللَّهُ انبِعَاثَهُمْ فَثَبَّطَهُمْ وَقِيلَ اقْعُدُوا مَعَ الْقَاعِدِينَ (46) Ti o ba je pe won gbero ijade fun ogun esin ni, won iba se ipalemo fun un. Sugbon Allahu korira idide won fun ogun esin, O si ko ifaseyin ba won. Won si so fun won pe: "E jokoo pelu awon olujokoo sile |
لَوْ خَرَجُوا فِيكُم مَّا زَادُوكُمْ إِلَّا خَبَالًا وَلَأَوْضَعُوا خِلَالَكُمْ يَبْغُونَكُمُ الْفِتْنَةَ وَفِيكُمْ سَمَّاعُونَ لَهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ (47) Ti o ba je pe won jade pelu yin, won ko nii kun yin afi pelu ibaje. Won yo si sare maa da rukerudo sile laaarin yin, ti won yoo maa ko yin sinu iyonu. Ati pe won ni olugboro fun won laaarin yin. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi |
لَقَدِ ابْتَغَوُا الْفِتْنَةَ مِن قَبْلُ وَقَلَّبُوا لَكَ الْأُمُورَ حَتَّىٰ جَاءَ الْحَقُّ وَظَهَرَ أَمْرُ اللَّهِ وَهُمْ كَارِهُونَ (48) Won kuku ti da iyonu sile teletele. Won si doju awon oro ru fun o titi ododo fi de, ti ase Allahu si foju han kedere; emi won si ko o |
وَمِنْهُم مَّن يَقُولُ ائْذَن لِّي وَلَا تَفْتِنِّي ۚ أَلَا فِي الْفِتْنَةِ سَقَطُوا ۗ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌ بِالْكَافِرِينَ (49) O wa ninu won, eni ti n wi pe: “Yonda fun mi (ki ng jokoo sile); ma se ko mi sinu adanwo.” Inu adanwo (sisa fogun esin) ma ni won ti subu si yii. Dajudaju ina Jahanamo yo si kuku yi awon alaigbagbo po |
إِن تُصِبْكَ حَسَنَةٌ تَسُؤْهُمْ ۖ وَإِن تُصِبْكَ مُصِيبَةٌ يَقُولُوا قَدْ أَخَذْنَا أَمْرَنَا مِن قَبْلُ وَيَتَوَلَّوا وَّهُمْ فَرِحُونَ (50) Ti daadaa ba sele si o, o maa ba won ninu je. Ti aida ba si sele si o, won a wi pe: “A kuku ti gba ase tiwa siwaju (lati jokoo sile.)” Won a peyin da; won yo si maa dunnu |
قُل لَّن يُصِيبَنَا إِلَّا مَا كَتَبَ اللَّهُ لَنَا هُوَ مَوْلَانَا ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ (51) So pe: “Ko si ohun kan t’o maa sele si wa ayafi ohun ti Allahu ko mo wa. Oun ni Alaabo wa.” Allahu si ni ki awon onigbagbo ododo gbarale |
قُلْ هَلْ تَرَبَّصُونَ بِنَا إِلَّا إِحْدَى الْحُسْنَيَيْنِ ۖ وَنَحْنُ نَتَرَبَّصُ بِكُمْ أَن يُصِيبَكُمُ اللَّهُ بِعَذَابٍ مِّنْ عِندِهِ أَوْ بِأَيْدِينَا ۖ فَتَرَبَّصُوا إِنَّا مَعَكُم مُّتَرَبِّصُونَ (52) So pe: "Se e n reti kini kan pelu wa ni bi ko se okan ninu daadaa meji (iku ogun tabi isegun)? Awa naa n reti pelu yin pe ki Allahu mu iya kan wa ba yin lati odo Re tabi lati owo wa. Nitori naa, e maa reti, dajudaju awa naa wa pelu yin ti a n reti |
قُلْ أَنفِقُوا طَوْعًا أَوْ كَرْهًا لَّن يُتَقَبَّلَ مِنكُمْ ۖ إِنَّكُمْ كُنتُمْ قَوْمًا فَاسِقِينَ (53) So pe: "E finnu-findo nawo ni tabi pelu tipatipa, A o nii gba a lowo yin (nitori pe) dajudaju eyin je ijo obileje |
وَمَا مَنَعَهُمْ أَن تُقْبَلَ مِنْهُمْ نَفَقَاتُهُمْ إِلَّا أَنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَبِرَسُولِهِ وَلَا يَأْتُونَ الصَّلَاةَ إِلَّا وَهُمْ كُسَالَىٰ وَلَا يُنفِقُونَ إِلَّا وَهُمْ كَارِهُونَ (54) Ko si si ohun kan ti ko je ki A gba inawo won lowo won bi ko se pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won ko nii wa kirun afi ki won je oroju alainikan-anse. Won ko si nii nawo fesin afi ki emi won ko o |
فَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَالُهُمْ وَلَا أَوْلَادُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ لِيُعَذِّبَهُم بِهَا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ (55) Nitori naa, ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. Emi yo si bo lara won, ti won maa wa nipo alaigbagbo |
وَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ إِنَّهُمْ لَمِنكُمْ وَمَا هُم مِّنكُمْ وَلَٰكِنَّهُمْ قَوْمٌ يَفْرَقُونَ (56) Won n fi Allahu bura pe dajudaju awon kuku wa lara yin. Won ko si si lara yin, sugbon dajudaju won je ijo kan t’o n beru |
لَوْ يَجِدُونَ مَلْجَأً أَوْ مَغَارَاتٍ أَوْ مُدَّخَلًا لَّوَلَّوْا إِلَيْهِ وَهُمْ يَجْمَحُونَ (57) Ti o ba je pe won ri ibusasi kan, tabi awon iho apata kan, tabi ibusawo kan, won iba seri sibe ni werewere |
وَمِنْهُم مَّن يَلْمِزُكَ فِي الصَّدَقَاتِ فَإِنْ أُعْطُوا مِنْهَا رَضُوا وَإِن لَّمْ يُعْطَوْا مِنْهَا إِذَا هُمْ يَسْخَطُونَ (58) O tun wa ninu won, eni ti n da o lebi nibi (pipin) awon ore. Ti A ba fun won ninu re, won a yonu (si i). Ti A o ba si fun won ninu re, nigba naa ni won yoo maa binu |
وَلَوْ أَنَّهُمْ رَضُوا مَا آتَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ وَقَالُوا حَسْبُنَا اللَّهُ سَيُؤْتِينَا اللَّهُ مِن فَضْلِهِ وَرَسُولُهُ إِنَّا إِلَى اللَّهِ رَاغِبُونَ (59) Ati pe (iba loore fun won) ti o ba je pe dajudaju won yonu si ohun ti Allahu ati Ojise Re fun won, ki won si so pe: "Allahu to wa. Allahu yo si fun wa ninu oore ajulo Re ati pe Ojise Re (si maa pin ore) , dajudaju odo Allahu si ni awa n wa oore si |
۞ إِنَّمَا الصَّدَقَاتُ لِلْفُقَرَاءِ وَالْمَسَاكِينِ وَالْعَامِلِينَ عَلَيْهَا وَالْمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمْ وَفِي الرِّقَابِ وَالْغَارِمِينَ وَفِي سَبِيلِ اللَّهِ وَابْنِ السَّبِيلِ ۖ فَرِيضَةً مِّنَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (60) Awon ti ore (Zakah) wa fun ni awon alaini, awon mekunnu, awon osise Zakah, awon ti okan won fe gba ’Islam, awon eru (fun gbigba ominira), awon onigbese, awon t’o wa loju ogun (esin) Allahu ati onirin-ajo (ti agara da). Oran-anyan ni lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
وَمِنْهُمُ الَّذِينَ يُؤْذُونَ النَّبِيَّ وَيَقُولُونَ هُوَ أُذُنٌ ۚ قُلْ أُذُنُ خَيْرٍ لَّكُمْ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَيُؤْمِنُ لِلْمُؤْمِنِينَ وَرَحْمَةٌ لِّلَّذِينَ آمَنُوا مِنكُمْ ۚ وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ رَسُولَ اللَّهِ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (61) Awon t’o n ko inira ba Anabi wa ninu won, ti won si n wi pe: “Eleti-ofe ni." So pe: "Eleti-ofe rere ni fun yin; o gbagbo ninu Allahu. O si gba awon onigbagbo ododo gbo. Ike ni fun awon onigbagbo ododo ninu Ojise Allahu, iya eleta-elero n be fun won.” |
يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَكُمْ لِيُرْضُوكُمْ وَاللَّهُ وَرَسُولُهُ أَحَقُّ أَن يُرْضُوهُ إِن كَانُوا مُؤْمِنِينَ (62) Won n fi Allahu bura fun yin lati wa iyonu yin. Allahu ati Ojise Re l’o si ye ki won wa iyonu Re ti won ba je onigbagbo ododo |
أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّهُ مَن يُحَادِدِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَأَنَّ لَهُ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدًا فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ الْخِزْيُ الْعَظِيمُ (63) Se won ko mo pe enikeni t’o ba n tako Allahu ati Ojise Re, dajudaju ina Jahanamo ti wa fun un ni? Olusegbere si ni ninu re. Iyen si ni abuku nla |
يَحْذَرُ الْمُنَافِقُونَ أَن تُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ سُورَةٌ تُنَبِّئُهُم بِمَا فِي قُلُوبِهِمْ ۚ قُلِ اسْتَهْزِئُوا إِنَّ اللَّهَ مُخْرِجٌ مَّا تَحْذَرُونَ (64) Awon sobe-selu musulumi n beru pe ki A ma se so surah kan kale nipa won, ti o maa fun won ni iro ohun ti n be ninu okan won. So pe: "E maa se yeye lo. Dajudaju Allahu yoo safi han ohun ti e n beru |
وَلَئِن سَأَلْتَهُمْ لَيَقُولُنَّ إِنَّمَا كُنَّا نَخُوضُ وَنَلْعَبُ ۚ قُلْ أَبِاللَّهِ وَآيَاتِهِ وَرَسُولِهِ كُنتُمْ تَسْتَهْزِئُونَ (65) Ti o ba kuku bi won leere, dajudaju won a wi pe: "Awa kan n rojo lasan ni, a si n sawada ni." So pe: "Se Allahu, awon ayah Re ati Ojise Re ni e n fi se yeye |
لَا تَعْتَذِرُوا قَدْ كَفَرْتُم بَعْدَ إِيمَانِكُمْ ۚ إِن نَّعْفُ عَن طَائِفَةٍ مِّنكُمْ نُعَذِّبْ طَائِفَةً بِأَنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ (66) E ma se mu awawi wa. Dajudaju e ti sai gbagbo leyin igbagbo yin. Ti A ba se amojukuro fun apa kan ninu yin, A oo fiya je apa kan nitori pe won je elese |
الْمُنَافِقُونَ وَالْمُنَافِقَاتُ بَعْضُهُم مِّن بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمُنكَرِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمَعْرُوفِ وَيَقْبِضُونَ أَيْدِيَهُمْ ۚ نَسُوا اللَّهَ فَنَسِيَهُمْ ۗ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ هُمُ الْفَاسِقُونَ (67) Awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin, iru kan-un ni won; won n pase ohun buruku, won n ko ohun rere, won si n kawo gbera (lati nawo fesin). Won gbagbe Allahu. Nitori naa, Allahu gbagbe won. Dajudaju awon sobe-selu musulumi, awon ni obileje |
وَعَدَ اللَّهُ الْمُنَافِقِينَ وَالْمُنَافِقَاتِ وَالْكُفَّارَ نَارَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ هِيَ حَسْبُهُمْ ۚ وَلَعَنَهُمُ اللَّهُ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ مُّقِيمٌ (68) Allahu si ti se adehun ina Jahanamo fun awon sobe-selu musulumi lokunrin ati awon sobe-selu musulumo lobinrin ati awon alaigbagbo. Olusegbere ni won ninu re. Ina maa to won. Allahu si ti sebi le won. Iya gbere si wa fun won |
كَالَّذِينَ مِن قَبْلِكُمْ كَانُوا أَشَدَّ مِنكُمْ قُوَّةً وَأَكْثَرَ أَمْوَالًا وَأَوْلَادًا فَاسْتَمْتَعُوا بِخَلَاقِهِمْ فَاسْتَمْتَعْتُم بِخَلَاقِكُمْ كَمَا اسْتَمْتَعَ الَّذِينَ مِن قَبْلِكُم بِخَلَاقِهِمْ وَخُضْتُمْ كَالَّذِي خَاضُوا ۚ أُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ (69) (Awon sobe-selu musulumi da) gege bi awon t’o siwaju yin; won le ju yin lo ni agbara, won si po (ju yin lo) ni awon dukia ati awon omo. Nigba naa, won je igbadun ipin tiwon (ninu oore aye). Eyin (sobe-selu wonyii naa yoo) je igbadun ipin tiyin gege bi awon t’o siwaju yin se je igbadun ipin tiwon. Eyin naa si sosokuso bi eyi ti awon naa so ni isokuso. Awon wonyen, awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen, awon si ni eni ofo |
أَلَمْ يَأْتِهِمْ نَبَأُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ وَقَوْمِ إِبْرَاهِيمَ وَأَصْحَابِ مَدْيَنَ وَالْمُؤْتَفِكَاتِ ۚ أَتَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ (70) Se iroyin awon t’o siwaju won ko ti i de ba won ni? (Iroyin) ijo (Anabi) Nuh, iran ‘Ad, iran Thamud, ijo (Anabi) ’Ibrohim, awon ara Modyan ati awon ilu ti A doju re bole (ijo Anabi Lut); awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Nitori naa, Allahu ko se abosi si won, sugbon emi ara won ni won sabosi si |
وَالْمُؤْمِنُونَ وَالْمُؤْمِنَاتُ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ يَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنكَرِ وَيُقِيمُونَ الصَّلَاةَ وَيُؤْتُونَ الزَّكَاةَ وَيُطِيعُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ أُولَٰئِكَ سَيَرْحَمُهُمُ اللَّهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ (71) Awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, apa kan won lore apa kan; won n pase ohun rere, won n ko ohun buruku, won n kirun, won n yo Zakah, won si n tele ti Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni Allahu yoo sake. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon |
وَعَدَ اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ وَرِضْوَانٌ مِّنَ اللَّهِ أَكْبَرُ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (72) Allahu se adehun awon Ogba Idera fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. (O tun se adehun) awon ibugbe t’o dara ninu awon ogba idera ‘Adni (fun won). Iyonu lati odo Allahu l’o si tobi julo (fun won). Iyen, ohun ni erenje nla |
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ جَاهِدِ الْكُفَّارَ وَالْمُنَافِقِينَ وَاغْلُظْ عَلَيْهِمْ ۚ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ (73) Iwo Anabi, gbogun ti awon alaigbagbo ati awon sobe-selu musulumi. Ki o si le mo won. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Ikangun naa si buru |
يَحْلِفُونَ بِاللَّهِ مَا قَالُوا وَلَقَدْ قَالُوا كَلِمَةَ الْكُفْرِ وَكَفَرُوا بَعْدَ إِسْلَامِهِمْ وَهَمُّوا بِمَا لَمْ يَنَالُوا ۚ وَمَا نَقَمُوا إِلَّا أَنْ أَغْنَاهُمُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ مِن فَضْلِهِ ۚ فَإِن يَتُوبُوا يَكُ خَيْرًا لَّهُمْ ۖ وَإِن يَتَوَلَّوْا يُعَذِّبْهُمُ اللَّهُ عَذَابًا أَلِيمًا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۚ وَمَا لَهُمْ فِي الْأَرْضِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ (74) Won n fi Allahu bura pe awon ko soro (buruku). Won si kuku ti so oro aigbagbo, won si sai gbagbo leyin ti won ti gba ’Islam. Won tun gberokero si nnkan ti owo won ko nii ba. Won ko tako kini kan bi ko se nitori pe Allahu ati Ojise Re ro awon (Sohabah) loro ninu ola Re. Ti won ba ronu piwada, o maa dara fun won. Ti won ba si koyin (si yin), Allahu yoo je won niya eleta-elero ni aye ati ni orun. Ko si nii si alaabo ati alaranse kan fun won lori ile aye |
۞ وَمِنْهُم مَّنْ عَاهَدَ اللَّهَ لَئِنْ آتَانَا مِن فَضْلِهِ لَنَصَّدَّقَنَّ وَلَنَكُونَنَّ مِنَ الصَّالِحِينَ (75) O wa ninu won, eni t’o ba Allahu se adehun pe: "Ti O ba fun wa ninu oore-ajulo Re, dajudaju a oo maa tore, dajudaju a o si wa ninu awon eni ire |
فَلَمَّا آتَاهُم مِّن فَضْلِهِ بَخِلُوا بِهِ وَتَوَلَّوا وَّهُم مُّعْرِضُونَ (76) Amo nigba ti O fun won ninu oore-ajulo Re, won sahun si I. Won peyin da, won si n gbunri (lati nawo fesin) |
فَأَعْقَبَهُمْ نِفَاقًا فِي قُلُوبِهِمْ إِلَىٰ يَوْمِ يَلْقَوْنَهُ بِمَا أَخْلَفُوا اللَّهَ مَا وَعَدُوهُ وَبِمَا كَانُوا يَكْذِبُونَ (77) Nitori naa, ahun won mu oro won kangun si isobe-selu ninu okan won titi di ojo ti won yoo pade Allahu nitori pe won ye adehun ti won ba Allahu se ati nitori pe won n paro |
أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ سِرَّهُمْ وَنَجْوَاهُمْ وَأَنَّ اللَّهَ عَلَّامُ الْغُيُوبِ (78) Se won ko mo pe Allahu mo asiri won ati oro ateso won, ati pe dajudaju Allahu ni Onimo nipa awon ikoko |
الَّذِينَ يَلْمِزُونَ الْمُطَّوِّعِينَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ فِي الصَّدَقَاتِ وَالَّذِينَ لَا يَجِدُونَ إِلَّا جُهْدَهُمْ فَيَسْخَرُونَ مِنْهُمْ ۙ سَخِرَ اللَّهُ مِنْهُمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (79) Awon t’o n bu awon olutore-aanu ninu awon onigbagbo ododo lori ore tita ati awon ti ko ri nnkan kan tayo iwon agbara won, won si n fi won se yeye, Allahu fi awon naa se yeye. Iya eleta-elero si wa fun won |
اسْتَغْفِرْ لَهُمْ أَوْ لَا تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ إِن تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ سَبْعِينَ مَرَّةً فَلَن يَغْفِرَ اللَّهُ لَهُمْ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ (80) Yala o toro aforijin fun won tabi o o toro aforijin fun won – koda ki o toro aforijin fun won nigba aadorin – Allahu ko nii forijin won. Iyen nitori pe dajudaju won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje |
فَرِحَ الْمُخَلَّفُونَ بِمَقْعَدِهِمْ خِلَافَ رَسُولِ اللَّهِ وَكَرِهُوا أَن يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَقَالُوا لَا تَنفِرُوا فِي الْحَرِّ ۗ قُلْ نَارُ جَهَنَّمَ أَشَدُّ حَرًّا ۚ لَّوْ كَانُوا يَفْقَهُونَ (81) Awon olusaseyin fun ogun esin dunnu si jijokoo sinu ile won leyin Ojise Allahu. Won si korira lati fi dukia won ati emi won jagun loju ona (esin) Allahu. Won tun wi pe: “E ma lo jagun ninu ooru gbigbona.” So pe: “Ina Jahanamo le julo ni gbigbona, ti o ba je pe won gbo agboye oro.” |
فَلْيَضْحَكُوا قَلِيلًا وَلْيَبْكُوا كَثِيرًا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ (82) Nitori naa, ki won rerin-in die, ki won si sunkun pupo; (o je) esan (fun) ohun ti won n se nise |
فَإِن رَّجَعَكَ اللَّهُ إِلَىٰ طَائِفَةٍ مِّنْهُمْ فَاسْتَأْذَنُوكَ لِلْخُرُوجِ فَقُل لَّن تَخْرُجُوا مَعِيَ أَبَدًا وَلَن تُقَاتِلُوا مَعِيَ عَدُوًّا ۖ إِنَّكُمْ رَضِيتُم بِالْقُعُودِ أَوَّلَ مَرَّةٍ فَاقْعُدُوا مَعَ الْخَالِفِينَ (83) Ti Allahu ba mu o dele ba igun kan ninu won, ti won ba wa n gbase lodo re fun jijade fun ogun esin, so nigba naa pe: “Eyin ko le jade fun ogun esin mo pelu mi. Eyin ko si le ja ota kan logun mo pelu mi, nitori pe e ti yonu si ijokoo sile ni igba akoko. Nitori naa, e jokoo sile ti awon olusaseyin fun ogun esin.” |
وَلَا تُصَلِّ عَلَىٰ أَحَدٍ مِّنْهُم مَّاتَ أَبَدًا وَلَا تَقُمْ عَلَىٰ قَبْرِهِ ۖ إِنَّهُمْ كَفَرُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَمَاتُوا وَهُمْ فَاسِقُونَ (84) Laelae, o o gbodo kirun si eni kan kan lara ninu won, ti o ba ku, o o si gbodo duro nibi saree re, nitori pe won sai gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Won si ku nigba ti won wa nipo obileje |
وَلَا تُعْجِبْكَ أَمْوَالُهُمْ وَأَوْلَادُهُمْ ۚ إِنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ أَن يُعَذِّبَهُم بِهَا فِي الدُّنْيَا وَتَزْهَقَ أَنفُسُهُمْ وَهُمْ كَافِرُونَ (85) Ma se je ki awon dukia won ati awon omo won ya o lenu; Allahu kan fe fi je won niya ninu isemi aye (yii) ni. (O si fe ki) emi bo lara won, nigba ti won ba wa nipo alaigbagbo |
وَإِذَا أُنزِلَتْ سُورَةٌ أَنْ آمِنُوا بِاللَّهِ وَجَاهِدُوا مَعَ رَسُولِهِ اسْتَأْذَنَكَ أُولُو الطَّوْلِ مِنْهُمْ وَقَالُوا ذَرْنَا نَكُن مَّعَ الْقَاعِدِينَ (86) Nigba ti A ba so surah kan kale pe ki won gbagbo ninu Allahu, ki won si jagun pelu Ojise Re, (nigba naa ni) awon oloro ninu won yoo maa toro iyonda lodo re, won a si wi pe: “Fi wa sile ki a wa pelu awon olujokoo sile.” |
رَضُوا بِأَن يَكُونُوا مَعَ الْخَوَالِفِ وَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ (87) Won yonu si ki won maa wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. A ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko nii gbo agboye |
لَٰكِنِ الرَّسُولُ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ جَاهَدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ ۚ وَأُولَٰئِكَ لَهُمُ الْخَيْرَاتُ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ (88) Sugbon Ojise ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re, won fi dukia won ati emi won jagun esin. Awon wonyen, awon oore n be fun won. Awon wonyen, awon si ni olujere |
أَعَدَّ اللَّهُ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (89) Allahu ti pese sile de won awon Ogba Idera kan ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen ni erenje nla |
وَجَاءَ الْمُعَذِّرُونَ مِنَ الْأَعْرَابِ لِيُؤْذَنَ لَهُمْ وَقَعَدَ الَّذِينَ كَذَبُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ سَيُصِيبُ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (90) Awon alawaawi ninu awon Larubawa oko wa (ba o) nitori ki won le yonda (ijokoo sile) fun won. Awon t’o si pe oro Allahu ati oro Ojise niro naa jokoo sile. Iya eleta-elero yo si fowo ba awon t’o sai gbagbo ninu won |
لَّيْسَ عَلَى الضُّعَفَاءِ وَلَا عَلَى الْمَرْضَىٰ وَلَا عَلَى الَّذِينَ لَا يَجِدُونَ مَا يُنفِقُونَ حَرَجٌ إِذَا نَصَحُوا لِلَّهِ وَرَسُولِهِ ۚ مَا عَلَى الْمُحْسِنِينَ مِن سَبِيلٍ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (91) Ko si ese fun awon alailagbara, awon alaisan ati awon ti ko ri ohun ti won maa na ni owo (lati fi jagun esin) nigba ti won ba ti ni otito si Allahu ati Ojise Re. Ko si ibawi kan fun awon olotiito-inu se. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
وَلَا عَلَى الَّذِينَ إِذَا مَا أَتَوْكَ لِتَحْمِلَهُمْ قُلْتَ لَا أَجِدُ مَا أَحْمِلُكُمْ عَلَيْهِ تَوَلَّوا وَّأَعْيُنُهُمْ تَفِيضُ مِنَ الدَّمْعِ حَزَنًا أَلَّا يَجِدُوا مَا يُنفِقُونَ (92) Ko tun si ese fun awon ti (o je pe) nigba ti won ba wa ba o pe ki o fun awon ni nnkan ti awon yoo gun (lo soju ogun), ti o si so pe, “Ng o ri nnkan ti mo le fun yin gun (lo soju ogun), won maa pada pelu oju won ti yoo maa damije ni ti ibanuje pe won ko ri nnkan ti won maa na (lo soju ogun esin) |
۞ إِنَّمَا السَّبِيلُ عَلَى الَّذِينَ يَسْتَأْذِنُونَكَ وَهُمْ أَغْنِيَاءُ ۚ رَضُوا بِأَن يَكُونُوا مَعَ الْخَوَالِفِ وَطَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ (93) Awon ti ibawi wa fun ni awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, ti) won si je oloro, ti won yonu si ki won wa pelu awon olusaseyin fun ogun esin. Allahu ti fi edidi di okan won pa; nitori naa, won ko si mo |
يَعْتَذِرُونَ إِلَيْكُمْ إِذَا رَجَعْتُمْ إِلَيْهِمْ ۚ قُل لَّا تَعْتَذِرُوا لَن نُّؤْمِنَ لَكُمْ قَدْ نَبَّأَنَا اللَّهُ مِنْ أَخْبَارِكُمْ ۚ وَسَيَرَى اللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (94) Won yoo mu awawi wa fun yin nigba ti e ba dari de ba won. So pe: "E ma se mu awawi wa; a o nii gba yin gbo. Allahu kuku ti so awon oro yin fun wa. Allahu ati Ojise Re yo si ri ise (owo) yin. Leyin naa, A oo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. Nigba naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
سَيَحْلِفُونَ بِاللَّهِ لَكُمْ إِذَا انقَلَبْتُمْ إِلَيْهِمْ لِتُعْرِضُوا عَنْهُمْ ۖ فَأَعْرِضُوا عَنْهُمْ ۖ إِنَّهُمْ رِجْسٌ ۖ وَمَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ (95) Won yoo maa fi Allahu bura fun yin nigba ti e ba dari de ba won, nitori ki e le pa won ti. Nitori naa, e pa won ti; dajudaju egbin ni won. Ina Jahanamo si ni ibugbe won. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise |
يَحْلِفُونَ لَكُمْ لِتَرْضَوْا عَنْهُمْ ۖ فَإِن تَرْضَوْا عَنْهُمْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يَرْضَىٰ عَنِ الْقَوْمِ الْفَاسِقِينَ (96) Won yoo maa bura fun yin nitori ki e le yonu si won. Ti e ba yonu si won, dajudaju Allahu ko nii yonu si ijo obileje |
الْأَعْرَابُ أَشَدُّ كُفْرًا وَنِفَاقًا وَأَجْدَرُ أَلَّا يَعْلَمُوا حُدُودَ مَا أَنزَلَ اللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (97) Awon Larubawa oko le ninu aigbagbo ati isobe-selu. O si sunmo pe won ko mo awon enu-ala ohun ti Allahu sokale fun Ojise Re. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
وَمِنَ الْأَعْرَابِ مَن يَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ مَغْرَمًا وَيَتَرَبَّصُ بِكُمُ الدَّوَائِرَ ۚ عَلَيْهِمْ دَائِرَةُ السَّوْءِ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ (98) Ati pe o wa ninu awon Larubawa oko eni ti o ka inawo t’o n na (fun esin) si owo oran. O si n reti apadasi aburu fun yin. Awon si ni apadasi aburu yoo de ba. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
وَمِنَ الْأَعْرَابِ مَن يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَيَتَّخِذُ مَا يُنفِقُ قُرُبَاتٍ عِندَ اللَّهِ وَصَلَوَاتِ الرَّسُولِ ۚ أَلَا إِنَّهَا قُرْبَةٌ لَّهُمْ ۚ سَيُدْخِلُهُمُ اللَّهُ فِي رَحْمَتِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (99) O tun wa ninu awon Larubawa oko, eni ti o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin, ti o si so inawo t’o n na (fun esin) di awon isunmo Allahu ati (gbigba) adua (lodo) Ojise. Kiye si i, dajudaju ohun ni isunmo Allahu fun won. Allahu yo si fi won sinu ike Re. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
وَالسَّابِقُونَ الْأَوَّلُونَ مِنَ الْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنصَارِ وَالَّذِينَ اتَّبَعُوهُم بِإِحْسَانٍ رَّضِيَ اللَّهُ عَنْهُمْ وَرَضُوا عَنْهُ وَأَعَدَّ لَهُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي تَحْتَهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا أَبَدًا ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (100) Awon asiwaju, awon eni akoko ninu awon Muhajirun ati awon ’Ansor pelu awon t’o fi daadaa tele won, Allahu yonu si won. Won si yonu si (ohun ti Allahu fun won). O tun pa lese sile de won awon Ogba Idera ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re titi laelae. Iyen ni erenje nla |
وَمِمَّنْ حَوْلَكُم مِّنَ الْأَعْرَابِ مُنَافِقُونَ ۖ وَمِنْ أَهْلِ الْمَدِينَةِ ۖ مَرَدُوا عَلَى النِّفَاقِ لَا تَعْلَمُهُمْ ۖ نَحْنُ نَعْلَمُهُمْ ۚ سَنُعَذِّبُهُم مَّرَّتَيْنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٍ (101) Awon sobe-selu musulumi kan n be ninu awon ti o wa ni ayika yin ninu awon Larubawa oko ati ninu awon ara ilu Modinah, ti won wonkoko mo isobe-selu. O o mo won, Awa l’A mo won. A oo je won niya ni ee meji. Leyin naa, A oo da won pada sinu iya nla |
وَآخَرُونَ اعْتَرَفُوا بِذُنُوبِهِمْ خَلَطُوا عَمَلًا صَالِحًا وَآخَرَ سَيِّئًا عَسَى اللَّهُ أَن يَتُوبَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (102) Awon miiran jewo ese won. Won da ise rere po mo ise miiran t’o buru. Boya Allahu yoo gba ironupiwada won. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
خُذْ مِنْ أَمْوَالِهِمْ صَدَقَةً تُطَهِّرُهُمْ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيْهِمْ ۖ إِنَّ صَلَاتَكَ سَكَنٌ لَّهُمْ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ (103) Gba ore (Zakah) ninu dukia won, ki o fi so won di eni mimo, ki o si fi se afomo fun won. Se adua fun won. Dajudaju adua re ni ifayabale fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo |
أَلَمْ يَعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ هُوَ يَقْبَلُ التَّوْبَةَ عَنْ عِبَادِهِ وَيَأْخُذُ الصَّدَقَاتِ وَأَنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ (104) Se won ko mo pe dajudaju Allahu Oun l’O n gba ironupiwada lowo awon erusin Re, O si n gba awon ore, ati pe dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
وَقُلِ اعْمَلُوا فَسَيَرَى اللَّهُ عَمَلَكُمْ وَرَسُولُهُ وَالْمُؤْمِنُونَ ۖ وَسَتُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (105) So pe: "E sise. Allahu a ri ise yin, Ojise Re ati awon onigbagbo ododo naa (maa ri i). Won si maa da yin pada sodo Onimo-ikoko-ati-gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
وَآخَرُونَ مُرْجَوْنَ لِأَمْرِ اللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمْ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (106) Won so oro awon yooku ro na fun ase Allahu; yala ki O je won niya tabi ki O gba ironupiwada won. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مَسْجِدًا ضِرَارًا وَكُفْرًا وَتَفْرِيقًا بَيْنَ الْمُؤْمِنِينَ وَإِرْصَادًا لِّمَنْ حَارَبَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ مِن قَبْلُ ۚ وَلَيَحْلِفُنَّ إِنْ أَرَدْنَا إِلَّا الْحُسْنَىٰ ۖ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ (107) Awon t’o ko mosalasi lati fi da inira ati aigbagbo sile ati lati fi se opinya laaarin awon onigbagbo ododo ati lati fi se ibuba fun awon t’o gbogun ti Allahu ati Ojise Re ni isaaju – dajudaju won n bura pe “A o gbero kini kan bi ko se ohun rere.” – Allahu si n jerii pe dajudaju opuro ni won |
لَا تَقُمْ فِيهِ أَبَدًا ۚ لَّمَسْجِدٌ أُسِّسَ عَلَى التَّقْوَىٰ مِنْ أَوَّلِ يَوْمٍ أَحَقُّ أَن تَقُومَ فِيهِ ۚ فِيهِ رِجَالٌ يُحِبُّونَ أَن يَتَطَهَّرُوا ۚ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُطَّهِّرِينَ (108) Ma se duro (kirun) ninu re laelae. Dajudaju mosalasi ti won ba fi ipile re lele lori iberu Allahu lati ojo akoko l’o letoo julo pe ki o duro (kirun) ninu re. Awon eniyan t’o nifee lati maa se imora wa ninu re. Allahu si feran awon olusemora |
أَفَمَنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ تَقْوَىٰ مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانٍ خَيْرٌ أَم مَّنْ أَسَّسَ بُنْيَانَهُ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٍ فَانْهَارَ بِهِ فِي نَارِ جَهَنَّمَ ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (109) Nje eni ti o fi ipile ile mimo tire lele lori iberu Allahu ati iyonu (Re) l’o loore julo ni tabi eni ti o fi ipile ile mimo tire lele ni egbe kan leti ogbun t’o maa ye lule, ti o si maa ye e lese sinu ina Jahanamo? Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi |
لَا يَزَالُ بُنْيَانُهُمُ الَّذِي بَنَوْا رِيبَةً فِي قُلُوبِهِمْ إِلَّا أَن تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (110) Ile won ti won mo kale ko nii ye ko iyemeji sinu okan won titi okan won yoo fi ja kelekele. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
۞ إِنَّ اللَّهَ اشْتَرَىٰ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ أَنفُسَهُمْ وَأَمْوَالَهُم بِأَنَّ لَهُمُ الْجَنَّةَ ۚ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَيَقْتُلُونَ وَيُقْتَلُونَ ۖ وَعْدًا عَلَيْهِ حَقًّا فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنجِيلِ وَالْقُرْآنِ ۚ وَمَنْ أَوْفَىٰ بِعَهْدِهِ مِنَ اللَّهِ ۚ فَاسْتَبْشِرُوا بِبَيْعِكُمُ الَّذِي بَايَعْتُم بِهِ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (111) Dajudaju Allahu ra emi awon onigbagbo ododo ati dukia won nitori pe dajudaju tiwon ni Ogba Idera. Won n jagun loju ona (esin) Allahu; won n pa ota esin, won si n pa awon naa. (O je) adehun lodo Allahu. (O je) ododo ninu at-Taorah, al-’Injil ati al-Ƙur’an. Ta si ni o le mu adehun re se ju Allahu? Nitori naa, e dunnu si okowo yin ti e (fi emi ati dukia yin) se. Iyen, ohun si ni erenje nla |
التَّائِبُونَ الْعَابِدُونَ الْحَامِدُونَ السَّائِحُونَ الرَّاكِعُونَ السَّاجِدُونَ الْآمِرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَالنَّاهُونَ عَنِ الْمُنكَرِ وَالْحَافِظُونَ لِحُدُودِ اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ (112) Awon oluronupiwada, awon olujosin (fun Allahu), awon oludupe (fun Allahu), awon alaaawe, awon oludawote-orunkun (lori irun), awon oluforikanle (fun Allahu), awon olupase-ohun rere, awon oluko-ohun buruku ati awon oluso-enu-ala ti Allahu gbekale, fun awon onigbagbo ododo (wonyi) ni iro idunnu (Ogba Idera) |
مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَن يَسْتَغْفِرُوا لِلْمُشْرِكِينَ وَلَوْ كَانُوا أُولِي قُرْبَىٰ مِن بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُمْ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ (113) Ko ye fun Anabi ati awon t’o gbagbo lododo lati toro aforijin fun awon osebo, won ibaa je ebi, leyin ti o ti han si won pe dajudaju ero inu ina Jehim ni won |
وَمَا كَانَ اسْتِغْفَارُ إِبْرَاهِيمَ لِأَبِيهِ إِلَّا عَن مَّوْعِدَةٍ وَعَدَهَا إِيَّاهُ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُ أَنَّهُ عَدُوٌّ لِّلَّهِ تَبَرَّأَ مِنْهُ ۚ إِنَّ إِبْرَاهِيمَ لَأَوَّاهٌ حَلِيمٌ (114) Ati pe aforijin ti (Anabi) ’Ibrohim toro fun baba re ko si je kini kan bi ko se nitori adehun t’o se fun un. Sugbon nigba ti o han si i pe dajudaju ota Allahu ni (baba re), o yowo yose kuro ninu re. Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim ni oluraworase, olufarada |
وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُضِلَّ قَوْمًا بَعْدَ إِذْ هَدَاهُمْ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُم مَّا يَتَّقُونَ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ (115) Allahu ki i mu isina ba ijo kan, leyin igba ti O ti to won sona, titi (Allahu) yoo fi se alaye nnkan ti won maa sora fun fun won. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
إِنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۚ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ (116) Dajudaju Allahu l’o ni ijoba awon sanmo ati ile. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu |
لَّقَد تَّابَ اللَّهُ عَلَى النَّبِيِّ وَالْمُهَاجِرِينَ وَالْأَنصَارِ الَّذِينَ اتَّبَعُوهُ فِي سَاعَةِ الْعُسْرَةِ مِن بَعْدِ مَا كَادَ يَزِيغُ قُلُوبُ فَرِيقٍ مِّنْهُمْ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّهُ بِهِمْ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ (117) Dajudaju Allahu ti gba ironupiwada Anabi, awon Muhajirun ati awon ’Ansor, awon t’o tele e ni akoko isoro leyin ti okan igun kan ninu won fee yi pada, (amo) leyin naa, Allahu gba ironupiwada won. Dajudaju Oun ni Alaaanu, Asake-orun fun won |
وَعَلَى الثَّلَاثَةِ الَّذِينَ خُلِّفُوا حَتَّىٰ إِذَا ضَاقَتْ عَلَيْهِمُ الْأَرْضُ بِمَا رَحُبَتْ وَضَاقَتْ عَلَيْهِمْ أَنفُسُهُمْ وَظَنُّوا أَن لَّا مَلْجَأَ مِنَ اللَّهِ إِلَّا إِلَيْهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيْهِمْ لِيَتُوبُوا ۚ إِنَّ اللَّهَ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ (118) (O tun gba ironupiwada) awon meta ti A (so oro won ro ninu awon olusaseyin fun ogun Tabuk. Awon musulumi si deye si won) titi ile fi ha mo won tohun ti bi o se feju to. Oro ara won si su ara won. Won si mo (ni amodaju) pe ko si ibusasi kan ti awon fi le sa mo Allahu lowo afi ki won sa si odo Re. Leyin naa, Allahu gba ironupiwada won nitori ki won le maa ronu piwada. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَكُونُوا مَعَ الصَّادِقِينَ (119) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu, ki e si wa pelu awon olododo |
مَا كَانَ لِأَهْلِ الْمَدِينَةِ وَمَنْ حَوْلَهُم مِّنَ الْأَعْرَابِ أَن يَتَخَلَّفُوا عَن رَّسُولِ اللَّهِ وَلَا يَرْغَبُوا بِأَنفُسِهِمْ عَن نَّفْسِهِ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ لَا يُصِيبُهُمْ ظَمَأٌ وَلَا نَصَبٌ وَلَا مَخْمَصَةٌ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَلَا يَطَئُونَ مَوْطِئًا يَغِيظُ الْكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنْ عَدُوٍّ نَّيْلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُم بِهِ عَمَلٌ صَالِحٌ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجْرَ الْمُحْسِنِينَ (120) Ko letoo fun awon ara ilu Modinah ati eni ti o wa ni ayika won ninu awon Larubawa oko lati sa seyin fun Ojise Allahu (nipa ogun esin. Ko si letoo fun won) lati feran emi ara won ju emi re. Iyen nitori pe dajudaju ongbe, inira tabi ebi kan ko nii sele si won loju ogun loju ona (esin) Allahu, tabi won ko nii te ona kan ti n bi awon alaigbagbo ninu, tabi owo won ko nii ba kini kan lara ota afi ki A fi ko ise rere sile fun won. Dajudaju Allahu ko nii fi esan awon oluse-rere rare |
وَلَا يُنفِقُونَ نَفَقَةً صَغِيرَةً وَلَا كَبِيرَةً وَلَا يَقْطَعُونَ وَادِيًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمْ لِيَجْزِيَهُمُ اللَّهُ أَحْسَنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (121) Won ko si nii na owo kekere tabi pupo (fun ogun esin), tabi ki won la afonifoji kan ko ja afi ki A ko o sile fun won nitori ki Allahu le san won ni esan t’o dara julo nipa ohun ti won n se nise |
۞ وَمَا كَانَ الْمُؤْمِنُونَ لِيَنفِرُوا كَافَّةً ۚ فَلَوْلَا نَفَرَ مِن كُلِّ فِرْقَةٍ مِّنْهُمْ طَائِفَةٌ لِّيَتَفَقَّهُوا فِي الدِّينِ وَلِيُنذِرُوا قَوْمَهُمْ إِذَا رَجَعُوا إِلَيْهِمْ لَعَلَّهُمْ يَحْذَرُونَ (122) Gbogbo awon musulumi ko si gbodo da lo si oju ogun esin. Iba suwon ki igun kan ninu won ninu iko kookan jade lati wa agboye nipa esin, ki won si maa se ikilo fun awon eniyan won nigba ti won ba pada sodo won boya won yo le sora se |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا قَاتِلُوا الَّذِينَ يَلُونَكُم مِّنَ الْكُفَّارِ وَلْيَجِدُوا فِيكُمْ غِلْظَةً ۚ وَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَعَ الْمُتَّقِينَ (123) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e gbogun ti awon t’o sunmo yin ninu awon alaigbagbo; ki won ri ilekoko lara yin. Ki e si mo pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluberu (Re) |
وَإِذَا مَا أُنزِلَتْ سُورَةٌ فَمِنْهُم مَّن يَقُولُ أَيُّكُمْ زَادَتْهُ هَٰذِهِ إِيمَانًا ۚ فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا فَزَادَتْهُمْ إِيمَانًا وَهُمْ يَسْتَبْشِرُونَ (124) Nigba ti A ba si so surah kan kale, o n be ninu won eni ti o maa wi pe: “Ta ni ninu yin ni eyi le igbagbo (re) kun?” Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, (ayah naa) yo si le igbagbo (won) kun. Won yo si maa dunnu |
وَأَمَّا الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ فَزَادَتْهُمْ رِجْسًا إِلَىٰ رِجْسِهِمْ وَمَاتُوا وَهُمْ كَافِرُونَ (125) Ni ti awon ti aisan si wa ninu okan won, (ayah naa) yo si se alekun egbin si egbin won. Won yo si ku si ipo alaigbagbo |
أَوَلَا يَرَوْنَ أَنَّهُمْ يُفْتَنُونَ فِي كُلِّ عَامٍ مَّرَّةً أَوْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ لَا يَتُوبُونَ وَلَا هُمْ يَذَّكَّرُونَ (126) Se won ko ri i pe A n dan won wo ni ee kan tabi ee meji ni odoodun. Leyin naa, won ko ronu piwada, won ko si lo iranti |
وَإِذَا مَا أُنزِلَتْ سُورَةٌ نَّظَرَ بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ هَلْ يَرَاكُم مِّنْ أَحَدٍ ثُمَّ انصَرَفُوا ۚ صَرَفَ اللَّهُ قُلُوبَهُم بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَّا يَفْقَهُونَ (127) Ati pe nigba ti A ba so surah kan kale, apa kan won yoo wo apa kan loju (won yo si wi pe): “Se eni kan n wo yin bi?” Leyin naa, won maa peyinda. Allahu si pa okan won da (sodi) nitori pe dajudaju awon ni ijo kan ti ko gbo agboye |
لَقَدْ جَاءَكُمْ رَسُولٌ مِّنْ أَنفُسِكُمْ عَزِيزٌ عَلَيْهِ مَا عَنِتُّمْ حَرِيصٌ عَلَيْكُم بِالْمُؤْمِنِينَ رَءُوفٌ رَّحِيمٌ (128) Dajudaju Ojise kan ti wa ba yin lati aarin yin. Ohun ti o maa ko inira ba yin lagbara lara re. O n se akolekan (oore orun) fun yin; alaaanuati onikee ni fun awon oni gbagbo ododo |
فَإِن تَوَلَّوْا فَقُلْ حَسْبِيَ اللَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ ۖ وَهُوَ رَبُّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ (129) Nitori naa, ti won ba peyinda, so pe: “Allahu to fun mi. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni mo gbarale. Oun si ni Oluwa Ite nla |