Quran with Yoruba translation - Surah Al-Kahf ayat 22 - الكَهف - Page - Juz 15
﴿سَيَقُولُونَ ثَلَٰثَةٞ رَّابِعُهُمۡ كَلۡبُهُمۡ وَيَقُولُونَ خَمۡسَةٞ سَادِسُهُمۡ كَلۡبُهُمۡ رَجۡمَۢا بِٱلۡغَيۡبِۖ وَيَقُولُونَ سَبۡعَةٞ وَثَامِنُهُمۡ كَلۡبُهُمۡۚ قُل رَّبِّيٓ أَعۡلَمُ بِعِدَّتِهِم مَّا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا قَلِيلٞۗ فَلَا تُمَارِ فِيهِمۡ إِلَّا مِرَآءٗ ظَٰهِرٗا وَلَا تَسۡتَفۡتِ فِيهِم مِّنۡهُمۡ أَحَدٗا ﴾
[الكَهف: 22]
﴿سيقولون ثلاثة رابعهم كلبهم ويقولون خمسة سادسهم كلبهم رجما بالغيب ويقولون سبعة﴾ [الكَهف: 22]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n ń wí pé: “Mẹ́ta ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹrin wọn.” Wọ́n tún ń wí pé: "Márùn-ún ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹfà wọn." Ọ̀rọ̀ t’ó pamọ́ fún wọn (ni wọ́n ń sọ). Wọ́n tún ń wí pé: “Méje ni wọ́n. Ajá wọn ṣìkẹjọ wọn.” Sọ pé: "Olúwa mi nímọ̀ jùlọ nípa òǹkà wọn. Kò sí (ẹni tí) ó mọ (òǹkà) wọn àfi àwọn díẹ̀. Nítorí náà, má ṣe bá wọn ṣe àríyànjiyàn nípa (òǹkà) wọn àfi (kí o fi) àríyànjiyàn (náà tì síbi ẹ̀rí) t’ó yanjú (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ yìí). Má sì ṣe bi ẹnì kan nínú wọn léèrè nípa (òǹkà) wọn |