×

Surah An-Najm in Yoruba

Quran Yoruba ⮕ Surah Najm

Translation of the Meanings of Surah Najm in Yoruba - اليوربا

The Quran in Yoruba - Surah Najm translated into Yoruba, Surah An-Najm in Yoruba. We provide accurate translation of Surah Najm in Yoruba - اليوربا, Verses 62 - Surah Number 53 - Page 526.

بسم الله الرحمن الرحيم

وَالنَّجْمِ إِذَا هَوَىٰ (1)
(Allahu bura pelu) irawo nigba ti o ba jabo
مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمْ وَمَا غَوَىٰ (2)
Eni yin ko sina, ko si sonu
وَمَا يَنطِقُ عَنِ الْهَوَىٰ (3)
Ati pe ko nii soro ife-inu
إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَىٰ (4)
Ko nii so ohun kan tayo imisi ti A fi ranse si i
عَلَّمَهُ شَدِيدُ الْقُوَىٰ (5)
Alagbara (iyen, molaika Jibril) l’o ko o ni imo (al-Ƙur’an)
ذُو مِرَّةٍ فَاسْتَوَىٰ (6)
O ni alaafia t’o peye. Nitori naa, o duro wamuwamu
وَهُوَ بِالْأُفُقِ الْأَعْلَىٰ (7)
nigba ti o wa ninu ofurufu loke patapata
ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ (8)
Leyin naa, o sun mo (Anabi). O si sokale (to o wa)
فَكَانَ قَابَ قَوْسَيْنِ أَوْ أَدْنَىٰ (9)
(Alafo aarin awon mejeeji) si to iwon orun ofa meji, tabi ki o kere (si iyen)
فَأَوْحَىٰ إِلَىٰ عَبْدِهِ مَا أَوْحَىٰ (10)
Allahu si fun erusin Re ni imisi t’O fun un
مَا كَذَبَ الْفُؤَادُ مَا رَأَىٰ (11)
Okan (Anabi) ko paro ohun t’o ri
أَفَتُمَارُونَهُ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ (12)
Se e oo ja a niyan nipa ohun t’o ri ni
وَلَقَدْ رَآهُ نَزْلَةً أُخْرَىٰ (13)
Ati pe dajudaju o ri i nigba keji Allahu (subhanahu wa ta'ala) ni o ri bi o tile je pe igun yii fi kun un pe okan l’o fi ri Allahu bii oro ti o todo Omo ‘Abbas (rodiyallahu 'anhu) wa pe “Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) fi okan re ri Allahu ni.” Iyen ni pe
عِندَ سِدْرَةِ الْمُنتَهَىٰ (14)
nibi igi sidirah al-Muntaha
عِندَهَا جَنَّةُ الْمَأْوَىٰ (15)
nitosi re ni Ogba Ibugbe (gbere) wa
إِذْ يَغْشَى السِّدْرَةَ مَا يَغْشَىٰ (16)
(Ranti) nigba ti ohun t’o bo igi Sidirah bo o mole
مَا زَاغَ الْبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ (17)
Oju (Anabi) ko ye, ko si tayo enu-ala
لَقَدْ رَأَىٰ مِنْ آيَاتِ رَبِّهِ الْكُبْرَىٰ (18)
Dajudaju o ri ninu awon ami Oluwa re, t’o tobi julo
أَفَرَأَيْتُمُ اللَّاتَ وَالْعُزَّىٰ (19)
E so fun mi nipa orisa Lat ati orisa ‘Uzza
وَمَنَاةَ الثَّالِثَةَ الْأُخْرَىٰ (20)
ati Monah, orisa keta miiran
أَلَكُمُ الذَّكَرُ وَلَهُ الْأُنثَىٰ (21)
Se omokunrin ni tiyin, omobinrin si ni tiRe
تِلْكَ إِذًا قِسْمَةٌ ضِيزَىٰ (22)
Ipin abosi niyen nigba naa
إِنْ هِيَ إِلَّا أَسْمَاءٌ سَمَّيْتُمُوهَا أَنتُمْ وَآبَاؤُكُم مَّا أَنزَلَ اللَّهُ بِهَا مِن سُلْطَانٍ ۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَمَا تَهْوَى الْأَنفُسُ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ الْهُدَىٰ (23)
(Awon oruko orisa wonyen) ko si je kini kan bi ko se awon oruko kan ti eyin ati awon baba yin fi so (awon orisa yin funra yin). Allahu ko si so eri oro kan kale nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso ati ohun ti emi (won) n fe. Imona kuku ti de ba won lati odo Oluwa won
أَمْ لِلْإِنسَانِ مَا تَمَنَّىٰ (24)
Tabi ti eniyan ni nnkan t’o ba n fe
فَلِلَّهِ الْآخِرَةُ وَالْأُولَىٰ (25)
Ti Allahu si ni orun ati aye
۞ وَكَم مِّن مَّلَكٍ فِي السَّمَاوَاتِ لَا تُغْنِي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا إِلَّا مِن بَعْدِ أَن يَأْذَنَ اللَّهُ لِمَن يَشَاءُ وَيَرْضَىٰ (26)
Ati pe meloo meloo ninu awon molaika t’o wa ninu awon sanmo, ti isipe won ko nii ro won loro kini kan ayafi leyin igba ti Allahu ba yonda fun eni ti O ba fe, ti O si yonu si
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ لَيُسَمُّونَ الْمَلَائِكَةَ تَسْمِيَةَ الْأُنثَىٰ (27)
Dajudaju awon ti ko ni igbagbo ododo ninu Ojo Ikeyin, awon ni won n fun awon molaika ni oruko obinrin
وَمَا لَهُم بِهِ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ ۖ وَإِنَّ الظَّنَّ لَا يُغْنِي مِنَ الْحَقِّ شَيْئًا (28)
Ko si imo kan fun won nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si nii roro kini kan lara ododo
فَأَعْرِضْ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا (29)
Nitori naa, seri kuro ni odo eni t’o keyin si iranti Wa, ti ko si gbero kini kan afi isemi aye
ذَٰلِكَ مَبْلَغُهُم مِّنَ الْعِلْمِ ۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اهْتَدَىٰ (30)
Iyen ni odiwon (ati opin) imo won. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa eni t’o mona
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى (31)
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile nitori ki O le san awon t’o se ise aburu ni esan ohun ti won se nise ati nitori ki O le san awon t’o se ise rere ni esan rere
الَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ إِلَّا اللَّمَمَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ وَاسِعُ الْمَغْفِرَةِ ۚ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنشَأَكُم مِّنَ الْأَرْضِ وَإِذْ أَنتُمْ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ ۖ فَلَا تُزَكُّوا أَنفُسَكُمْ ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اتَّقَىٰ (32)
Awon t’o n jinna si ese nla nla ati iwa ibaje ayafi awon ese peepeepe, dajudaju Oluwa re gbooro ni aforijin. O nimo julo nipa yin nigba ti O seda yin lati inu ile ati nigba ti e wa ni ole ninu awon ikun iya yin. Nitori naa, e ma se fora yin mo. O nimo julo nipa eni t’o beru (Re)
أَفَرَأَيْتَ الَّذِي تَوَلَّىٰ (33)
So fun mi nipa eni t’o gbunri (kuro nibi ododo)
وَأَعْطَىٰ قَلِيلًا وَأَكْدَىٰ (34)
ti o fi die tore, ti o si di iyoku mowo
أَعِندَهُ عِلْمُ الْغَيْبِ فَهُوَ يَرَىٰ (35)
Se imo ikoko wa ni odo re, ti o si n ri i (pe elomiiran l’o ma ba oun jiya lorun)
أَمْ لَمْ يُنَبَّأْ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ (36)
Tabi won ko fun un ni iro ohun t’o wa ninu tira (Anabi) Musa ni
وَإِبْرَاهِيمَ الَّذِي وَفَّىٰ (37)
ati (tira Anabi) ’Ibrohim, eni t’o mu (ofin Allahu) se
أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ (38)
pe dajudaju eleru-ese kan ko nii ru eru-ese elomiiran
وَأَن لَّيْسَ لِلْإِنسَانِ إِلَّا مَا سَعَىٰ (39)
Ati pe ko si kini kan fun eniyan afi ohun t’o se nise
وَأَنَّ سَعْيَهُ سَوْفَ يُرَىٰ (40)
Ati pe dajudaju ise re, laipe won maa fi han an
ثُمَّ يُجْزَاهُ الْجَزَاءَ الْأَوْفَىٰ (41)
Leyin naa, won maa san an ni esan re, ni esan t’o kun julo
وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ الْمُنتَهَىٰ (42)
Ati pe dajudaju odo Oluwa re ni opin (irin-ajo eda)
وَأَنَّهُ هُوَ أَضْحَكَ وَأَبْكَىٰ (43)
Dajudaju Oun l’O n pa (eda) ni erin. O si n pa (eda) ni ekun
وَأَنَّهُ هُوَ أَمَاتَ وَأَحْيَا (44)
Dajudaju Oun l’O n so (eda) di oku. O si n so (eda) di alaaye
وَأَنَّهُ خَلَقَ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنثَىٰ (45)
Dajudaju Oun l’O da eda ni orisi meji, okunrin ati obinrin
مِن نُّطْفَةٍ إِذَا تُمْنَىٰ (46)
lati ara ato nigba ti won ba da a sinu apoluke
وَأَنَّ عَلَيْهِ النَّشْأَةَ الْأُخْرَىٰ (47)
Dajudaju Oun l’O maa se iseda ikeyin fun ajinde
وَأَنَّهُ هُوَ أَغْنَىٰ وَأَقْنَىٰ (48)
Dajudaju Oun l’O n se pupo, O si n se kekere (oore fun eda)
وَأَنَّهُ هُوَ رَبُّ الشِّعْرَىٰ (49)
Dajudaju Oun si ni Oluwa irawo Si‘ro (ti won so di orisa)
وَأَنَّهُ أَهْلَكَ عَادًا الْأُولَىٰ (50)
Dajudaju Oun l’O pa iran ‘Ad re, awon eni akoko
وَثَمُودَ فَمَا أَبْقَىٰ (51)
ati iran Thamud, ko si se won ku
وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا هُمْ أَظْلَمَ وَأَطْغَىٰ (52)
ati ijo Nuh t’o siwaju (won), dajudaju won je alabosi julo, won si tayo enu-ala julo
وَالْمُؤْتَفِكَةَ أَهْوَىٰ (53)
ati ilu ti won dawo (ilu Anabi Lut) t’O ye lule (lati oke)
فَغَشَّاهَا مَا غَشَّىٰ (54)
Ohun t’o bo won mole bo won mole
فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ (55)
Nitori naa, ewo ninu idera Oluwa re ni iwo (eniyan) n ja niyan
هَٰذَا نَذِيرٌ مِّنَ النُّذُرِ الْأُولَىٰ (56)
Eyi ni ikilo kan ninu awon ikilo akoko
أَزِفَتِ الْآزِفَةُ (57)
Ohun t’o sunmo sunmo
لَيْسَ لَهَا مِن دُونِ اللَّهِ كَاشِفَةٌ (58)
Leyin Allahu, ko si eni t’o le safi han (Akoko naa)
أَفَمِنْ هَٰذَا الْحَدِيثِ تَعْجَبُونَ (59)
Se oro yii l’o n se yin ni kayefi
وَتَضْحَكُونَ وَلَا تَبْكُونَ (60)
E n rerin-in, e o si sunkun
وَأَنتُمْ سَامِدُونَ (61)
Afonu-fora ni yin
فَاسْجُدُوا لِلَّهِ وَاعْبُدُوا ۩ (62)
Nitori naa, e fori kanle fun Allahu, ki e josin (fun Un)
❮ Previous Next ❯

Surahs from Quran :

1- Fatiha2- Baqarah
3- Al Imran4- Nisa
5- Maidah6- Anam
7- Araf8- Anfal
9- Tawbah10- Yunus
11- Hud12- Yusuf
13- Raad14- Ibrahim
15- Hijr16- Nahl
17- Al Isra18- Kahf
19- Maryam20- TaHa
21- Anbiya22- Hajj
23- Muminun24- An Nur
25- Furqan26- Shuara
27- Naml28- Qasas
29- Ankabut30- Rum
31- Luqman32- Sajdah
33- Ahzab34- Saba
35- Fatir36- Yasin
37- Assaaffat38- Sad
39- Zumar40- Ghafir
41- Fussilat42- shura
43- Zukhruf44- Ad Dukhaan
45- Jathiyah46- Ahqaf
47- Muhammad48- Al Fath
49- Hujurat50- Qaf
51- zariyat52- Tur
53- Najm54- Al Qamar
55- Rahman56- Waqiah
57- Hadid58- Mujadilah
59- Al Hashr60- Mumtahina
61- Saff62- Jumuah
63- Munafiqun64- Taghabun
65- Talaq66- Tahrim
67- Mulk68- Qalam
69- Al-Haqqah70- Maarij
71- Nuh72- Jinn
73- Muzammil74- Muddathir
75- Qiyamah76- Insan
77- Mursalat78- An Naba
79- Naziat80- Abasa
81- Takwir82- Infitar
83- Mutaffifin84- Inshiqaq
85- Buruj86- Tariq
87- Al Ala88- Ghashiya
89- Fajr90- Al Balad
91- Shams92- Lail
93- Duha94- Sharh
95- Tin96- Al Alaq
97- Qadr98- Bayyinah
99- Zalzalah100- Adiyat
101- Qariah102- Takathur
103- Al Asr104- Humazah
105- Al Fil106- Quraysh
107- Maun108- Kawthar
109- Kafirun110- Nasr
111- Masad112- Ikhlas
113- Falaq114- An Nas