وَالنَّجْمِ إِذَا هَوَىٰ (1) (Allahu bura pelu) irawo nigba ti o ba jabo |
مَا ضَلَّ صَاحِبُكُمْ وَمَا غَوَىٰ (2) Eni yin ko sina, ko si sonu |
وَمَا يَنطِقُ عَنِ الْهَوَىٰ (3) Ati pe ko nii soro ife-inu |
إِنْ هُوَ إِلَّا وَحْيٌ يُوحَىٰ (4) Ko nii so ohun kan tayo imisi ti A fi ranse si i |
عَلَّمَهُ شَدِيدُ الْقُوَىٰ (5) Alagbara (iyen, molaika Jibril) l’o ko o ni imo (al-Ƙur’an) |
ذُو مِرَّةٍ فَاسْتَوَىٰ (6) O ni alaafia t’o peye. Nitori naa, o duro wamuwamu |
وَهُوَ بِالْأُفُقِ الْأَعْلَىٰ (7) nigba ti o wa ninu ofurufu loke patapata |
ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّىٰ (8) Leyin naa, o sun mo (Anabi). O si sokale (to o wa) |
فَكَانَ قَابَ قَوْسَيْنِ أَوْ أَدْنَىٰ (9) (Alafo aarin awon mejeeji) si to iwon orun ofa meji, tabi ki o kere (si iyen) |
فَأَوْحَىٰ إِلَىٰ عَبْدِهِ مَا أَوْحَىٰ (10) Allahu si fun erusin Re ni imisi t’O fun un |
مَا كَذَبَ الْفُؤَادُ مَا رَأَىٰ (11) Okan (Anabi) ko paro ohun t’o ri |
أَفَتُمَارُونَهُ عَلَىٰ مَا يَرَىٰ (12) Se e oo ja a niyan nipa ohun t’o ri ni |
وَلَقَدْ رَآهُ نَزْلَةً أُخْرَىٰ (13) Ati pe dajudaju o ri i nigba keji Allahu (subhanahu wa ta'ala) ni o ri bi o tile je pe igun yii fi kun un pe okan l’o fi ri Allahu bii oro ti o todo Omo ‘Abbas (rodiyallahu 'anhu) wa pe “Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) fi okan re ri Allahu ni.” Iyen ni pe |
عِندَ سِدْرَةِ الْمُنتَهَىٰ (14) nibi igi sidirah al-Muntaha |
عِندَهَا جَنَّةُ الْمَأْوَىٰ (15) nitosi re ni Ogba Ibugbe (gbere) wa |
إِذْ يَغْشَى السِّدْرَةَ مَا يَغْشَىٰ (16) (Ranti) nigba ti ohun t’o bo igi Sidirah bo o mole |
مَا زَاغَ الْبَصَرُ وَمَا طَغَىٰ (17) Oju (Anabi) ko ye, ko si tayo enu-ala |
لَقَدْ رَأَىٰ مِنْ آيَاتِ رَبِّهِ الْكُبْرَىٰ (18) Dajudaju o ri ninu awon ami Oluwa re, t’o tobi julo |
أَفَرَأَيْتُمُ اللَّاتَ وَالْعُزَّىٰ (19) E so fun mi nipa orisa Lat ati orisa ‘Uzza |
وَمَنَاةَ الثَّالِثَةَ الْأُخْرَىٰ (20) ati Monah, orisa keta miiran |
أَلَكُمُ الذَّكَرُ وَلَهُ الْأُنثَىٰ (21) Se omokunrin ni tiyin, omobinrin si ni tiRe |
تِلْكَ إِذًا قِسْمَةٌ ضِيزَىٰ (22) Ipin abosi niyen nigba naa |
إِنْ هِيَ إِلَّا أَسْمَاءٌ سَمَّيْتُمُوهَا أَنتُمْ وَآبَاؤُكُم مَّا أَنزَلَ اللَّهُ بِهَا مِن سُلْطَانٍ ۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَمَا تَهْوَى الْأَنفُسُ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُم مِّن رَّبِّهِمُ الْهُدَىٰ (23) (Awon oruko orisa wonyen) ko si je kini kan bi ko se awon oruko kan ti eyin ati awon baba yin fi so (awon orisa yin funra yin). Allahu ko si so eri oro kan kale nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso ati ohun ti emi (won) n fe. Imona kuku ti de ba won lati odo Oluwa won |
أَمْ لِلْإِنسَانِ مَا تَمَنَّىٰ (24) Tabi ti eniyan ni nnkan t’o ba n fe |
فَلِلَّهِ الْآخِرَةُ وَالْأُولَىٰ (25) Ti Allahu si ni orun ati aye |
۞ وَكَم مِّن مَّلَكٍ فِي السَّمَاوَاتِ لَا تُغْنِي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا إِلَّا مِن بَعْدِ أَن يَأْذَنَ اللَّهُ لِمَن يَشَاءُ وَيَرْضَىٰ (26) Ati pe meloo meloo ninu awon molaika t’o wa ninu awon sanmo, ti isipe won ko nii ro won loro kini kan ayafi leyin igba ti Allahu ba yonda fun eni ti O ba fe, ti O si yonu si |
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ لَيُسَمُّونَ الْمَلَائِكَةَ تَسْمِيَةَ الْأُنثَىٰ (27) Dajudaju awon ti ko ni igbagbo ododo ninu Ojo Ikeyin, awon ni won n fun awon molaika ni oruko obinrin |
وَمَا لَهُم بِهِ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ ۖ وَإِنَّ الظَّنَّ لَا يُغْنِي مِنَ الْحَقِّ شَيْئًا (28) Ko si imo kan fun won nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si nii roro kini kan lara ododo |
فَأَعْرِضْ عَن مَّن تَوَلَّىٰ عَن ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا (29) Nitori naa, seri kuro ni odo eni t’o keyin si iranti Wa, ti ko si gbero kini kan afi isemi aye |
ذَٰلِكَ مَبْلَغُهُم مِّنَ الْعِلْمِ ۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اهْتَدَىٰ (30) Iyen ni odiwon (ati opin) imo won. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa eni t’o mona |
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى (31) Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile nitori ki O le san awon t’o se ise aburu ni esan ohun ti won se nise ati nitori ki O le san awon t’o se ise rere ni esan rere |
الَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ إِلَّا اللَّمَمَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ وَاسِعُ الْمَغْفِرَةِ ۚ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنشَأَكُم مِّنَ الْأَرْضِ وَإِذْ أَنتُمْ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ ۖ فَلَا تُزَكُّوا أَنفُسَكُمْ ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اتَّقَىٰ (32) Awon t’o n jinna si ese nla nla ati iwa ibaje ayafi awon ese peepeepe, dajudaju Oluwa re gbooro ni aforijin. O nimo julo nipa yin nigba ti O seda yin lati inu ile ati nigba ti e wa ni ole ninu awon ikun iya yin. Nitori naa, e ma se fora yin mo. O nimo julo nipa eni t’o beru (Re) |
أَفَرَأَيْتَ الَّذِي تَوَلَّىٰ (33) So fun mi nipa eni t’o gbunri (kuro nibi ododo) |
وَأَعْطَىٰ قَلِيلًا وَأَكْدَىٰ (34) ti o fi die tore, ti o si di iyoku mowo |
أَعِندَهُ عِلْمُ الْغَيْبِ فَهُوَ يَرَىٰ (35) Se imo ikoko wa ni odo re, ti o si n ri i (pe elomiiran l’o ma ba oun jiya lorun) |
أَمْ لَمْ يُنَبَّأْ بِمَا فِي صُحُفِ مُوسَىٰ (36) Tabi won ko fun un ni iro ohun t’o wa ninu tira (Anabi) Musa ni |
وَإِبْرَاهِيمَ الَّذِي وَفَّىٰ (37) ati (tira Anabi) ’Ibrohim, eni t’o mu (ofin Allahu) se |
أَلَّا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ (38) pe dajudaju eleru-ese kan ko nii ru eru-ese elomiiran |
وَأَن لَّيْسَ لِلْإِنسَانِ إِلَّا مَا سَعَىٰ (39) Ati pe ko si kini kan fun eniyan afi ohun t’o se nise |
وَأَنَّ سَعْيَهُ سَوْفَ يُرَىٰ (40) Ati pe dajudaju ise re, laipe won maa fi han an |
ثُمَّ يُجْزَاهُ الْجَزَاءَ الْأَوْفَىٰ (41) Leyin naa, won maa san an ni esan re, ni esan t’o kun julo |
وَأَنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ الْمُنتَهَىٰ (42) Ati pe dajudaju odo Oluwa re ni opin (irin-ajo eda) |
وَأَنَّهُ هُوَ أَضْحَكَ وَأَبْكَىٰ (43) Dajudaju Oun l’O n pa (eda) ni erin. O si n pa (eda) ni ekun |
وَأَنَّهُ هُوَ أَمَاتَ وَأَحْيَا (44) Dajudaju Oun l’O n so (eda) di oku. O si n so (eda) di alaaye |
وَأَنَّهُ خَلَقَ الزَّوْجَيْنِ الذَّكَرَ وَالْأُنثَىٰ (45) Dajudaju Oun l’O da eda ni orisi meji, okunrin ati obinrin |
مِن نُّطْفَةٍ إِذَا تُمْنَىٰ (46) lati ara ato nigba ti won ba da a sinu apoluke |
وَأَنَّ عَلَيْهِ النَّشْأَةَ الْأُخْرَىٰ (47) Dajudaju Oun l’O maa se iseda ikeyin fun ajinde |
وَأَنَّهُ هُوَ أَغْنَىٰ وَأَقْنَىٰ (48) Dajudaju Oun l’O n se pupo, O si n se kekere (oore fun eda) |
وَأَنَّهُ هُوَ رَبُّ الشِّعْرَىٰ (49) Dajudaju Oun si ni Oluwa irawo Si‘ro (ti won so di orisa) |
وَأَنَّهُ أَهْلَكَ عَادًا الْأُولَىٰ (50) Dajudaju Oun l’O pa iran ‘Ad re, awon eni akoko |
وَثَمُودَ فَمَا أَبْقَىٰ (51) ati iran Thamud, ko si se won ku |
وَقَوْمَ نُوحٍ مِّن قَبْلُ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا هُمْ أَظْلَمَ وَأَطْغَىٰ (52) ati ijo Nuh t’o siwaju (won), dajudaju won je alabosi julo, won si tayo enu-ala julo |
وَالْمُؤْتَفِكَةَ أَهْوَىٰ (53) ati ilu ti won dawo (ilu Anabi Lut) t’O ye lule (lati oke) |
فَغَشَّاهَا مَا غَشَّىٰ (54) Ohun t’o bo won mole bo won mole |
فَبِأَيِّ آلَاءِ رَبِّكَ تَتَمَارَىٰ (55) Nitori naa, ewo ninu idera Oluwa re ni iwo (eniyan) n ja niyan |
هَٰذَا نَذِيرٌ مِّنَ النُّذُرِ الْأُولَىٰ (56) Eyi ni ikilo kan ninu awon ikilo akoko |
أَزِفَتِ الْآزِفَةُ (57) Ohun t’o sunmo sunmo |
لَيْسَ لَهَا مِن دُونِ اللَّهِ كَاشِفَةٌ (58) Leyin Allahu, ko si eni t’o le safi han (Akoko naa) |
أَفَمِنْ هَٰذَا الْحَدِيثِ تَعْجَبُونَ (59) Se oro yii l’o n se yin ni kayefi |
وَتَضْحَكُونَ وَلَا تَبْكُونَ (60) E n rerin-in, e o si sunkun |
وَأَنتُمْ سَامِدُونَ (61) Afonu-fora ni yin |
فَاسْجُدُوا لِلَّهِ وَاعْبُدُوا ۩ (62) Nitori naa, e fori kanle fun Allahu, ki e josin (fun Un) |