Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 114 - البَقَرَة - Page - Juz 1
﴿وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن مَّنَعَ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ أَن يُذۡكَرَ فِيهَا ٱسۡمُهُۥ وَسَعَىٰ فِي خَرَابِهَآۚ أُوْلَٰٓئِكَ مَا كَانَ لَهُمۡ أَن يَدۡخُلُوهَآ إِلَّا خَآئِفِينَۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ ﴾
[البَقَرَة: 114]
﴿ومن أظلم ممن منع مساجد الله أن يذكر فيها اسمه وسعى في﴾ [البَقَرَة: 114]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àti pé ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí ó ṣe àwọn mọ́sálásí Allāhu ní èèwọ̀ láti ṣèrántí orúkọ Allāhu nínú rẹ̀, tí ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìparun àwọn mọ́sálásí náà? Àwọn wọ̀nyẹn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti wọ inú rẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Àbùkù ń bẹ fún wọn n’ílé ayé. Ní ọ̀run, ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn |