Quran with Yoruba translation - Surah Al-Qasas ayat 46 - القَصَص - Page - Juz 20
﴿وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ ٱلطُّورِ إِذۡ نَادَيۡنَا وَلَٰكِن رَّحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٖ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ ﴾
[القَصَص: 46]
﴿وما كنت بجانب الطور إذ نادينا ولكن رحمة من ربك لتنذر قوما﴾ [القَصَص: 46]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí. 16:36 àti sūrah Fātir 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn t’ó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀ Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan t’ó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) fi gbé Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé |