Quran with Yoruba translation - Surah Al-hajj ayat 36 - الحج - Page - Juz 17
﴿وَٱلۡبُدۡنَ جَعَلۡنَٰهَا لَكُم مِّن شَعَٰٓئِرِ ٱللَّهِ لَكُمۡ فِيهَا خَيۡرٞۖ فَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا صَوَآفَّۖ فَإِذَا وَجَبَتۡ جُنُوبُهَا فَكُلُواْ مِنۡهَا وَأَطۡعِمُواْ ٱلۡقَانِعَ وَٱلۡمُعۡتَرَّۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرۡنَٰهَا لَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴾
[الحج: 36]
﴿والبدن جعلناها لكم من شعائر الله لكم فيها خير فاذكروا اسم الله﴾ [الحج: 36]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fun yín. Oore wà lára wọn fun yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ onítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fun yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un) |