Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 73 - آل عِمران - Page - Juz 3
﴿وَلَا تُؤۡمِنُوٓاْ إِلَّا لِمَن تَبِعَ دِينَكُمۡ قُلۡ إِنَّ ٱلۡهُدَىٰ هُدَى ٱللَّهِ أَن يُؤۡتَىٰٓ أَحَدٞ مِّثۡلَ مَآ أُوتِيتُمۡ أَوۡ يُحَآجُّوكُمۡ عِندَ رَبِّكُمۡۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡفَضۡلَ بِيَدِ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ ﴾
[آل عِمران: 73]
﴿ولا تؤمنوا إلا لمن تبع دينكم قل إن الهدى هدى الله أن﴾ [آل عِمران: 73]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Wọ́n tún wí pé:) “Ẹ má gbàgbọ́ àyàfi ẹni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀sìn yín.” Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà (’Islām) ni ìmọ̀nà ti Allāhu.” (Wọ́n tún wí pé:) “(Ẹ má gbàgbọ́) pé wọ́n fún ẹnì kan ní irú ohun tí Wọ́n fun yín tàbí pé wọn yóò takò yín (tí wọn yó sì jàre yín) lọ́dọ̀ Olúwa yín.” Sọ pé: “Dájúdájú oore àjùlọ wà ní ọwọ́ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.” |