Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 164 - آل عِمران - Page - Juz 4
﴿لَقَدۡ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ إِذۡ بَعَثَ فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡ أَنفُسِهِمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمۡ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلُ لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ ﴾
[آل عِمران: 164]
﴿لقد من الله على المؤمنين إذ بعث فيهم رسولا من أنفسهم يتلو﴾ [آل عِمران: 164]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Allāhu kúkú ti ṣe oore fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí Ó fi lè gbé Òjíṣẹ́ kan dìde sí wọn láààrin ara wọn. (Òjíṣẹ́ náà) ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà (al-Ƙur’ān) àti ìjìnlẹ̀ òye (sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé |