Quran with Yoruba translation - Surah Hud ayat 7 - هُود - Page - Juz 12
﴿وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ وَكَانَ عَرۡشُهُۥ عَلَى ٱلۡمَآءِ لِيَبۡلُوَكُمۡ أَيُّكُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗاۗ وَلَئِن قُلۡتَ إِنَّكُم مَّبۡعُوثُونَ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡمَوۡتِ لَيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ ﴾
[هُود: 7]
﴿وهو الذي خلق السموات والأرض في ستة أيام وكان عرشه على الماء﴾ [هُود: 7]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) – nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín l’ó dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.” |