Quran with Yoruba translation - Surah Al-‘Ankabut ayat 21 - العَنكبُوت - Page - Juz 20
﴿يُعَذِّبُ مَن يَشَآءُ وَيَرۡحَمُ مَن يَشَآءُۖ وَإِلَيۡهِ تُقۡلَبُونَ ﴾
[العَنكبُوت: 21]
﴿يعذب من يشاء ويرحم من يشاء وإليه تقلبون﴾ [العَنكبُوت: 21]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ó ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì ń kẹ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí. ó jẹ́ ohun tí Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀dá náà nínú kádàrá rẹ̀ nítorí pé tibi-tire ni kádàrá ẹ̀dá. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ yìí ni à ń pè ní ""mọṣī’atu-llāhi al-kaoniyyah"" “fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu tayé”. Bí àpẹẹrẹ lágbájá fẹ́ di olówó lọ́nà ẹ̀tọ́ ó jẹ́ ohun tí Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹ̀dá nínú òfin àti ìlànà Rẹ̀. Allāhu kò sì níí fẹ́ òfin àti ìlànà kan bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Rẹ̀ t’ó sọ̀kalẹ̀ fún wa àfi kí ó jẹ́ rere pọ́nńbélé tàbí kí rere rẹ̀ tẹ̀wọ̀n ju aburú rẹ̀ lọ. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ yìí ni à ń pè ní ""mọṣī’atu-llāhi aṣ-ṣẹr‘iyyah"" “fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu tòfin”. Bí àpẹẹrẹ lágbájá fẹ́ di mùsùlùmí méjèèjì l’ó dúró sórí “ ‘adl” àti “ fọdl” – déédé àti ọlá. Àlàyé èyí ni pé tí ìyà bá jẹ́ lágbájá nílé ayé tàbí ní ọ̀run láì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo ẹnu ẹni kẹ́ni kò gbà á láti fi ẹ̀sùn kan Allāhu lórí fífẹ́bẹ́ẹ̀ Rẹ̀ lórí ẹ̀dá rẹ̀. Ṣebí nílé ayé yìí gan-an |