Quran with Yoruba translation - Surah Al-hajj ayat 47 - الحج - Page - Juz 17
﴿وَيَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥۚ وَإِنَّ يَوۡمًا عِندَ رَبِّكَ كَأَلۡفِ سَنَةٖ مِّمَّا تَعُدُّونَ ﴾
[الحج: 47]
﴿ويستعجلونك بالعذاب ولن يخلف الله وعده وإن يوما عند ربك كألف سنة﴾ [الحج: 47]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà). Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ń sọ nípa ìdí tí ìyà kò fi tètè sọ̀kalẹ̀ lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí pé tí Òun bá sọ fún wọn pé àárọ̀ ọ̀la ni ọjọ́ ìyà wọn (bí àpẹẹrẹ) dípò ẹgbẹ̀rún ọdún. Kíyè sí i nínú āyah ọjọ́ kan ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún ó tún lè jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún yálà nílé yìí tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde |