Quran with Yoruba translation - Surah Hud ayat 31 - هُود - Page - Juz 12
﴿وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ إِنِّي مَلَكٞ وَلَآ أَقُولُ لِلَّذِينَ تَزۡدَرِيٓ أَعۡيُنُكُمۡ لَن يُؤۡتِيَهُمُ ٱللَّهُ خَيۡرًاۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا فِيٓ أَنفُسِهِمۡ إِنِّيٓ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ ﴾
[هُود: 31]
﴿ولا أقول لكم عندي خزائن الله ولا أعلم الغيب ولا أقول إني﴾ [هُود: 31]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Èmi kò sì sọ fun yín pé àwọn ilé-owó Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan t’ó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí |