Quran with Yoruba translation - Surah Al-Isra’ ayat 97 - الإسرَاء - Page - Juz 15
﴿وَمَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَلَن تَجِدَ لَهُمۡ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِهِۦۖ وَنَحۡشُرُهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمۡ عُمۡيٗا وَبُكۡمٗا وَصُمّٗاۖ مَّأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ كُلَّمَا خَبَتۡ زِدۡنَٰهُمۡ سَعِيرٗا ﴾
[الإسرَاء: 97]
﴿ومن يهد الله فهو المهتد ومن يضلل فلن تجد لهم أولياء من﴾ [الإسرَاء: 97]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Àti pé A máa kó wọn jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìdojúbolẹ̀. (Wọn yóò di) afọ́jú, ayaya àti odi. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Nígbàkígbà tí Iná bá jó lọọlẹ̀, A máa ṣàlékún jíjò (rẹ̀) fún wọn |