أَتَىٰ أَمْرُ اللَّهِ فَلَا تَسْتَعْجِلُوهُ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ (1) Ase Allahu de tan. E ma wule wa a pelu ikanju. Mimo ni fun Un. O si ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
يُنَزِّلُ الْمَلَائِكَةَ بِالرُّوحِ مِنْ أَمْرِهِ عَلَىٰ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ أَنْ أَنذِرُوا أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا أَنَا فَاتَّقُونِ (2) (Allahu) n fi ase Re so molaika (Jibril) kale lati maa mu imisi wa diedie fun enikeni ti O ba fe (bee fun) ninu awon erusin Re nitori ki e le fi se ikilo pe: “Dajudaju ko si olohun kan ti ijosin to si afi Emi. Nitori naa, e beru Mi.” |
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ تَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ (3) O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
خَلَقَ الْإِنسَانَ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ (4) O da eniyan lati inu ato. (Eniyan) si di olujiyan ponnbele (nipa Ajinde) |
وَالْأَنْعَامَ خَلَقَهَا ۗ لَكُمْ فِيهَا دِفْءٌ وَمَنَافِعُ وَمِنْهَا تَأْكُلُونَ (5) Awon eran-osin, O seda won. Aso otutu ati awon anfaani (miiran) n be fun yin lara won. Ati pe e n je ninu won |
وَلَكُمْ فِيهَا جَمَالٌ حِينَ تُرِيحُونَ وَحِينَ تَسْرَحُونَ (6) Oso tun n be fun yin lara won nigba ti e ba n da won lo (si ile won) ati nigba ti e ba n ko won jade lo jeko |
وَتَحْمِلُ أَثْقَالَكُمْ إِلَىٰ بَلَدٍ لَّمْ تَكُونُوا بَالِغِيهِ إِلَّا بِشِقِّ الْأَنفُسِ ۚ إِنَّ رَبَّكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ (7) Won si n ru awon eru yin t’o wuwo lo si ilu kan ti e o le de afi pelu wahala emi. Dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee |
وَالْخَيْلَ وَالْبِغَالَ وَالْحَمِيرَ لِتَرْكَبُوهَا وَزِينَةً ۚ وَيَخْلُقُ مَا لَا تَعْلَمُونَ (8) (O seda) esin, ibaaka ati ketekete nitori ki e le gun won. (Won tun je) oso. O tun n seda ohun ti e o mo |
وَعَلَى اللَّهِ قَصْدُ السَّبِيلِ وَمِنْهَا جَائِرٌ ۚ وَلَوْ شَاءَ لَهَدَاكُمْ أَجْمَعِينَ (9) Allahu l’O n salaye (’Islam) ona taara. Awon ona esin wiwo tun wa (loto) . Ti O ba fe bee ni, iba to gbogbo yin si ona (esin ’Islam) |
هُوَ الَّذِي أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً ۖ لَّكُم مِّنْهُ شَرَابٌ وَمِنْهُ شَجَرٌ فِيهِ تُسِيمُونَ (10) Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. Mimu wa fun yin ninu re. Igi eweko tun n wu jade lati inu re. E si n fi bo awon eran-osin |
يُنبِتُ لَكُم بِهِ الزَّرْعَ وَالزَّيْتُونَ وَالنَّخِيلَ وَالْأَعْنَابَ وَمِن كُلِّ الثَّمَرَاتِ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (11) (Allahu) tun n fi (omi yii) hu awon irugbin, igi ororo zaetun, igi dabinu, igi ajara ati gbogbo awon eso (yooku) jade fun yin. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
وَسَخَّرَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ وَالشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ وَالنُّجُومُ مُسَخَّرَاتٌ بِأَمْرِهِ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (12) O ro oru, osan, oorun, osupa ati awon irawo fun yin pelu ase Re. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye |
وَمَا ذَرَأَ لَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُخْتَلِفًا أَلْوَانُهُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّقَوْمٍ يَذَّكَّرُونَ (13) Ati ohun ti O tun seda re fun yin lori ile, ti awon awo re je orisirisi. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n lo iranti |
وَهُوَ الَّذِي سَخَّرَ الْبَحْرَ لِتَأْكُلُوا مِنْهُ لَحْمًا طَرِيًّا وَتَسْتَخْرِجُوا مِنْهُ حِلْيَةً تَلْبَسُونَهَا وَتَرَى الْفُلْكَ مَوَاخِرَ فِيهِ وَلِتَبْتَغُوا مِن فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ (14) Oun ni Eni ti O ro agbami odo nitori ki e le je eran (eja) tutu ati nitori ki e le mu nnkan oso ti e oo maa wo sara jade lati inu (odo), - o si maa ri awon oko oju-omi ti yoo maa la oju omi koja lo bo – ati nitori ki e le wa ninu awon ajulo oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Allahu) |
وَأَلْقَىٰ فِي الْأَرْضِ رَوَاسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمْ وَأَنْهَارًا وَسُبُلًا لَّعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ (15) O si fi awon apata t’o duro gbagidi sori ile ki o ma fi le mi mo yin lese ati awon odo ati awon oju-ona nitori ki e le da oju ona mo |
وَعَلَامَاتٍ ۚ وَبِالنَّجْمِ هُمْ يَهْتَدُونَ (16) ati awon ami opopona (fun itosona irin osan). Won tun n fi irawo da oju ona mo (lale) |
أَفَمَن يَخْلُقُ كَمَن لَّا يَخْلُقُ ۗ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ (17) Nje Eni ti O da eda da bi eni ti ko da eda bi? Nitori naa, se e o nii lo iranti ni |
وَإِن تَعُدُّوا نِعْمَةَ اللَّهِ لَا تُحْصُوهَا ۗ إِنَّ اللَّهَ لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ (18) Ti e ba sonka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju Allahu ma ni Alaforijin, Onikee |
وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعْلِنُونَ (19) Ati pe Allahu mo ohun ti e n fi pamo ati ohun ti e n se afihan re |
وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَا يَخْلُقُونَ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ (20) Awon (orisa) ti won n pe leyin Allahu; won ko le da kini kan. Allahu l’O si seda won |
أَمْوَاتٌ غَيْرُ أَحْيَاءٍ ۖ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ (21) Oku (ni won), won ki i se alaaye. Won ko si mo akoko ti A oo gbe won dide. won ki i se alaaye.” ko so iku Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) di ohun t’o ti sele. Sebi awon molaika kan wa lara nnkan ti awon eniyan n josin fun leyin Allahu. Se oku ni awon molaika naa ni tabi alaaye? A o kuku ti i gbo iku molaika kan kan ri. Bakan naa as-Saton ar-Rojim je okan pataki ninu ohun ti awon eniyan n josin fun. Se oku ni Saeton naa ni tabi alaaye? Rara bi Allahu se fe.” Ko wa si eri taara kan kan t’o fi rinle pe Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti ku bi ko se ayah oniponna eyi ti a ti se alaye lori re siwaju ninu itose-oro fun surah ali-’Imron 3:55. Dipo ki a ri ayah kan tabi hadith kan taara lori iku Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) hadith t’o n fi ipadabo re rinle l’a n ri. Eni ti ko i ku l’o si le pada wa sile aye. ” ninu ayah naa ki i se itumo adamo. Idi ni pe ere ti ko si emi lara re ni awon orisa naa. Ipo oku eni ti ko le soro |
إِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۚ فَالَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٌ وَهُم مُّسْتَكْبِرُونَ (22) Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Amo awon ti ko ni igbagbo ninu Ojo Ikeyin ni okan won tako o, ti won si n segberaga |
لَا جَرَمَ أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْتَكْبِرِينَ (23) Ko si tabi-sugbon, dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n se afihan re. Ati pe dajudaju (Allahu) ko nifee awon onigbeeraga |
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَا أَنزَلَ رَبُّكُمْ ۙ قَالُوا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ (24) Nigba ti won ba so fun won pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Akosile alo awon eni akoko ni.” |
لِيَحْمِلُوا أَوْزَارَهُمْ كَامِلَةً يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۙ وَمِنْ أَوْزَارِ الَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ أَلَا سَاءَ مَا يَزِرُونَ (25) (Won so bee) nitori ki won le ru eru ese tiwon ni pipe perepere ni Ojo Ajinde ati (nitori ki won le ru) ninu eru ese awon ti won n si lona pelu ainimo. Gbo, ohun ti won yoo ru ni ese, o buru |
قَدْ مَكَرَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَأَتَى اللَّهُ بُنْيَانَهُم مِّنَ الْقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيْهِمُ السَّقْفُ مِن فَوْقِهِمْ وَأَتَاهُمُ الْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ (26) Awon t’o siwaju won kuku dete. Allahu si da ile won wo lati ipile. Orule si wo lu won mole lati oke won. Ati pe iya de ba won ni aye ti won ko ti fura |
ثُمَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ يُخْزِيهِمْ وَيَقُولُ أَيْنَ شُرَكَائِيَ الَّذِينَ كُنتُمْ تُشَاقُّونَ فِيهِمْ ۚ قَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ إِنَّ الْخِزْيَ الْيَوْمَ وَالسُّوءَ عَلَى الْكَافِرِينَ (27) Leyin naa, ni Ojo Ajinde (Allahu) yoo yepere won. O si maa so pe: “Ibo ni awon (ti e so di) akegbe Mi wa, awon ti e ti tori won yapa (Mi)?” Awon ti A fun ni imo esin yo si so pe: “Dajudaju abuku ati aburu ojo oni wa fun awon alaigbagbo.” |
الَّذِينَ تَتَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ ظَالِمِي أَنفُسِهِمْ ۖ فَأَلْقَوُا السَّلَمَ مَا كُنَّا نَعْمَلُ مِن سُوءٍ ۚ بَلَىٰ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (28) (Awon ni) awon ti molaika n pa nigba ti won n sabosi si emi ara won lowo. Ni asiko yii ni won juwo juse sile (won si wi pe): “Awa ko se ise aburu kan kan.” Rara (e sise aburu)! Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti e n se nise |
فَادْخُلُوا أَبْوَابَ جَهَنَّمَ خَالِدِينَ فِيهَا ۖ فَلَبِئْسَ مَثْوَى الْمُتَكَبِّرِينَ (29) Nitori naa, e wo awon enu ona Ina lo, olusegbere ni yin ninu re. Ibugbe awon onigbeeraga si buru |
۞ وَقِيلَ لِلَّذِينَ اتَّقَوْا مَاذَا أَنزَلَ رَبُّكُمْ ۚ قَالُوا خَيْرًا ۗ لِّلَّذِينَ أَحْسَنُوا فِي هَٰذِهِ الدُّنْيَا حَسَنَةٌ ۚ وَلَدَارُ الْآخِرَةِ خَيْرٌ ۚ وَلَنِعْمَ دَارُ الْمُتَّقِينَ (30) Won so fun awon t’o beru (Allahu) pe: “Ki ni Oluwa yin sokale? Won a wi pe: “Rere ni.” Rere ti wa fun awon t’o se rere ni ile aye yii. Dajudaju Ile Ikeyin loore julo. Ati pe dajudaju ile awon oluberu (Allahu) dara |
جَنَّاتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ لَهُمْ فِيهَا مَا يَشَاءُونَ ۚ كَذَٰلِكَ يَجْزِي اللَّهُ الْمُتَّقِينَ (31) Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon odo yo si maa san ni isale re. Ohunkohun ti won ba n fe maa wa fun won ninu re. Bayen ni Allahu se n san esan rere fun awon oluberu (Re) |
الَّذِينَ تَتَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ طَيِّبِينَ ۙ يَقُولُونَ سَلَامٌ عَلَيْكُمُ ادْخُلُوا الْجَنَّةَ بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (32) Awon ti molaika n pa, nigba ti won n se rere lowo, (awon molaika) n so pe: “Alaafia fun yin. E wo inu Ogba Idera nitori ohun ti e n se nise.” |
هَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا أَن تَأْتِيَهُمُ الْمَلَائِكَةُ أَوْ يَأْتِيَ أَمْرُ رَبِّكَ ۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ اللَّهُ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ (33) Se won n reti ohun kan yato si pe ki awon molaika wa ba won tabi ki ase Oluwa re de? Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Allahu ko si se abosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si |
فَأَصَابَهُمْ سَيِّئَاتُ مَا عَمِلُوا وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ (34) Nitori naa, awon aburu ohun ti won se nise sele si won. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po |
وَقَالَ الَّذِينَ أَشْرَكُوا لَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا عَبَدْنَا مِن دُونِهِ مِن شَيْءٍ نَّحْنُ وَلَا آبَاؤُنَا وَلَا حَرَّمْنَا مِن دُونِهِ مِن شَيْءٍ ۚ كَذَٰلِكَ فَعَلَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ فَهَلْ عَلَى الرُّسُلِ إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ (35) Awon ti won ba Allahu wa akegbe yo si wi pe: “Ti o ba je pe Allahu fe ni awa iba ti josin fun kini kan leyin Re, awa ati awon baba wa. Bakan naa, awa iba ti se kini kan ni eewo leyin Re.” Bayen ni awon t’o siwaju won ti se. Nje ojuse kan wa fun awon Ojise bi ko se ise-jije ponnbele |
وَلَقَدْ بَعَثْنَا فِي كُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولًا أَنِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاجْتَنِبُوا الطَّاغُوتَ ۖ فَمِنْهُم مَّنْ هَدَى اللَّهُ وَمِنْهُم مَّنْ حَقَّتْ عَلَيْهِ الضَّلَالَةُ ۚ فَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُكَذِّبِينَ (36) Dajudaju A ti gbe Ojise dide ninu ijo kookan (lati jise) pe: “E josin fun Allahu. Ki e si jinna si awon orisa.” Nitori naa, o wa ninu won, eni ti Allahu to si ona. O si wa ninu won, eni ti isina ko le lori. Nitori naa, e rin kiri lori ile, ki e si woye si bi atubotan awon t’o pe awon Ojise ni opuro se ri |
إِن تَحْرِصْ عَلَىٰ هُدَاهُمْ فَإِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَن يُضِلُّ ۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ (37) Ti o ba n soju kokoro si imona won, eni ti Allahu ba si lona, dajudaju ko nii fi mona, ko si nii si awon alaranse kan kan fun won |
وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ ۙ لَا يَبْعَثُ اللَّهُ مَن يَمُوتُ ۚ بَلَىٰ وَعْدًا عَلَيْهِ حَقًّا وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ (38) Won si fi Allahu bura ti ibura won si lagbara gan-an pe: “Allahu ko nii gbe eni ti o ku dide.” Ko ri bee, (ajinde je) adehun lodo Allahu. Ododo si ni, sugbon opolopo eniyan ko mo |
لِيُبَيِّنَ لَهُمُ الَّذِي يَخْتَلِفُونَ فِيهِ وَلِيَعْلَمَ الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّهُمْ كَانُوا كَاذِبِينَ (39) (Allahu yoo gbe eda dide) nitori ki O le salaye ohun ti won n yapa enu si fun won ati nitori ki awon t’o sai gbagbo le mo pe dajudaju awon ni won je opuro |
إِنَّمَا قَوْلُنَا لِشَيْءٍ إِذَا أَرَدْنَاهُ أَن نَّقُولَ لَهُ كُن فَيَكُونُ (40) Oro Wa fun kini kan nigba ti A ba gbero re ni pe, A maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee.” |
وَالَّذِينَ هَاجَرُوا فِي اللَّهِ مِن بَعْدِ مَا ظُلِمُوا لَنُبَوِّئَنَّهُمْ فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً ۖ وَلَأَجْرُ الْآخِرَةِ أَكْبَرُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ (41) Awon t’o gbe ilu won ju sile nitori ti Allahu, leyin ti awon alaigbagbo ti sabosi si won, dajudaju Awa yoo wa ibugbe rere fun won. Esan Ojo Ikeyin si tobi julo, ti o ba je pe (awon ti ko se hijrah) mo |
الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ (42) (Awon ni) awon t’o se suuru, won si n gbarale Oluwa won |
وَمَا أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ إِلَّا رِجَالًا نُّوحِي إِلَيْهِمْ ۚ فَاسْأَلُوا أَهْلَ الذِّكْرِ إِن كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ (43) A o ran eni kan ni ise-ojise siwaju re afi awon okunrin ti A n fi imisi ranse si. Nitori naa, e beere lodo awon oniran-anti ti eyin ko ba mo. ki i se awon sufi. Idi ni pe okunfa ayah mejeeji yii ni pe |
بِالْبَيِّنَاتِ وَالزُّبُرِ ۗ وَأَنزَلْنَا إِلَيْكَ الذِّكْرَ لِتُبَيِّنَ لِلنَّاسِ مَا نُزِّلَ إِلَيْهِمْ وَلَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ (44) (A fi) awon eri t’o yanju ati ipin-ipin Tira (ran won nise). Ati pe A so tira Iranti (iyen, al-Ƙur’an) kale fun o nitori ki o le salaye fun awon eniyan ohun ti A sokale fun won ati nitori ki won le ronu jinle |
أَفَأَمِنَ الَّذِينَ مَكَرُوا السَّيِّئَاتِ أَن يَخْسِفَ اللَّهُ بِهِمُ الْأَرْضَ أَوْ يَأْتِيَهُمُ الْعَذَابُ مِنْ حَيْثُ لَا يَشْعُرُونَ (45) Se awon t’o da ete aburu fi okan bale pe Allahu ko le mu ile ri mo won lese ni, tabi pe iya ko le de ba won lati aye ti won ko ti nii fura |
أَوْ يَأْخُذَهُمْ فِي تَقَلُّبِهِمْ فَمَا هُم بِمُعْجِزِينَ (46) Tabi (Allahu) ko le gba won mu lori irinke-rindo won ni? Won ko si nii mori bo |
أَوْ يَأْخُذَهُمْ عَلَىٰ تَخَوُّفٍ فَإِنَّ رَبَّكُمْ لَرَءُوفٌ رَّحِيمٌ (47) Tabi (Allahu) ko le maa gba won mu diedie ni? Nitori naa, dajudaju Oluwa yin ma ni Alaaanu, Onikee |
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَىٰ مَا خَلَقَ اللَّهُ مِن شَيْءٍ يَتَفَيَّأُ ظِلَالُهُ عَنِ الْيَمِينِ وَالشَّمَائِلِ سُجَّدًا لِّلَّهِ وَهُمْ دَاخِرُونَ (48) Ati pe se won ko ri gbogbo nnkan ti Allahu seda re, ti ooji re n pada yo lati otun ati osi ni oluforikanle fun Allahu; ti won si n yepere ara won (fun Un) |
وَلِلَّهِ يَسْجُدُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ مِن دَابَّةٍ وَالْمَلَائِكَةُ وَهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ (49) Allahu si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile ni nnkan abemi ati awon molaika n fori kanle fun. Won ko si segberaga |
يَخَافُونَ رَبَّهُم مِّن فَوْقِهِمْ وَيَفْعَلُونَ مَا يُؤْمَرُونَ ۩ (50) Won n paya Oluwa won t’O n be loke won. Won si n se ohun ti A n pa lase fun won |
۞ وَقَالَ اللَّهُ لَا تَتَّخِذُوا إِلَٰهَيْنِ اثْنَيْنِ ۖ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ فَإِيَّايَ فَارْهَبُونِ (51) Allahu so pe: “E ma se josin fun olohun meji. Oun nikan ni Olohun Okan soso ti ijosin to si. Nitori naa, Emi (nikan) ni ki e beru.” |
وَلَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَهُ الدِّينُ وَاصِبًا ۚ أَفَغَيْرَ اللَّهِ تَتَّقُونَ (52) TiRe si ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. TiRe si ni esin titi laelae Nitori naa, se (nnkan miiran) yato si Allahu ni eyin yoo maa beru ni |
وَمَا بِكُم مِّن نِّعْمَةٍ فَمِنَ اللَّهِ ۖ ثُمَّ إِذَا مَسَّكُمُ الضُّرُّ فَإِلَيْهِ تَجْأَرُونَ (53) Ohunkohun ti e ni ninu idera, lati odo Allahu ni. Leyin naa, ti owo inira ba te yin, Oun ni ki e maa pe (fun idande) |
ثُمَّ إِذَا كَشَفَ الضُّرَّ عَنكُمْ إِذَا فَرِيقٌ مِّنكُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ (54) Leyin naa, nigba ti O ba si mu inira naa kuro fun yin tan, nigba naa ni apa kan ninu yin yo si maa sebo si Oluwa won |
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا ۖ فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ (55) nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won. Nitori naa, e maa gbadun nso. Laipe e maa mo |
وَيَجْعَلُونَ لِمَا لَا يَعْلَمُونَ نَصِيبًا مِّمَّا رَزَقْنَاهُمْ ۗ تَاللَّهِ لَتُسْأَلُنَّ عَمَّا كُنتُمْ تَفْتَرُونَ (56) Won n fi ipin kan ninu ohun ti A pese fun won lele fun ohun ti won ko mo. Mo fi Allahu bura, dajudaju won yoo bi yin leere nipa ohun ti e n da ni adapa iro |
وَيَجْعَلُونَ لِلَّهِ الْبَنَاتِ سُبْحَانَهُ ۙ وَلَهُم مَّا يَشْتَهُونَ (57) Won tun n fi (bibi) awon omobinrin lele fun Allahu - Mimo ni fun Un (ko bimo). – Won si n fi ohun ti won n fe lele fun tiwon |
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِالْأُنثَىٰ ظَلَّ وَجْهُهُ مُسْوَدًّا وَهُوَ كَظِيمٌ (58) Nigba ti won ba fun okan ninu won ni iro idunnu (pe o bi) omobinrin, oju re yoo sokunkun, o si maa kun fun ibanuje |
يَتَوَارَىٰ مِنَ الْقَوْمِ مِن سُوءِ مَا بُشِّرَ بِهِ ۚ أَيُمْسِكُهُ عَلَىٰ هُونٍ أَمْ يَدُسُّهُ فِي التُّرَابِ ۗ أَلَا سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ (59) O si maa fi ara pamo fun awon eniyan nitori iro aburu ti won fun un. Se o maa gba a ni nnkan abuku ni tabi o maa bo o mole laaye? E gbo, ohun ti won n da lejo buru |
لِلَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ مَثَلُ السَّوْءِ ۖ وَلِلَّهِ الْمَثَلُ الْأَعْلَىٰ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (60) Ti awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo ni akawe aburu. Ti Allahu si ni akawe t’o ga julo. Ati pe Oun ni Alagbara, Ologbon |
وَلَوْ يُؤَاخِذُ اللَّهُ النَّاسَ بِظُلْمِهِم مَّا تَرَكَ عَلَيْهَا مِن دَابَّةٍ وَلَٰكِن يُؤَخِّرُهُمْ إِلَىٰ أَجَلٍ مُّسَمًّى ۖ فَإِذَا جَاءَ أَجَلُهُمْ لَا يَسْتَأْخِرُونَ سَاعَةً ۖ وَلَا يَسْتَقْدِمُونَ (61) Ti o ba je pe Allahu n gba awon eniyan mu nitori abosi owo won, iba ti se abemi kan kan ku sori ile. Sugbon O n lo won lara di gbedeke akoko kan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di igba kan, won ko si nii fa a seyin.” |
وَيَجْعَلُونَ لِلَّهِ مَا يَكْرَهُونَ وَتَصِفُ أَلْسِنَتُهُمُ الْكَذِبَ أَنَّ لَهُمُ الْحُسْنَىٰ ۖ لَا جَرَمَ أَنَّ لَهُمُ النَّارَ وَأَنَّهُم مُّفْرَطُونَ (62) Won n fi (omobinrin) nnkan ti won korira lele fun Allahu. Ahon won si n royin iro pe dajudaju rere ni tawon. Ko si tabi-sugbon, dajudaju Ina ni tiwon. Ati pe dajudaju won maa pa won ti sinu re ni |
تَاللَّهِ لَقَدْ أَرْسَلْنَا إِلَىٰ أُمَمٍ مِّن قَبْلِكَ فَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَهُوَ وَلِيُّهُمُ الْيَوْمَ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (63) Mo fi Allahu bura, dajudaju A ti ran awon Ojise nise si awon ijo kan siwaju re. Nigba naa, Esu se ise won ni oso fun won; oun si ni ore won lonii. Iya eleta-elero si wa fun won |
وَمَا أَنزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ إِلَّا لِتُبَيِّنَ لَهُمُ الَّذِي اخْتَلَفُوا فِيهِ ۙ وَهُدًى وَرَحْمَةً لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ (64) A ko so Tira naa kale fun o bi ko se pe ki o le salaye fun won ohun ti won n yapa enu si; o si je imona ati ike fun ijo onigbagbo ododo |
وَاللَّهُ أَنزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ (65) Allahu l’O n so omi kale lati sanmo. O si n fi ji ile leyin ti o ti ku. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo) |
وَإِنَّ لَكُمْ فِي الْأَنْعَامِ لَعِبْرَةً ۖ نُّسْقِيكُم مِّمَّا فِي بُطُونِهِ مِن بَيْنِ فَرْثٍ وَدَمٍ لَّبَنًا خَالِصًا سَائِغًا لِّلشَّارِبِينَ (66) Dajudaju ariwoye wa fun yin lara awon eran-osin, ti A n fun yin mu ninu nnkan t’o wa ninu re, (eyi) ti o n jade wa lati aarin boto inu agbedu ati eje. (O si n di) wara mimo t’o n lo tinrin ni ofun awon t’o n mu un |
وَمِن ثَمَرَاتِ النَّخِيلِ وَالْأَعْنَابِ تَتَّخِذُونَ مِنْهُ سَكَرًا وَرِزْقًا حَسَنًا ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (67) Ati pe lati ara awon eso dabinu ati eso ajara ni e ti n se oti ati ohun amu-soro t’o dara. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye |
وَأَوْحَىٰ رَبُّكَ إِلَى النَّحْلِ أَنِ اتَّخِذِي مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا وَمِنَ الشَّجَرِ وَمِمَّا يَعْرِشُونَ (68) Oluwa re si fi mo kokoro oyin pe: "Mu ile sinu apata, igi ati ohun ti (awon eniyan) mo ga |
ثُمَّ كُلِي مِن كُلِّ الثَّمَرَاتِ فَاسْلُكِي سُبُلَ رَبِّكِ ذُلُلًا ۚ يَخْرُجُ مِن بُطُونِهَا شَرَابٌ مُّخْتَلِفٌ أَلْوَانُهُ فِيهِ شِفَاءٌ لِّلنَّاسِ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (69) Leyin naa, je lara gbogbo eso, ki o si to awon oju ona Oluwa re pelu iteriba." Ohun mimu ti awo re yato sira won yoo maa jade lati inu kokoro oyin. Iwosan ni fun awon eniyan. Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle |
وَاللَّهُ خَلَقَكُمْ ثُمَّ يَتَوَفَّاكُمْ ۚ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰ أَرْذَلِ الْعُمُرِ لِكَيْ لَا يَعْلَمَ بَعْدَ عِلْمٍ شَيْئًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ قَدِيرٌ (70) Allahu l’O seda yin. Leyin naa, O n gba emi yin. O si wa ninu yin eni ti A oo da pada si ogbo kujokujo nitori ki o ma le mo nnkan kan mo leyin ti o ti mo on. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alagbara |
وَاللَّهُ فَضَّلَ بَعْضَكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ فِي الرِّزْقِ ۚ فَمَا الَّذِينَ فُضِّلُوا بِرَادِّي رِزْقِهِمْ عَلَىٰ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُمْ فَهُمْ فِيهِ سَوَاءٌ ۚ أَفَبِنِعْمَةِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ (71) Allahu l’O soore ajulo fun apa kan yin lori apa kan ninu arisiki. Awon ti A fun ni oore ajulo, ki won fun awon eru won ni arisiki won, ki won si jo pin in ni dogbadogba! Nitori naa, se idera Allahu ni won yoo maa tako |
وَاللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا وَجَعَلَ لَكُم مِّنْ أَزْوَاجِكُم بَنِينَ وَحَفَدَةً وَرَزَقَكُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ ۚ أَفَبِالْبَاطِلِ يُؤْمِنُونَ وَبِنِعْمَتِ اللَّهِ هُمْ يَكْفُرُونَ (72) Ati pe Allahu se awon iyawo fun yin lati ara yin. O fun yin ni awon omo ati omoomo lati ara awon iyawo yin. O si pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Se iro (iyen, orisa) ni won yoo gbagbo, won yo si sai gbagbo ninu idera Allahu |
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَمْلِكُ لَهُمْ رِزْقًا مِّنَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ شَيْئًا وَلَا يَسْتَطِيعُونَ (73) Dipo (ki won josin fun) Allahu, won n josin fun ohun ti ko ni ikapa arisiki kan kan fun won ninu sanmo ati ile; won ko si lagbara (lati se nnkan kan) |
فَلَا تَضْرِبُوا لِلَّهِ الْأَمْثَالَ ۚ إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ وَأَنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ (74) Nitori naa, e ma se fi awon akawe naa lele nipa Allahu. Dajudaju Allahu nimo; eyin ko si nimo |
۞ ضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا عَبْدًا مَّمْلُوكًا لَّا يَقْدِرُ عَلَىٰ شَيْءٍ وَمَن رَّزَقْنَاهُ مِنَّا رِزْقًا حَسَنًا فَهُوَ يُنفِقُ مِنْهُ سِرًّا وَجَهْرًا ۖ هَلْ يَسْتَوُونَ ۚ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ (75) Allahu fi akawe kan lele (nipa) eru kan ti o wa labe oga, ti ko si le da nnkan kan se ati eni ti A fun ni arisiki t’o dara lati odo wa, ti o si n na ninu re ni ikoko ati ni gbangba. Se won dogba bi? Gbogbo ope n je ti Allahu. Sugbon opolopo won ni ko mo |
وَضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا رَّجُلَيْنِ أَحَدُهُمَا أَبْكَمُ لَا يَقْدِرُ عَلَىٰ شَيْءٍ وَهُوَ كَلٌّ عَلَىٰ مَوْلَاهُ أَيْنَمَا يُوَجِّههُّ لَا يَأْتِ بِخَيْرٍ ۖ هَلْ يَسْتَوِي هُوَ وَمَن يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ ۙ وَهُوَ عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ (76) Allahu tun fi akawe kan lele (nipa) okunrin meji kan, ti okan ninu won je odi, ti ko le da nnkan kan se, ti o tun je wahala fun oga re (nitori pe) ibikibi ti o ba ran an lo, ko nii mu oore kan bo (fun un lati ibe). Se o dogba pelu eni ti O n pase sise eto, ti o si wa loju ona taara |
وَلِلَّهِ غَيْبُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَمَا أَمْرُ السَّاعَةِ إِلَّا كَلَمْحِ الْبَصَرِ أَوْ هُوَ أَقْرَبُ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (77) Ti Allahu ni ikoko awon sanmo ati ile. Oro Akoko naa ko kuku tayo iseju tabi ki o tun sunmo julo. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
وَاللَّهُ أَخْرَجَكُم مِّن بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ لَا تَعْلَمُونَ شَيْئًا وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۙ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ (78) Allahu l’O mu yin jade lati inu ikun awon iya yin nigba ti eyin ko ti i da nnkan kan mo. O si se igboro, awon iriran ati awon okan fun yin nitori ki e le dupe (fun Un) |
أَلَمْ يَرَوْا إِلَى الطَّيْرِ مُسَخَّرَاتٍ فِي جَوِّ السَّمَاءِ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا اللَّهُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ (79) Se won ko woye si awon eye ti A ro (fun fifo) ninu ofurufu (labe) sanmo? Ko si eni t’o n mu won duro (sinu ofurufu) bi ko se Allahu. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo |
وَاللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّن بُيُوتِكُمْ سَكَنًا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ الْأَنْعَامِ بُيُوتًا تَسْتَخِفُّونَهَا يَوْمَ ظَعْنِكُمْ وَيَوْمَ إِقَامَتِكُمْ ۙ وَمِنْ أَصْوَافِهَا وَأَوْبَارِهَا وَأَشْعَارِهَا أَثَاثًا وَمَتَاعًا إِلَىٰ حِينٍ (80) Allahu se ibusinmi fun yin sinu ile yin. Lati ara awo eran-osin, O tun se awon ile (atibaba) kan t’o fuye fun yin lati gbe rin ni ojo irin-ajo yin ati ni ojo ti e ba wa ninu ilu. Lati ara irun agutan, irun rakunmi ati irun ewure, e tun n ri awon nnkan oso ati nnkan igbadun lo titi fun igba die. aso eyi ti won ba fi irun agutan hun maa n je aso t’o roju julo ni rira. Nitori eyi aso irun agutan je aso awon mekunnu. Awon olowo ki i si fe ra a fun wiwo sorun nitori pe olufokansin eni esa onpero kookan ninu awon aafa onibidiah wonyen ba tun bere si fi oruko ara re pero dipo lilo oruko agbelero ti won dijo se adadaale re. Nigba naa ni aye won ba di ilana / toriko “at-tasowuffu al-kodiriyyah” ti okunrin kan ko ba ti ri ise halal se ni ise oojo o maa di “seeu” |
وَاللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَالًا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ الْجِبَالِ أَكْنَانًا وَجَعَلَ لَكُمْ سَرَابِيلَ تَقِيكُمُ الْحَرَّ وَسَرَابِيلَ تَقِيكُم بَأْسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعْمَتَهُ عَلَيْكُمْ لَعَلَّكُمْ تُسْلِمُونَ (81) Allahu se awon iboji fun yin lati ara nnkan ti O da. O se awon ibugbe fun yin lati ara awon apata. O tun se awon aso fun yin t’o n daabo bo yin lowo ooru ati awon aso t’o n daabo bo yin loju ogun yin. Bayen l’O se n pe idera Re le yin lori nitori ki e le je musulumi |
فَإِن تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا عَلَيْكَ الْبَلَاغُ الْمُبِينُ (82) Nitori naa, ti won ba gbunri, ise-jije ponnbele lojuse tire |
يَعْرِفُونَ نِعْمَتَ اللَّهِ ثُمَّ يُنكِرُونَهَا وَأَكْثَرُهُمُ الْكَافِرُونَ (83) Won mo idera Allahu, leyin naa won n tako o. Opolopo won si ni alaimoore |
وَيَوْمَ نَبْعَثُ مِن كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا ثُمَّ لَا يُؤْذَنُ لِلَّذِينَ كَفَرُوا وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ (84) (Ranti) ojo ti A oo gbe elerii kan dide ninu gbogbo ijo (awon Anabi), leyin naa, A o nii yonda (aroye sise) fun awon t’o sai gbagbo. Won ko si nii fun won ni aye lati pada se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu |
وَإِذَا رَأَى الَّذِينَ ظَلَمُوا الْعَذَابَ فَلَا يُخَفَّفُ عَنْهُمْ وَلَا هُمْ يُنظَرُونَ (85) Nigba ti awon t’o sabosi ba ri Iya, nigba naa, A o nii se iya won ni fifuye, A o si nii fun won ni isinmi (ninu Ina) |
وَإِذَا رَأَى الَّذِينَ أَشْرَكُوا شُرَكَاءَهُمْ قَالُوا رَبَّنَا هَٰؤُلَاءِ شُرَكَاؤُنَا الَّذِينَ كُنَّا نَدْعُو مِن دُونِكَ ۖ فَأَلْقَوْا إِلَيْهِمُ الْقَوْلَ إِنَّكُمْ لَكَاذِبُونَ (86) Nigba ti awon t’o ba Allahu wa akegbe ba ri awon orisa won, won a wi pe: “Oluwa wa, awon wonyi ni awon orisa wa ti a n pe leyin Re.” Nigba naa (awon orisa) yoo ju oro naa pada si won pe: “Dajudaju opuro ma ni eyin.” |
وَأَلْقَوْا إِلَى اللَّهِ يَوْمَئِذٍ السَّلَمَ ۖ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ (87) Won si maa jura won sile fun Allahu ni ojo yen. Ohun ti won n da ni adapa iro yo si di ofo mo won lowo |
الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ زِدْنَاهُمْ عَذَابًا فَوْقَ الْعَذَابِ بِمَا كَانُوا يُفْسِدُونَ (88) Awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, A o se alekun iya lori iya fun won nitori pe won n sebaje |
وَيَوْمَ نَبْعَثُ فِي كُلِّ أُمَّةٍ شَهِيدًا عَلَيْهِم مِّنْ أَنفُسِهِمْ ۖ وَجِئْنَا بِكَ شَهِيدًا عَلَىٰ هَٰؤُلَاءِ ۚ وَنَزَّلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ تِبْيَانًا لِّكُلِّ شَيْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً وَبُشْرَىٰ لِلْمُسْلِمِينَ (89) (Ranti) Ojo ti A oo gbe elerii dide fun ijo kookan laaarin ara won, A si maa mu iwo wa ni elerii fun awon wonyi. A so Tira kale fun o; (o je) alaye fun gbogbo nnkan, imona, ike ati iro idunnu fun awon musulumi |
۞ إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيتَاءِ ذِي الْقُرْبَىٰ وَيَنْهَىٰ عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنكَرِ وَالْبَغْيِ ۚ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ (90) Dajudaju Allahu n pase sise deede, sise rere ati fifun ebi (ni nnkan). O si n ko iwa ibaje, ohun buruku ati rukerudo. O n se waasi fun yin nitori ki e le lo iranti |
وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللَّهِ إِذَا عَاهَدتُّمْ وَلَا تَنقُضُوا الْأَيْمَانَ بَعْدَ تَوْكِيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللَّهَ عَلَيْكُمْ كَفِيلًا ۚ إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ (91) Ki e si mu adehun Allahu se nigba ti e ba se adehun. E ma se tu ibura leyin ifirinle re. E si kuku ti fi Allahu se Elerii lori ara yin. Dajudaju Allahu mo ohun ti e n se nise |
وَلَا تَكُونُوا كَالَّتِي نَقَضَتْ غَزْلَهَا مِن بَعْدِ قُوَّةٍ أَنكَاثًا تَتَّخِذُونَ أَيْمَانَكُمْ دَخَلًا بَيْنَكُمْ أَن تَكُونَ أُمَّةٌ هِيَ أَرْبَىٰ مِنْ أُمَّةٍ ۚ إِنَّمَا يَبْلُوكُمُ اللَّهُ بِهِ ۚ وَلَيُبَيِّنَنَّ لَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ مَا كُنتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ (92) Ki e si ma se da bi (obinrin) eyi ti o tu owu didi re pale leyin ti o ti di i le. Nse ni e n lo ibura yin fun etan laaarin ara yin nitori pe iran kan po ju iran kan lo. Dajudaju Allahu n dan yin wo pelu re ni. Ati pe ni Ojo Ajinde O kuku maa salaye fun yin ohun ti e n yapa enu si |
وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَجَعَلَكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَٰكِن يُضِلُّ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ ۚ وَلَتُسْأَلُنَّ عَمَّا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (93) Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon O n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Dajudaju Won maa bi yin leere nipa ohun ti e n se nise |
وَلَا تَتَّخِذُوا أَيْمَانَكُمْ دَخَلًا بَيْنَكُمْ فَتَزِلَّ قَدَمٌ بَعْدَ ثُبُوتِهَا وَتَذُوقُوا السُّوءَ بِمَا صَدَدتُّمْ عَن سَبِيلِ اللَّهِ ۖ وَلَكُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ (94) E ma se lo ibura yin fun etan laaarin ara yin, nitori ki ese yin ma baa ye gere leyin idurosinsin re, ati nitori ki e ma baa to iya buruku wo nipa bi e se seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu. Iya nla yo si wa fun yin |
وَلَا تَشْتَرُوا بِعَهْدِ اللَّهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۚ إِنَّمَا عِندَ اللَّهِ هُوَ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ (95) E ma se ta adehun Allahu ni owo pooku. Ohun ti n be lodo Allahu, o loore julo fun yin ti e ba mo |
مَا عِندَكُمْ يَنفَدُ ۖ وَمَا عِندَ اللَّهِ بَاقٍ ۗ وَلَنَجْزِيَنَّ الَّذِينَ صَبَرُوا أَجْرَهُم بِأَحْسَنِ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (96) Ohun t’o n be lodo yin maa tan. Ohun t’o n be lodo Allahu si maa wa titi laelae. Dajudaju A si maa fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san awon t’o se suuru lesan won |
مَنْ عَمِلَ صَالِحًا مِّن ذَكَرٍ أَوْ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤْمِنٌ فَلَنُحْيِيَنَّهُ حَيَاةً طَيِّبَةً ۖ وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَجْرَهُم بِأَحْسَنِ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (97) Enikeni ti o ba se ise rere, okunrin ni tabi obinrin, o si je onigbagbo ododo, dajudaju A oo je ki o lo igbesi aye t’o dara. Dajudaju A o si fi eyi t’o dara julo si ohun ti won n se nise san won ni esan won |
فَإِذَا قَرَأْتَ الْقُرْآنَ فَاسْتَعِذْ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ الرَّجِيمِ (98) Nigba ti o ba (fe) ke al-Ƙur’an, sa di Allahu nibi (aburu) Esu, eni eko |
إِنَّهُ لَيْسَ لَهُ سُلْطَانٌ عَلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ (99) Dajudaju ko si agbara kan fun un lori awon t’o gbagbo, ti won si n gbarale Oluwa won |
إِنَّمَا سُلْطَانُهُ عَلَى الَّذِينَ يَتَوَلَّوْنَهُ وَالَّذِينَ هُم بِهِ مُشْرِكُونَ (100) Eni t’o lagbara lori re ni awon t’o n mu un ni ore ati awon t’o so o di akegbe Allahu |
وَإِذَا بَدَّلْنَا آيَةً مَّكَانَ آيَةٍ ۙ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُنَزِّلُ قَالُوا إِنَّمَا أَنتَ مُفْتَرٍ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ (101) Nigba ti A ba paaro ayah kan si aye ayah kan, Allahu l’O si nimo julo nipa ohun t’O n sokale, won a wi pe: “Iwo kan je aladapa iro ni.” Amo opolopo won ni ko nimo |
قُلْ نَزَّلَهُ رُوحُ الْقُدُسِ مِن رَّبِّكَ بِالْحَقِّ لِيُثَبِّتَ الَّذِينَ آمَنُوا وَهُدًى وَبُشْرَىٰ لِلْمُسْلِمِينَ (102) So pe: “Emi mimo (molaika Jibril) l’o so o kale lati odo Oluwa re ni ti ododo nitori ki o le mu ese awon t’o gbagbo lododo rinle. (Ki o si le je) imona ati iro idunnu fun awon musulumi |
وَلَقَدْ نَعْلَمُ أَنَّهُمْ يَقُولُونَ إِنَّمَا يُعَلِّمُهُ بَشَرٌ ۗ لِّسَانُ الَّذِي يُلْحِدُونَ إِلَيْهِ أَعْجَمِيٌّ وَهَٰذَا لِسَانٌ عَرَبِيٌّ مُّبِينٌ (103) A si kuku ti mo pe dajudaju won n wi pe: “Sebi abara kan l’o n ko o (ni al-Ƙur’an).” Ede eni ti won n ye si (ti won n toka si pe o n ko o) ki i se elede Larubawa. Ede Larubawa ponnbele si ni (al-Ƙur’an) yii |
إِنَّ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ لَا يَهْدِيهِمُ اللَّهُ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (104) Dajudaju awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu, Allahu ko nii to won sona. Iya eleta-elero si wa fun won |
إِنَّمَا يَفْتَرِي الْكَذِبَ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْكَاذِبُونَ (105) Awon ti ko gbagbo ninu awon ayah Allahu l’o n da adapa iro (mo Allahu). Awon wonyen si ni opuro |
مَن كَفَرَ بِاللَّهِ مِن بَعْدِ إِيمَانِهِ إِلَّا مَنْ أُكْرِهَ وَقَلْبُهُ مُطْمَئِنٌّ بِالْإِيمَانِ وَلَٰكِن مَّن شَرَحَ بِالْكُفْرِ صَدْرًا فَعَلَيْهِمْ غَضَبٌ مِّنَ اللَّهِ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ (106) Enikeni ti o ba sai gbagbo ninu Allahu leyin igbagbo re, yato si eni ti won je nipa, ti okan re si bale pelu igbagbo ododo, sugbon enikeni ti aigbagbo ba te lorun, ibinu lati odo Allahu n be lori won. Iya nla si wa fun won |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ اسْتَحَبُّوا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا عَلَى الْآخِرَةِ وَأَنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ (107) Iyen nitori pe won feran isemi aye ju orun. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo |
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ طَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَسَمْعِهِمْ وَأَبْصَارِهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ (108) Awon wonyen ni awon ti Allahu ti fi edidi bo okan won, igboro won ati iriran won. Awon wonyen si ni afonufora |
لَا جَرَمَ أَنَّهُمْ فِي الْآخِرَةِ هُمُ الْخَاسِرُونَ (109) Ko si tabi-sugbon, dajudaju awon ni olofo ni orun |
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ هَاجَرُوا مِن بَعْدِ مَا فُتِنُوا ثُمَّ جَاهَدُوا وَصَبَرُوا إِنَّ رَبَّكَ مِن بَعْدِهَا لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ (110) Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o gbe ilu won ju sile leyin ti awon alaigbagbo ti ko ifooro ba won, leyin naa, ti won jagun esin, ti won si se suuru - dajudaju Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun (fun won) leyin (ifooro ti won ri lodo awon alaigbagbo) |
۞ يَوْمَ تَأْتِي كُلُّ نَفْسٍ تُجَادِلُ عَن نَّفْسِهَا وَتُوَفَّىٰ كُلُّ نَفْسٍ مَّا عَمِلَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ (111) (Ranti) Ojo ti emi kookan yoo de lati du ori ara re. A o si san emi kookan ni esan ohun ti o se nise; won ko si nii sabosi si won |
وَضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا قَرْيَةً كَانَتْ آمِنَةً مُّطْمَئِنَّةً يَأْتِيهَا رِزْقُهَا رَغَدًا مِّن كُلِّ مَكَانٍ فَكَفَرَتْ بِأَنْعُمِ اللَّهِ فَأَذَاقَهَا اللَّهُ لِبَاسَ الْجُوعِ وَالْخَوْفِ بِمَا كَانُوا يَصْنَعُونَ (112) Allahu fi akawe lele nipa ilu kan, ti o je (ilu) aabo ati ifayabale, ti arisiki re n te e lowo ni pupo ni gbogbo aye. Amo (won) se aimoore si awon idera Allahu. Nitori naa, Allahu fun won ni iya ebi ati ipaya to wo nitori ohun ti won n se nise |
وَلَقَدْ جَاءَهُمْ رَسُولٌ مِّنْهُمْ فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ وَهُمْ ظَالِمُونَ (113) Ojise kuku ti de ba won laaarin ara won. Won si pe e ni opuro. Nitori naa, owo iya ba won. Alabosi si ni won |
فَكُلُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ حَلَالًا طَيِّبًا وَاشْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ إِن كُنتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ (114) E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin ni nnkan eto, t’o dara. Ki e si dupe oore Allahu ti o ba je pe Oun nikan soso ni e n josin fun |
إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيْكُمُ الْمَيْتَةَ وَالدَّمَ وَلَحْمَ الْخِنزِيرِ وَمَا أُهِلَّ لِغَيْرِ اللَّهِ بِهِ ۖ فَمَنِ اضْطُرَّ غَيْرَ بَاغٍ وَلَا عَادٍ فَإِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (115) Ohun ti (Allahu) se ni eewo fun yin ni eran okunbete, eje, eran elede ati eyi ti won pa pelu oruko t’o yato si “Allahu”. Nitori naa, enikeni ti won ba fi inira ebi kan, yato si eni t’o n wa eewo kiri ati olutayo-enu-ala, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
وَلَا تَقُولُوا لِمَا تَصِفُ أَلْسِنَتُكُمُ الْكَذِبَ هَٰذَا حَلَالٌ وَهَٰذَا حَرَامٌ لِّتَفْتَرُوا عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ ۚ إِنَّ الَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ لَا يُفْلِحُونَ (116) E ma se so nipa ohun ti ahon yin royin ni iro pe: “Eyi ni eto, eyi si ni eewo” nitori ki e le da adapa iro mo Allahu. Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere |
مَتَاعٌ قَلِيلٌ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (117) Igbadun aye bin-intin (le wa fun won, amo) iya eleta-elero wa fun won (ni orun) |
وَعَلَى الَّذِينَ هَادُوا حَرَّمْنَا مَا قَصَصْنَا عَلَيْكَ مِن قَبْلُ ۖ وَمَا ظَلَمْنَاهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ (118) Ati pe A se ohun ti A so fun o siwaju ni eewo fun awon t’o di yehudi. A o si sabosi si won, sugbon awon ni won n sabosi si emi ara won |
ثُمَّ إِنَّ رَبَّكَ لِلَّذِينَ عَمِلُوا السُّوءَ بِجَهَالَةٍ ثُمَّ تَابُوا مِن بَعْدِ ذَٰلِكَ وَأَصْلَحُوا إِنَّ رَبَّكَ مِن بَعْدِهَا لَغَفُورٌ رَّحِيمٌ (119) Leyin naa, dajudaju Oluwa re - nipa awon t’o se aburu pelu aimokan, leyin naa, ti won ronu piwada leyin iyen, ti won si se atunse leyin re dajudaju Oluwa re ma ni Alaforijin, Asake-orun |
إِنَّ إِبْرَاهِيمَ كَانَ أُمَّةً قَانِتًا لِّلَّهِ حَنِيفًا وَلَمْ يَكُ مِنَ الْمُشْرِكِينَ (120) Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim je asiwaju-awokose-rere, olutele-ase Allahu, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si je ara awon osebo |
شَاكِرًا لِّأَنْعُمِهِ ۚ اجْتَبَاهُ وَهَدَاهُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ (121) O maa n dupe awon idera Allahu. Allahu sa a lesa. O si to o si ona taara (’Islam) |
وَآتَيْنَاهُ فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ (122) A se ohun rere fun un nile aye. Ati pe ni orun dajudaju o maa wa ninu awon eni rere |
ثُمَّ أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ أَنِ اتَّبِعْ مِلَّةَ إِبْرَاهِيمَ حَنِيفًا ۖ وَمَا كَانَ مِنَ الْمُشْرِكِينَ (123) Leyin naa, A fi imisi ranse si o pe ki o tele esin (Anabi) ’Ibrohim, oluduro-deede-ninu-esin. Ko si wa lara awon osebo |
إِنَّمَا جُعِلَ السَّبْتُ عَلَى الَّذِينَ اخْتَلَفُوا فِيهِ ۚ وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَحْكُمُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ (124) Awon ti won se (agbega) ojo Sabt fun ni awon t’o yapa enu nipa re. Dajudaju Oluwa re yoo kuku se idajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si |
ادْعُ إِلَىٰ سَبِيلِ رَبِّكَ بِالْحِكْمَةِ وَالْمَوْعِظَةِ الْحَسَنَةِ ۖ وَجَادِلْهُم بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ ۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِ ۖ وَهُوَ أَعْلَمُ بِالْمُهْتَدِينَ (125) Pepe si oju ona Oluwa re pelu ogbon ijinle (iyen, al-Ƙur’an ati sunnah Anabi s.a.w.) ati waasi rere. Ki o si ja won niyan pelu eyi t’o dara julo. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni ti o sina kuro loju ona Re (’Islam). O si nimo julo nipa awon olumona (awon musulumi) |
وَإِنْ عَاقَبْتُمْ فَعَاقِبُوا بِمِثْلِ مَا عُوقِبْتُم بِهِ ۖ وَلَئِن صَبَرْتُمْ لَهُوَ خَيْرٌ لِّلصَّابِرِينَ (126) Ti e (ba fe) gbesan (iya), e gbesan iru iya ti won fi je yin. Dajudaju ti e ba si se suuru, o ma si loore julo fun awon onisuuru |
وَاصْبِرْ وَمَا صَبْرُكَ إِلَّا بِاللَّهِ ۚ وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَلَا تَكُ فِي ضَيْقٍ مِّمَّا يَمْكُرُونَ (127) Se suuru. Iwo ko si le ri suuru se afi pelu (iranlowo) Allahu. Ma se banuje nitori won. Ma si se wa ninu ibanuje nitori ohun ti won n da ni ete |
إِنَّ اللَّهَ مَعَ الَّذِينَ اتَّقَوا وَّالَّذِينَ هُم مُّحْسِنُونَ (128) Dajudaju Allahu wa pelu awon t’o beru (Re) ati awon t’o n se rere |