×

Leyin naa, O so ifayabale kale fun yin leyin ibanuje; oogbe ta 3:154 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah al-‘Imran ⮕ (3:154) ayat 154 in Yoruba

3:154 Surah al-‘Imran ayat 154 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 154 - آل عِمران - Page - Juz 4

﴿ثُمَّ أَنزَلَ عَلَيۡكُم مِّنۢ بَعۡدِ ٱلۡغَمِّ أَمَنَةٗ نُّعَاسٗا يَغۡشَىٰ طَآئِفَةٗ مِّنكُمۡۖ وَطَآئِفَةٞ قَدۡ أَهَمَّتۡهُمۡ أَنفُسُهُمۡ يَظُنُّونَ بِٱللَّهِ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ ظَنَّ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِۖ يَقُولُونَ هَل لَّنَا مِنَ ٱلۡأَمۡرِ مِن شَيۡءٖۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡأَمۡرَ كُلَّهُۥ لِلَّهِۗ يُخۡفُونَ فِيٓ أَنفُسِهِم مَّا لَا يُبۡدُونَ لَكَۖ يَقُولُونَ لَوۡ كَانَ لَنَا مِنَ ٱلۡأَمۡرِ شَيۡءٞ مَّا قُتِلۡنَا هَٰهُنَاۗ قُل لَّوۡ كُنتُمۡ فِي بُيُوتِكُمۡ لَبَرَزَ ٱلَّذِينَ كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَتۡلُ إِلَىٰ مَضَاجِعِهِمۡۖ وَلِيَبۡتَلِيَ ٱللَّهُ مَا فِي صُدُورِكُمۡ وَلِيُمَحِّصَ مَا فِي قُلُوبِكُمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ ﴾
[آل عِمران: 154]

Leyin naa, O so ifayabale kale fun yin leyin ibanuje; oogbe ta igun kan lo ninu yin. Igun kan ti emi ara won si ti ko ironu ba, ti won si n ni erokero si Allahu lona aito, erokero igba aimokan, won si n wi pe: “Nje a ni ase kan (ti a le mu wa) lori oro naa bi!” So pe: “Dajudaju gbogbo ase n je ti Allahu.” Won n fi pamo sinu okan won ohun ti won ko le safi han re fun o. Won n wi pe: "Ti o ba je pe a ni ase kan lori oro naa ni, won iba ti pa wa sibi." So pe: “Ti o ba je pe e wa ninu ile yin, awon ti A ti ko akoole pipa si ibujagun won mo iba kuku jade lo sibe.” (Ogun yii ri bee) nitori ki Allahu le gbidanwo ohun ti n be ninu igba-aya yin ati nitori ki O le safomo ohun ti n be ninu okan yin. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti n be ninu igba-aya eda

❮ Previous Next ❯

ترجمة: ثم أنـزل عليكم من بعد الغم أمنة نعاسا يغشى طائفة منكم وطائفة, باللغة اليوربا

﴿ثم أنـزل عليكم من بعد الغم أمنة نعاسا يغشى طائفة منكم وطائفة﴾ [آل عِمران: 154]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Lẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fun yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó ìrònú bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: "Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí." Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.” (Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek