Quran with Yoruba translation - Surah Ar-Ra‘d ayat 4 - الرَّعد - Page - Juz 13
﴿وَفِي ٱلۡأَرۡضِ قِطَعٞ مُّتَجَٰوِرَٰتٞ وَجَنَّٰتٞ مِّنۡ أَعۡنَٰبٖ وَزَرۡعٞ وَنَخِيلٞ صِنۡوَانٞ وَغَيۡرُ صِنۡوَانٖ يُسۡقَىٰ بِمَآءٖ وَٰحِدٖ وَنُفَضِّلُ بَعۡضَهَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلۡأُكُلِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ ﴾
[الرَّعد: 4]
﴿وفي الأرض قطع متجاورات وجنات من أعناب وزرع ونخيل صنوان وغير صنوان﴾ [الرَّعد: 4]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) t’ó wà nítòsí ara wọn àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù t’ó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fi omi ẹyọ kan wọn. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi jíjẹ. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ t’ó ní làákàyè |