Quran with Yoruba translation - Surah Al-hajj ayat 78 - الحج - Page - Juz 17
﴿وَجَٰهِدُواْ فِي ٱللَّهِ حَقَّ جِهَادِهِۦۚ هُوَ ٱجۡتَبَىٰكُمۡ وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمۡ إِبۡرَٰهِيمَۚ هُوَ سَمَّىٰكُمُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ مِن قَبۡلُ وَفِي هَٰذَا لِيَكُونَ ٱلرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيۡكُمۡ وَتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِۚ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱعۡتَصِمُواْ بِٱللَّهِ هُوَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ فَنِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ ﴾
[الحج: 78]
﴿وجاهدوا في الله حق جهاده هو اجتباكم وما جعل عليكم في الدين﴾ [الحج: 78]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe |