Quran with Yoruba translation - Surah As-saffat ayat 125 - الصَّافَات - Page - Juz 23
﴿أَتَدۡعُونَ بَعۡلٗا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ ﴾
[الصَّافَات: 125]
﴿أتدعون بعلا وتذرون أحسن الخالقين﴾ [الصَّافَات: 125]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni t’Ó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Òun l’Ó sì dára jùlọ nínú àwọn olùdájọ́. (sūrah al-’A‘rọ̄f 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Òun sì yára jùlọ nínú àwọn oníṣirò. (sūrah al-’Ani‘ām 6:62) olùdájọ́ aláàánú ìbáà mọ bíi ọmọ iná igún àfi kí Allāhu jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Kódà àdámọ́ owó àti okòwò tí wọ́n sọ di “ọrọ̀-Ajé. Àwọn t’ó ń bọ́ ẹlòmíìràn náà ń sọra wọn di olùpèsè. Yàtọ̀ sí pé Allāhu ti fi rinlẹ̀ pé Òun nìkan ni Olùpèsè fún gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Tí èyí kò bá tí ì dá àwọn kan lójú bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ gbé gbogbo ìpèsè olúkùlùkù lórí ìwọ̀n nínú àánú tí Allāhu fi sí àwọn ẹ̀dá kan lọ́kàn ni wọ́n fi di aláàánú. Nítorí náà Allāhu ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú |