Quran with Yoruba translation - Surah An-Nahl ayat 75 - النَّحل - Page - Juz 14
﴿۞ ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلًا عَبۡدٗا مَّمۡلُوكٗا لَّا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَمَن رَّزَقۡنَٰهُ مِنَّا رِزۡقًا حَسَنٗا فَهُوَ يُنفِقُ مِنۡهُ سِرّٗا وَجَهۡرًاۖ هَلۡ يَسۡتَوُۥنَۚ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ﴾
[النَّحل: 75]
﴿ضرب الله مثلا عبدا مملوكا لا يقدر على شيء ومن رزقناه منا﴾ [النَّحل: 75]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ẹrú kan tí ó wà lábẹ́ ọ̀gá, tí kò sì lè dá n̄ǹkan kan ṣe àti ẹni tí A fún ní arísìkí t’ó dára láti ọ̀dọ̀ wa, tí ó sì ń ná nínú rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Ṣé wọ́n dọ́gba bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀ |