الم (1) ’Alif lam mim |
أَحَسِبَ النَّاسُ أَن يُتْرَكُوا أَن يَقُولُوا آمَنَّا وَهُمْ لَا يُفْتَنُونَ (2) Nje awon eniyan lero pe A oo fi won sile ki won maa so pe: “A gbagbo”, ti A o si nii dan won wo |
وَلَقَدْ فَتَنَّا الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۖ فَلَيَعْلَمَنَّ اللَّهُ الَّذِينَ صَدَقُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْكَاذِبِينَ (3) A kuku ti dan awon t’o siwaju won wo. Nitori naa, dajudaju Allahu maa safi han awon t’o so ododo. Dajudaju O si maa safi han awon opuro |
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ أَن يَسْبِقُونَا ۚ سَاءَ مَا يَحْكُمُونَ (4) Abi awon t’o n se ise aburu lero pe awon maa mori bo mo Wa lowo ni? Ohun ti won n da lejo buru |
مَن كَانَ يَرْجُو لِقَاءَ اللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ اللَّهِ لَآتٍ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (5) Enikeni ti o ba n reti ipade Allahu, dajudaju akoko Allahu kuku n bo. Oun si ni Olugbo, Onimo |
وَمَن جَاهَدَ فَإِنَّمَا يُجَاهِدُ لِنَفْسِهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَغَنِيٌّ عَنِ الْعَالَمِينَ (6) Enikeni ti o ba gbiyanju, o n gbiyanju fun emi ara re ni. Dajudaju Allahu ni Oloro ti ko bukata si gbogbo eda |
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُكَفِّرَنَّ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَلَنَجْزِيَنَّهُمْ أَحْسَنَ الَّذِي كَانُوا يَعْمَلُونَ (7) Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa ha awon ise aburu won danu fun won. Dajudaju A o si san won lesan pelu eyi t’o dara ju ohun ti won n se |
وَوَصَّيْنَا الْإِنسَانَ بِوَالِدَيْهِ حُسْنًا ۖ وَإِن جَاهَدَاكَ لِتُشْرِكَ بِي مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ فَلَا تُطِعْهُمَا ۚ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (8) A pa a ni ase fun eniyan lati se daadaa si awon obi re mejeeji. Ti awon mejeeji ba si ja o logun pe ki o fi ohun ti iwo ko ni imo nipa re sebo si Mi, ma se tele awon mejeeji. Odo Mi ni ibupadasi yin. Nitori naa, Mo maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُدْخِلَنَّهُمْ فِي الصَّالِحِينَ (9) Awon t’o ba gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon eni rere |
وَمِنَ النَّاسِ مَن يَقُولُ آمَنَّا بِاللَّهِ فَإِذَا أُوذِيَ فِي اللَّهِ جَعَلَ فِتْنَةَ النَّاسِ كَعَذَابِ اللَّهِ وَلَئِن جَاءَ نَصْرٌ مِّن رَّبِّكَ لَيَقُولُنَّ إِنَّا كُنَّا مَعَكُمْ ۚ أَوَلَيْسَ اللَّهُ بِأَعْلَمَ بِمَا فِي صُدُورِ الْعَالَمِينَ (10) O n be ninu awon eniyan, eni t’o n wi pe: “A gba Allahu gbo.” Nigba ti won ba si fi inira kan won ninu esin Allahu, o maa so inira eniyan da bi iya ti Allahu. Ti aranse kan lati odo Oluwa re ba si de, dajudaju won yoo wi pe: “Dajudaju awa wa pelu yin.” Se Allahu ko l’O nimo julo nipa ohun ti n be ninu igba-aya gbogbo eda ni |
وَلَيَعْلَمَنَّ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَلَيَعْلَمَنَّ الْمُنَافِقِينَ (11) Dajudaju Allahu maa safi han awon t’o gbagbo ni ododo. O si maa safi han awon sobe-selu musulumi |
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا اتَّبِعُوا سَبِيلَنَا وَلْنَحْمِلْ خَطَايَاكُمْ وَمَا هُم بِحَامِلِينَ مِنْ خَطَايَاهُم مِّن شَيْءٍ ۖ إِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ (12) Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo ni ododo pe: “E tele oju ona tiwa nitori ki a le ru awon ese yin.” Won ko si le ru kini kan ninu ese won. Dajudaju opuro ma ni won |
وَلَيَحْمِلُنَّ أَثْقَالَهُمْ وَأَثْقَالًا مَّعَ أَثْقَالِهِمْ ۖ وَلَيُسْأَلُنَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَمَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ (13) Dajudaju won yoo ru eru ese tiwon ati awon eru ese kan mo eru ese tiwon. Ati pe dajudaju A oo bi won leere ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n da ni adapa iro |
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوْمِهِ فَلَبِثَ فِيهِمْ أَلْفَ سَنَةٍ إِلَّا خَمْسِينَ عَامًا فَأَخَذَهُمُ الطُّوفَانُ وَهُمْ ظَالِمُونَ (14) Dajudaju A ran (Anabi) Nuh nise si ijo re. O gbe laaarin won fun egberun odun afi aadota odun. Ekun-omi si gba won mu nigba ti won je alabosi |
فَأَنجَيْنَاهُ وَأَصْحَابَ السَّفِينَةِ وَجَعَلْنَاهَا آيَةً لِّلْعَالَمِينَ (15) A si la oun ati awon ero inu oko oju-omi. A si se won ni ami fun gbogbo eda |
وَإِبْرَاهِيمَ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَاتَّقُوهُ ۖ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ (16) (Ranti Anabi) ’Ibrohim. Nigba ti o so fun ijo re pe: “E josin fun Allahu. Ki e si paya Re. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo.” |
إِنَّمَا تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ أَوْثَانًا وَتَخْلُقُونَ إِفْكًا ۚ إِنَّ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ لَا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقًا فَابْتَغُوا عِندَ اللَّهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ وَاشْكُرُوا لَهُ ۖ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (17) E kan n josin fun awon orisa leyin Allahu. E si n da adapa iro. Dajudaju awon ti e n josin fun leyin Allahu, won ko ni ikapa arisiki kan fun yin. E wa arisiki si odo Allahu. Ki e josin fun Un. Ki e si dupe fun Un. Odo Re ni won yoo da yin pada si |
وَإِن تُكَذِّبُوا فَقَدْ كَذَّبَ أُمَمٌ مِّن قَبْلِكُمْ ۖ وَمَا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ (18) Ti e ba si pe (ododo) niro, awon ijo kan t’o siwaju yin kuku ti pe (ododo) niro. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele |
أَوَلَمْ يَرَوْا كَيْفَ يُبْدِئُ اللَّهُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى اللَّهِ يَسِيرٌ (19) Tabi won ko ri bi Allahu ti se bere eda ni? Leyin naa, O maa da a pada (si odo Re). Dajudaju iyen rorun fun Allahu |
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ بَدَأَ الْخَلْقَ ۚ ثُمَّ اللَّهُ يُنشِئُ النَّشْأَةَ الْآخِرَةَ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (20) So pe: “E rin kiri lori ile, ki e wo bi O se bere eda (ni ipile). Leyin naa, Allahu l’O maa mu iseda ikeyin wa (fun ajinde). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan.” |
يُعَذِّبُ مَن يَشَاءُ وَيَرْحَمُ مَن يَشَاءُ ۖ وَإِلَيْهِ تُقْلَبُونَ (21) O n je eni ti O ba fe niya. O si n ke eni ti O ba fe. Odo Re si ni won yoo da yin pada si. o je ohun ti Allahu fe bee fun eda naa ninu kadara re nitori pe tibi-tire ni kadara eda. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi al-kaoniyyah"" “fifebee Allahu taye”. Bi apeere lagbaja fe di olowo lona eto o je ohun ti Allahu fe bee fun eda ninu ofin ati ilana Re. Allahu ko si nii fe ofin ati ilana kan bee ninu Tira Re t’o sokale fun wa afi ki o je rere ponnbele tabi ki rere re tewon ju aburu re lo. Fifebee yii ni a n pe ni ""mosi’atu-llahi as-ser‘iyyah"" “fifebee Allahu tofin”. Bi apeere lagbaja fe di musulumi mejeeji l’o duro sori “ ‘adl” ati “ fodl” – deede ati ola. Alaye eyi ni pe ti iya ba je lagbaja nile aye tabi ni orun lai je onigbagbo ododo enu eni keni ko gba a lati fi esun kan Allahu lori fifebee Re lori eda re. Sebi nile aye yii gan-an |
وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ ۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ اللَّهِ مِن وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ (22) Ati pe eyin ko nii mori bo mo Allahu lowo lori ile ati ninu sanmo. Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu |
وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ وَلِقَائِهِ أُولَٰئِكَ يَئِسُوا مِن رَّحْمَتِي وَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ (23) Awon t’o sai gbagbo ninu awon ayah Allahu ati ipade Re (lorun), awon wonyen ti soreti nu ninu ike Mi. Awon wonyen ni iya eleta-elero n be fun |
فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا اقْتُلُوهُ أَوْ حَرِّقُوهُ فَأَنجَاهُ اللَّهُ مِنَ النَّارِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ (24) Esi ijo re ko je kini kan tayo pe won wi pe: “E pa a tabi ki e sun un nina.” Allahu si la a ninu ina. Dajudaju awon ami kuku wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo lododo |
وَقَالَ إِنَّمَا اتَّخَذْتُم مِّن دُونِ اللَّهِ أَوْثَانًا مَّوَدَّةَ بَيْنِكُمْ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ ثُمَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ يَكْفُرُ بَعْضُكُم بِبَعْضٍ وَيَلْعَنُ بَعْضُكُم بَعْضًا وَمَأْوَاكُمُ النَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّاصِرِينَ (25) O si so pe: “E kan mu awon orisa leyin Allahu, ni ohun ti e nifee si (lati josin fun) laaarin ara yin ninu isemi aye (yii). Leyin naa, ni Ojo Ajinde apa kan yin yoo tako apa kan. Apa kan yin yo si sebi le apa kan. Ina si ni ibugbe yin. Ko si nii si awon alaranse kan fun yin.” |
۞ فَآمَنَ لَهُ لُوطٌ ۘ وَقَالَ إِنِّي مُهَاجِرٌ إِلَىٰ رَبِّي ۖ إِنَّهُ هُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (26) (Anabi) Lut si gba a gbo. (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Dajudaju emi yoo fi ilu yii sile nitori ti Oluwa mi. Dajudaju Oun ni Alagbara, Ologbon |
وَوَهَبْنَا لَهُ إِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَجَعَلْنَا فِي ذُرِّيَّتِهِ النُّبُوَّةَ وَالْكِتَابَ وَآتَيْنَاهُ أَجْرَهُ فِي الدُّنْيَا ۖ وَإِنَّهُ فِي الْآخِرَةِ لَمِنَ الصَّالِحِينَ (27) A fi ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub (omoomo re) ta a lore. A si se jije Anabi ati fifunni ni tira sinu aromodomo re. A fun un ni esan re ni aye yii. Dajudaju ni orun, o tun wa ninu awon eni rere |
وَلُوطًا إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ إِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الْفَاحِشَةَ مَا سَبَقَكُم بِهَا مِنْ أَحَدٍ مِّنَ الْعَالَمِينَ (28) (Ranti Anabi) Lut. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Dajudaju eyin n se ibaje ti ko si eni kan ninu eda ti o se e ri siwaju yin |
أَئِنَّكُمْ لَتَأْتُونَ الرِّجَالَ وَتَقْطَعُونَ السَّبِيلَ وَتَأْتُونَ فِي نَادِيكُمُ الْمُنكَرَ ۖ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوْمِهِ إِلَّا أَن قَالُوا ائْتِنَا بِعَذَابِ اللَّهِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ (29) Se dajudaju eyin (okunrin) yoo maa to awon okunrin (egbe yin) lo (fun adun ibalopo), e tun n dana, e tun n se ohun buruku ninu akojo yin? Esi ijo re ko je kini kan afi ki won wi pe : “Mu iya Allahu wa fun wa ti o ba wa ninu awon olododo.” |
قَالَ رَبِّ انصُرْنِي عَلَى الْقَوْمِ الْمُفْسِدِينَ (30) O so pe: “Oluwa mi, saranse fun mi lori ijo obileje.” |
وَلَمَّا جَاءَتْ رُسُلُنَا إِبْرَاهِيمَ بِالْبُشْرَىٰ قَالُوا إِنَّا مُهْلِكُو أَهْلِ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ ۖ إِنَّ أَهْلَهَا كَانُوا ظَالِمِينَ (31) Nigba ti awon Ojise Wa si mu iro idunnu de ba (Anabi) ’Ibrohim, won so pe: “Dajudaju awa maa pa awon ara ilu yii run. Dajudaju awon ara ilu naa je alabosi.” |
قَالَ إِنَّ فِيهَا لُوطًا ۚ قَالُوا نَحْنُ أَعْلَمُ بِمَن فِيهَا ۖ لَنُنَجِّيَنَّهُ وَأَهْلَهُ إِلَّا امْرَأَتَهُ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ (32) O so pe: “Dajudaju (Anabi) Lut wa nibe! Won so pe: “Awa nimo julo nipa awon t’o wa nibe. Dajudaju awa yoo la oun ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun.” |
وَلَمَّا أَن جَاءَتْ رُسُلُنَا لُوطًا سِيءَ بِهِمْ وَضَاقَ بِهِمْ ذَرْعًا وَقَالُوا لَا تَخَفْ وَلَا تَحْزَنْ ۖ إِنَّا مُنَجُّوكَ وَأَهْلَكَ إِلَّا امْرَأَتَكَ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ (33) Nigba ti awon Ojise Wa de odo (Anabi) Lut, o banuje nitori won. Agbara re ko si ka oro won mo. Won si so fun un pe: “Ma beru, ma si se banuje. Dajudaju a maa la iwo ati awon ara ile re afi iyawo re ti o maa wa ninu awon oluseku-leyin sinu iparun.” |
إِنَّا مُنزِلُونَ عَلَىٰ أَهْلِ هَٰذِهِ الْقَرْيَةِ رِجْزًا مِّنَ السَّمَاءِ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ (34) Dajudaju a maa so iya kan kale le awon ara ilu yii lori lati inu sanmo nitori pe won je obileje |
وَلَقَد تَّرَكْنَا مِنْهَا آيَةً بَيِّنَةً لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (35) Dajudaju A ti fi ami kan t’o foju han lele ninu re fun ijo t’o ni laakaye |
وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا فَقَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ وَارْجُوا الْيَوْمَ الْآخِرَ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ (36) A tun ranse si ara ilu Modyan. (A ran) arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb (nise si won). O si so pe: “Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E reti Ojo Ikeyin, ki e si ma sebaje lori ile ni ti obileje.” |
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتْهُمُ الرَّجْفَةُ فَأَصْبَحُوا فِي دَارِهِمْ جَاثِمِينَ (37) Won pe e ni opuro. Nitori naa, ohun igbe lile t’o mi ile titi gba won mu. Won si di eni t’o da lule, ti won ti doku sinu ilu won |
وَعَادًا وَثَمُودَ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَاكِنِهِمْ ۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ الشَّيْطَانُ أَعْمَالَهُمْ فَصَدَّهُمْ عَنِ السَّبِيلِ وَكَانُوا مُسْتَبْصِرِينَ (38) (A tun ranse si awon) ara ‘Ad ati ara Thamud. (Iparun won) si kuku ti foju han kedere si yin ninu awon ibugbe won. Esu se awon ise won ni oso fun won. O si seri won kuro ninu esin (Allahu). Won si je oluriran (nipa oro aye) |
وَقَارُونَ وَفِرْعَوْنَ وَهَامَانَ ۖ وَلَقَدْ جَاءَهُم مُّوسَىٰ بِالْبَيِّنَاتِ فَاسْتَكْبَرُوا فِي الْأَرْضِ وَمَا كَانُوا سَابِقِينَ (39) (A tun ranse si awon) Ƙorun, Fir‘aon ati Hamon. Dajudaju (Anabi) Musa mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won si segberaga lori ile. Won ko si le mori bo ninu iya |
فَكُلًّا أَخَذْنَا بِذَنبِهِ ۖ فَمِنْهُم مَّنْ أَرْسَلْنَا عَلَيْهِ حَاصِبًا وَمِنْهُم مَّنْ أَخَذَتْهُ الصَّيْحَةُ وَمِنْهُم مَّنْ خَسَفْنَا بِهِ الْأَرْضَ وَمِنْهُم مَّنْ أَغْرَقْنَا ۚ وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ (40) A si mu ikookan won nipa ese re. O wa ninu won, eni ti A fi okuta ina ranse si. O wa ninu won eni ti igbe lile gba mu. O wa ninu won eni ti A je ki ile gbemi. O si wa ninu won eni ti A teri sinu omi. Allahu ko si nii sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si |
مَثَلُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ أَوْلِيَاءَ كَمَثَلِ الْعَنكَبُوتِ اتَّخَذَتْ بَيْتًا ۖ وَإِنَّ أَوْهَنَ الْبُيُوتِ لَبَيْتُ الْعَنكَبُوتِ ۖ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ (41) Apejuwe awon t’o mu awon (orisa) ni alatileyin leyin Allahu, o da bi apejuwe alantaakun ti o ko ile kan. Dajudaju ile ti o yepere julo ni ile alantaakun, ti won ba mo |
إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا يَدْعُونَ مِن دُونِهِ مِن شَيْءٍ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (42) Dajudaju Allahu mo ohunkohun ti won n pe leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
وَتِلْكَ الْأَمْثَالُ نَضْرِبُهَا لِلنَّاسِ ۖ وَمَا يَعْقِلُهَا إِلَّا الْعَالِمُونَ (43) Awon akawe wonyi, ti A n fun awon eniyan, ko si si eni ti o maa se laakaye nipa re afi awon onimo |
خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ (44) Allahu seda awon sanmo ati ile pelu ododo. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo |
اتْلُ مَا أُوحِيَ إِلَيْكَ مِنَ الْكِتَابِ وَأَقِمِ الصَّلَاةَ ۖ إِنَّ الصَّلَاةَ تَنْهَىٰ عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنكَرِ ۗ وَلَذِكْرُ اللَّهِ أَكْبَرُ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَصْنَعُونَ (45) Ke ohun ti A fi ranse si o ninu Tira. Ki o si kirun. Dajudaju irun kiki n ko iwa ibaje ati aburu. Ati pe iranti Allahu tobi julo. Allahu si mo ohun ti e n se. bi irun kiki se ni esan bee naa lo tun je ohun t’o n mu olukirun jinna si iwa aburu aawe gbigba ati bee bee lo. Enikeni ti o ba pa irun kiki ati aawe gbigba ti nipase fifun gbolohun yii ni itumo odi o ti ko iparun ba emi ara re ni ibamu si surah al-Muddaththir; 74: 42-43. Ki Allahu (subhanahu wa ta'ala) la wa ninu eyi |
۞ وَلَا تُجَادِلُوا أَهْلَ الْكِتَابِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ إِلَّا الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ ۖ وَقُولُوا آمَنَّا بِالَّذِي أُنزِلَ إِلَيْنَا وَأُنزِلَ إِلَيْكُمْ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمْ وَاحِدٌ وَنَحْنُ لَهُ مُسْلِمُونَ (46) E ma se ba ahlul-kitab sariyan jiyan afi ni ona t’o dara julo (eyi ni lilo al-Ƙur’an ati hadith. E ma si se ja won logun) afi awon t’o ba sabosi ninu won. Ki e si so pe: “A gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun awa ati ohun ti Won sokale fun eyin. Olohun wa ati Olohun yin, (Allahu) Okan soso ni. Awa si ni musulumi (olujuwo-juse-sile) fun Un.” |
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ ۚ فَالَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَمِنْ هَٰؤُلَاءِ مَن يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الْكَافِرُونَ (47) Bayen ni A se so Tira kale fun o. Nitori naa, awon ti A fun ni Tira, won gba a gbo. O si wa ninu awon wonyi (iyen, awon ara Mokkah), eni t’o gba a gbo. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alaigbagbo |
وَمَا كُنتَ تَتْلُو مِن قَبْلِهِ مِن كِتَابٍ وَلَا تَخُطُّهُ بِيَمِينِكَ ۖ إِذًا لَّارْتَابَ الْمُبْطِلُونَ (48) Iwo ko ke tira kan ri siwaju al-Ƙur’an, iwo ko si fi owo otun re ko nnkan ri. Bi bee ko nigba naa, ki awon opuro seyemeji (si al-Ƙur’an) |
بَلْ هُوَ آيَاتٌ بَيِّنَاتٌ فِي صُدُورِ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ ۚ وَمَا يَجْحَدُ بِآيَاتِنَا إِلَّا الظَّالِمُونَ (49) Rara (ko ri bi won se ro o. al-Ƙur’an), ohun ni awon ayah t’o yanju ninu igba-aya awon ti A fun ni imo-esin. Ko si si eni t’o n tako awon ayah Wa afi awon alabosi |
وَقَالُوا لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْهِ آيَاتٌ مِّن رَّبِّهِ ۖ قُلْ إِنَّمَا الْآيَاتُ عِندَ اللَّهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ (50) Won si wi pe: “Nitori ki ni Won ko se so awon ami (iyanu) kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Allahu nikan ni awon ami (iyanu) wa lodo Re. Ati pe olukilo ponnbele ni emi.” |
أَوَلَمْ يَكْفِهِمْ أَنَّا أَنزَلْنَا عَلَيْكَ الْكِتَابَ يُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَرَحْمَةً وَذِكْرَىٰ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ (51) Se ko to fun won (ni ami iyanu) pe A so tira (al-Ƙur’an) kale fun o, ti won n ke e fun won? Dajudaju ike ati isiti wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo |
قُلْ كَفَىٰ بِاللَّهِ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ شَهِيدًا ۖ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَالَّذِينَ آمَنُوا بِالْبَاطِلِ وَكَفَرُوا بِاللَّهِ أُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ (52) So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. O mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Awon t’o gba iro gbo, ti won si sai gbagbo ninu Allahu; awon wonyen, awon ni eni ofo |
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ ۚ وَلَوْلَا أَجَلٌ مُّسَمًّى لَّجَاءَهُمُ الْعَذَابُ وَلَيَأْتِيَنَّهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ (53) Won si n kan o loju nipa iya! Ti ko ba je pe o ti ni gbedeke akoko kan ni, iya naa iba kuku de ba won. (Iya) iba de ba won ni ojiji se, won ko si nii fura |
يَسْتَعْجِلُونَكَ بِالْعَذَابِ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةٌ بِالْكَافِرِينَ (54) Won n kan o loju nipa iya! Dajudaju ina Jahanamo kuku maa yi awon alaigbagbo po |
يَوْمَ يَغْشَاهُمُ الْعَذَابُ مِن فَوْقِهِمْ وَمِن تَحْتِ أَرْجُلِهِمْ وَيَقُولُ ذُوقُوا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (55) (Ranti) ojo ti iya yoo bo won mole lati oke won ati isale ese won, (Allahu) si maa so pe: “E to (iya) ohun ti e n se nise wo.” |
يَا عِبَادِيَ الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّ أَرْضِي وَاسِعَةٌ فَإِيَّايَ فَاعْبُدُونِ (56) Eyin erusin Mi, ti e gbagbo ni ododo, dajudaju ile Mi gbooro. Nitori naa, Emi nikan ni ki e josin fun |
كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا تُرْجَعُونَ (57) Gbogbo emi l’o maa to iku wo. Leyin naa, odo Wa ni won yoo da yin pada si |
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَنُبَوِّئَنَّهُم مِّنَ الْجَنَّةِ غُرَفًا تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ نِعْمَ أَجْرُ الْعَامِلِينَ (58) Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, dajudaju A maa fi won sinu awon ile peteesi giga kan ninu Ogba Idera, ti odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Esan awon oluse-rere si dara |
الَّذِينَ صَبَرُوا وَعَلَىٰ رَبِّهِمْ يَتَوَكَّلُونَ (59) (Awon ni) awon t’o se suuru. Oluwa won si ni won n gbarale |
وَكَأَيِّن مِّن دَابَّةٍ لَّا تَحْمِلُ رِزْقَهَا اللَّهُ يَرْزُقُهَا وَإِيَّاكُمْ ۚ وَهُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (60) Meloo meloo ninu awon eranko ti ko le da bukata ije-imu re gbe, ti Allahu si n se ije-imu fun awon ati eyin. Oun si ni Olugbo, Onimo |
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۖ فَأَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ (61) Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O da awon sanmo ati ile, ti O si ro oorun ati osupa?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” Nitori naa, bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo |
اللَّهُ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَيَقْدِرُ لَهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ (62) Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. O si n diwon re fun elomiiran. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
وَلَئِن سَأَلْتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ مِن بَعْدِ مَوْتِهَا لَيَقُولُنَّ اللَّهُ ۚ قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ (63) Ti o ba bi won leere pe: “Ta ni O so omi kale lati sanmo, ti O fi ta ile ji leyin ti o ti ku?”, dajudaju won a wi pe: “Allahu ni.” So pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, sugbon opolopo won ni ko se laakaye.” |
وَمَا هَٰذِهِ الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا لَهْوٌ وَلَعِبٌ ۚ وَإِنَّ الدَّارَ الْآخِرَةَ لَهِيَ الْحَيَوَانُ ۚ لَوْ كَانُوا يَعْلَمُونَ (64) Ki ni isemi aye yii bi ko se iranu ati ere sise. Ati pe dajudaju Ile Ikeyin si ni isemi gbere ti won ba mo |
فَإِذَا رَكِبُوا فِي الْفُلْكِ دَعَوُا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ فَلَمَّا نَجَّاهُمْ إِلَى الْبَرِّ إِذَا هُمْ يُشْرِكُونَ (65) Nigba ti won ba gun oko oju-omi, won yoo pe Allahu (gege bi) olusafomo-adua fun Un. Amo nigba ti O ba ko won yo si ori ile, nigba naa ni won yoo maa sebo |
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ وَلِيَتَمَتَّعُوا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ (66) nitori ki won le sai moore si nnkan ti A fun won ati nitori ki won le jayekaye. Nitori naa, laipe won maa mo |
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا جَعَلْنَا حَرَمًا آمِنًا وَيُتَخَطَّفُ النَّاسُ مِنْ حَوْلِهِمْ ۚ أَفَبِالْبَاطِلِ يُؤْمِنُونَ وَبِنِعْمَةِ اللَّهِ يَكْفُرُونَ (67) Se won ko ri i pe dajudaju Awa se Haram (Mokkah) ni aye ifayabale, ti won si n ji awon eniyan gbe lo ni ayika won? Se iro ni won yoo gbagbo, ti won yo si sai moore si idera Allahu |
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِالْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُ ۚ أَلَيْسَ فِي جَهَنَّمَ مَثْوًى لِّلْكَافِرِينَ (68) Ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu, tabi t’o pe ododo ni iro nigba ti o de ba a? Se inu ina Jahanamo ko ni ibugbe fun awon alaigbagbo ni |
وَالَّذِينَ جَاهَدُوا فِينَا لَنَهْدِيَنَّهُمْ سُبُلَنَا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَمَعَ الْمُحْسِنِينَ (69) Awon t’o gbiyanju nipa Wa, dajudaju A maa fi won mo awon ona Wa. Ati pe dajudaju Allahu wa pelu awon oluse-rere |