وَالصَّافَّاتِ صَفًّا (1) (Allahu bura pelu) awon molaika oluto-lowoowo taara |
فَالزَّاجِرَاتِ زَجْرًا (2) ati awon molaika t’o n wo esujo kiri taara |
فَالتَّالِيَاتِ ذِكْرًا (3) ati awon molaika onke-tira iranti |
إِنَّ إِلَٰهَكُمْ لَوَاحِدٌ (4) Dajudaju Olohun yin, Okan soso ni |
رَّبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا وَرَبُّ الْمَشَارِقِ (5) Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Oun si ni Oluwa awon ibuyo oorun |
إِنَّا زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِزِينَةٍ الْكَوَاكِبِ (6) Dajudaju Awa fi awon irawo se sanmo ile aye ni oso |
وَحِفْظًا مِّن كُلِّ شَيْطَانٍ مَّارِدٍ (7) ati iso nibi (aburu) gbogbo esu olorikunkun |
لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى الْمَلَإِ الْأَعْلَىٰ وَيُقْذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٍ (8) (Awon esu) ko si nii le teti si ijo (molaika t’o wa ni) aye giga julo (ninu sanmo). (Awon molaika) yo si maa ku (awon esu) loko (eta irawo) ni gbogbo agbegbe (sanmo) |
دُحُورًا ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ وَاصِبٌ (9) Won n le won danu. Iya ailopin si wa fun won |
إِلَّا مَنْ خَطِفَ الْخَطْفَةَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ ثَاقِبٌ (10) (Won ko nii gbo oro ni kikun) ayafi eni ti o ba ri oro ajigbo gbe, nigba naa (ni molaika) yo si fi eta irawo ina t’o maa jo o tele e |
فَاسْتَفْتِهِمْ أَهُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَم مَّنْ خَلَقْنَا ۚ إِنَّا خَلَقْنَاهُم مِّن طِينٍ لَّازِبٍ (11) Bi won leere wo pe se awon ni iseda won lagbara julo ni tabi awon (eniyan) ti A da? Dajudaju Awa da won lati ara erupe t’o le mora won |
بَلْ عَجِبْتَ وَيَسْخَرُونَ (12) Rara (ko jora won); iwo seemo (nipa al-Ƙur’an), awon si n se yeye |
وَإِذَا ذُكِّرُوا لَا يَذْكُرُونَ (13) Ati pe nigba ti won ba se iranti fun won, won ko nii lo iranti |
وَإِذَا رَأَوْا آيَةً يَسْتَسْخِرُونَ (14) Nigba ti won ba tun ri ami kan, won yoo maa se yeye |
وَقَالُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُّبِينٌ (15) Won si wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se idan ponnbele |
أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ (16) Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo tun gbe wa dide ni |
أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ (17) Se ati awon baba wa, awon eni akoko |
قُلْ نَعَمْ وَأَنتُمْ دَاخِرُونَ (18) So pe: "Bee ni. Eyin yo si di eni yepere |
فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ فَإِذَا هُمْ يَنظُرُونَ (19) Nitori naa, igbe eyo kan ma ni. Nigba naa ni won yoo maa wo sun |
وَقَالُوا يَا وَيْلَنَا هَٰذَا يَوْمُ الدِّينِ (20) Won a wi pe: "Egbe wa! Eyi ni Ojo esan |
هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ الَّذِي كُنتُم بِهِ تُكَذِّبُونَ (21) Eyi ni ojo Idajo eyi ti e n pe niro |
۞ احْشُرُوا الَّذِينَ ظَلَمُوا وَأَزْوَاجَهُمْ وَمَا كَانُوا يَعْبُدُونَ (22) E ko awon t’o sabosi jo, awon iyawo won ati ohun ti won n josin fun |
مِن دُونِ اللَّهِ فَاهْدُوهُمْ إِلَىٰ صِرَاطِ الْجَحِيمِ (23) leyin Allahu. Ki e si juwe won si oju ona ina Jehim |
وَقِفُوهُمْ ۖ إِنَّهُم مَّسْئُولُونَ (24) E da won duro na, dajudaju won maa bi won leere ibeere |
مَا لَكُمْ لَا تَنَاصَرُونَ (25) Ki ni ko je ki e ranra yin lowo |
بَلْ هُمُ الْيَوْمَ مُسْتَسْلِمُونَ (26) Rara, won ti juwo juse sile ni oni ni |
وَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ (27) Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere |
قَالُوا إِنَّكُمْ كُنتُمْ تَأْتُونَنَا عَنِ الْيَمِينِ (28) (Awon eniyan) wi pe: "Dajudaju eyin l’e n gba otun wole si wa lara (lati si wa lona) |
قَالُوا بَل لَّمْ تَكُونُوا مُؤْمِنِينَ (29) (Awon alujannu) wi pe: "Rara o (awa ko), eyin ni e ko je onigbagbo ododo |
وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيْكُم مِّن سُلْطَانٍ ۖ بَلْ كُنتُمْ قَوْمًا طَاغِينَ (30) Ati pe awa ko ni agbara kan lori yin, sugbon eyin je ijo olutayo-enu ala |
فَحَقَّ عَلَيْنَا قَوْلُ رَبِّنَا ۖ إِنَّا لَذَائِقُونَ (31) Oro Oluwa wa si ko le wa lori pe dajudaju awa yoo to Ina wo |
فَأَغْوَيْنَاكُمْ إِنَّا كُنَّا غَاوِينَ (32) Nitori naa, a si yin lona. Dajudaju awa naa si je olusina |
فَإِنَّهُمْ يَوْمَئِذٍ فِي الْعَذَابِ مُشْتَرِكُونَ (33) Dajudaju ni ojo yen, akegbe ni won ninu Iya |
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِالْمُجْرِمِينَ (34) Dajudaju bayen ni Awa yoo ti se pelu awon elese |
إِنَّهُمْ كَانُوا إِذَا قِيلَ لَهُمْ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللَّهُ يَسْتَكْبِرُونَ (35) Dajudaju nigba ti won ba so fun won pe "Ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu.", won yoo maa segberaga |
وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُو آلِهَتِنَا لِشَاعِرٍ مَّجْنُونٍ (36) Won si n wi pe: "Se a maa fi awon orisa wa sile nitori elewi were kan |
بَلْ جَاءَ بِالْحَقِّ وَصَدَّقَ الْمُرْسَلِينَ (37) Ko ri bee. O mu ododo wa ni. O si n jerii si ododo awon Ojise naa |
إِنَّكُمْ لَذَائِقُو الْعَذَابِ الْأَلِيمِ (38) Dajudaju e maa to iya eleta-elero wo |
وَمَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (39) A o nii san yin ni esan kan afi ohun ti e n se nise |
إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ (40) Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
أُولَٰئِكَ لَهُمْ رِزْقٌ مَّعْلُومٌ (41) Ti awon wonyen si ni arisiki ti won ti mo |
فَوَاكِهُ ۖ وَهُم مُّكْرَمُونَ (42) awon eso. Awon si ni alapon-onle |
فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ (43) ninu awon Ogba Idera |
عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَابِلِينَ (44) Lori awon ite ni won yoo ti koju sira won |
يُطَافُ عَلَيْهِم بِكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ (45) Won yoo maa gbe ife oti mimo kaa kiri odo won |
بَيْضَاءَ لَذَّةٍ لِّلشَّارِبِينَ (46) Funfun ni (oti naa). O n dun lenu awon t’o maa mu un |
لَا فِيهَا غَوْلٌ وَلَا هُمْ عَنْهَا يُنزَفُونَ (47) Ko si ipalara kan fun won ninu re, won ko si nii hunrira lori re |
وَعِندَهُمْ قَاصِرَاتُ الطَّرْفِ عِينٌ (48) Awon obinrin ti ki i wo elomiiran, awon eleyinju ege yo si wa lodo won |
كَأَنَّهُنَّ بَيْضٌ مَّكْنُونٌ (49) Won da bi tinu eyin. o tun je ki a mo pe won ko reti ike kan kan lorun ni tiwon. Ti o ba je pe won n reti ike kan ni orun |
فَأَقْبَلَ بَعْضُهُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ يَتَسَاءَلُونَ (50) Apa kan won yoo doju ko apa kan, ti won yoo maa bira won leere ibeere |
قَالَ قَائِلٌ مِّنْهُمْ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٌ (51) Onsoro kan ninu won yoo so pe: "Dajudaju emi ni ore kan |
يَقُولُ أَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُصَدِّقِينَ (52) ti o n wi pe, “Se dajudaju iwo wa ninu awon onigbagbo ninu Ojo Ajinde |
أَإِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَدِينُونَ (53) Se nigba ti a ba ku tan, ti a ti di erupe ati egungun, se dajudaju Won yoo san wa ni esan ni?” |
قَالَ هَلْ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ (54) O so pe: "Se eyin yoo yoju wo (eni naa ti ko gbagbo ninu Ojo ajinde) |
فَاطَّلَعَ فَرَآهُ فِي سَوَاءِ الْجَحِيمِ (55) O yoju wo o. O si ri i laaarin gbungbun ninu ina Jehim |
قَالَ تَاللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرْدِينِ (56) O (si) so pe: "Mo fi Allahu bura, iwo fee ko iparun ba mi tan |
وَلَوْلَا نِعْمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ الْمُحْضَرِينَ (57) Ati pe ti ki i ba se idera Oluwa mi ni, emi naa iba wa ninu eni ti won maa mu wa sinu Ina |
أَفَمَا نَحْنُ بِمَيِّتِينَ (58) Awa ko sa nii ku mo bayii |
إِلَّا مَوْتَتَنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ (59) Afi iku wa akoko. Won ko si nii je awa niya |
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (60) Dajudaju eyi, ohun ni erenje nla |
لِمِثْلِ هَٰذَا فَلْيَعْمَلِ الْعَامِلُونَ (61) Nitori iru eyi, ki awon olusesin maa sesin lo |
أَذَٰلِكَ خَيْرٌ نُّزُلًا أَمْ شَجَرَةُ الزَّقُّومِ (62) Nje iyen l’o loore julo ni ibudesi ni tabi igi zaƙum (igi elegun-un) |
إِنَّا جَعَلْنَاهَا فِتْنَةً لِّلظَّالِمِينَ (63) Dajudaju Awa se e ni adanwo fun awon alabosi |
إِنَّهَا شَجَرَةٌ تَخْرُجُ فِي أَصْلِ الْجَحِيمِ (64) Dajudaju ohun ni igi kan ti o maa hu jade lati idi ina Jehim |
طَلْعُهَا كَأَنَّهُ رُءُوسُ الشَّيَاطِينِ (65) Eso re da bi ori awon esu |
فَإِنَّهُمْ لَآكِلُونَ مِنْهَا فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ (66) Dajudaju won yoo maa je ninu re. Nitori naa, won yoo fi kun inu won bamubamu |
ثُمَّ إِنَّ لَهُمْ عَلَيْهَا لَشَوْبًا مِّنْ حَمِيمٍ (67) Leyin naa, dajudaju won yoo mu nnkan mimu awoyunweje gbigbona le e lori |
ثُمَّ إِنَّ مَرْجِعَهُمْ لَإِلَى الْجَحِيمِ (68) Leyin naa, dajudaju ibupadasi won ni ina Jehim |
إِنَّهُمْ أَلْفَوْا آبَاءَهُمْ ضَالِّينَ (69) Dajudaju won ba awon baba won ni olusina |
فَهُمْ عَلَىٰ آثَارِهِمْ يُهْرَعُونَ (70) Awon naa si n yara tele oripa won |
وَلَقَدْ ضَلَّ قَبْلَهُمْ أَكْثَرُ الْأَوَّلِينَ (71) Dajudaju opolopo awon eni akoko ti sina siwaju won |
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ (72) Dajudaju A ti ran awon olukilo si won |
فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُنذَرِينَ (73) Nitori naa, wo bi atubotan awon eni-akilo-fun ti ri |
إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ (74) Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
وَلَقَدْ نَادَانَا نُوحٌ فَلَنِعْمَ الْمُجِيبُونَ (75) Dajudaju (Anabi) Nuh pe Wa. A si dara ni olujepe |
وَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ (76) A gba oun ati awon ara ile re la kuro ninu ibanuje nla |
وَجَعَلْنَا ذُرِّيَّتَهُ هُمُ الْبَاقِينَ (77) A da awon aromodomo re si leyin re |
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ (78) A si fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
سَلَامٌ عَلَىٰ نُوحٍ فِي الْعَالَمِينَ (79) Alaafia ki o maa ba (Anabi) Nuh laaarin gbogbo eda |
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (80) Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ (81) Dajudaju oun wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ (82) Leyin naa, A te awon yooku ri sinu agbami |
۞ وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِ لَإِبْرَاهِيمَ (83) Dajudaju (Anabi) ’Ibrohim wa ninu ijo (ti o tele ilana) re |
إِذْ جَاءَ رَبَّهُ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ (84) (E ranti) nigba ti oun naa doju ko Oluwa re pelu okan mimo |
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَاذَا تَعْبُدُونَ (85) (Ranti) nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: "Ki ni e n josin fun |
أَئِفْكًا آلِهَةً دُونَ اللَّهِ تُرِيدُونَ (86) Se e n gbero lati so iro di olohun leyin Allahu |
فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ الْعَالَمِينَ (87) Ki si ni ero okan yin si Oluwa gbogbo eda?” |
فَنَظَرَ نَظْرَةً فِي النُّجُومِ (88) O siju wo awon irawo gan-an |
فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٌ (89) O si so pe: "Dajudaju o re mi |
فَتَوَلَّوْا عَنْهُ مُدْبِرِينَ (90) Nitori naa, won pa a ti, won si lo |
فَرَاغَ إِلَىٰ آلِهَتِهِمْ فَقَالَ أَلَا تَأْكُلُونَ (91) Nigba naa, o lo si odo awon orisa won. O si so pe: "Se e o nii jeun ni |
مَا لَكُمْ لَا تَنطِقُونَ (92) Ki ni o se yin ti e o soro |
فَرَاغَ عَلَيْهِمْ ضَرْبًا بِالْيَمِينِ (93) Nigba naa, o doju lilu ko won pelu owo otun (o si run won womuwomu) |
فَأَقْبَلُوا إِلَيْهِ يَزِفُّونَ (94) (Awon aborisa) sare wa doju ko o |
قَالَ أَتَعْبُدُونَ مَا تَنْحِتُونَ (95) O so pe: "Se e oo maa josin fun nnkan ti e gbe kale lere ni |
وَاللَّهُ خَلَقَكُمْ وَمَا تَعْمَلُونَ (96) Allahu l’O si da eyin ati nnkan ti e n se nise |
قَالُوا ابْنُوا لَهُ بُنْيَانًا فَأَلْقُوهُ فِي الْجَحِيمِ (97) Won wi pe: "E mo ile kan fun un, ki e si ju u sinu ina |
فَأَرَادُوا بِهِ كَيْدًا فَجَعَلْنَاهُمُ الْأَسْفَلِينَ (98) Won gbero ete si i. A si so won di eni yepere |
وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهْدِينِ (99) O so pe: "Dajudaju mo maa lo si (ilu ti) Oluwa mi (pa mi lase lati lo). O si maa to mi sona (lati de ibe) |
رَبِّ هَبْ لِي مِنَ الصَّالِحِينَ (100) Oluwa mi, ta mi lore omo ninu awon eni rere |
فَبَشَّرْنَاهُ بِغُلَامٍ حَلِيمٍ (101) A si fun un ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin alafarada |
فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ السَّعْيَ قَالَ يَا بُنَيَّ إِنِّي أَرَىٰ فِي الْمَنَامِ أَنِّي أَذْبَحُكَ فَانظُرْ مَاذَا تَرَىٰ ۚ قَالَ يَا أَبَتِ افْعَلْ مَا تُؤْمَرُ ۖ سَتَجِدُنِي إِن شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّابِرِينَ (102) Nigba ti (omo naa) dagba, ti o to ba (baba re) se ise, (baba re) so pe: "Omo mi, dajudaju emi la ala pe dajudaju mo n dunbu re. Nitori naa, woye si i, ki ni o ri si i." O so pe: "Baba mi, se ohun ti Won pa lase fun o. O maa ba mi ninu awon onisuuru, ti Allahu ba fe |
فَلَمَّا أَسْلَمَا وَتَلَّهُ لِلْجَبِينِ (103) Nigba ti awon mejeeji juwo juse sile, ti (Anabi ’Ibrohim) si doju (omo) re bole |
وَنَادَيْنَاهُ أَن يَا إِبْرَاهِيمُ (104) A pe e (bayii) pe, ’Ibrohim |
قَدْ صَدَّقْتَ الرُّؤْيَا ۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (105) o kuku ti mu ala naa se. Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ الْبَلَاءُ الْمُبِينُ (106) Dajudaju eyi, ohun ni adanwo ponnbele |
وَفَدَيْنَاهُ بِذِبْحٍ عَظِيمٍ (107) A si fi agbo nla serapada re |
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ (108) A tun fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
سَلَامٌ عَلَىٰ إِبْرَاهِيمَ (109) Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ibrohim |
كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (110) Bayen ni A se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ (111) Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
وَبَشَّرْنَاهُ بِإِسْحَاقَ نَبِيًّا مِّنَ الصَّالِحِينَ (112) A tun fun un ni iro idunnu (nipa bibi) ’Ishaƙ, (o maa je) Anabi. (O si maa wa) ninu awon eni rere |
وَبَارَكْنَا عَلَيْهِ وَعَلَىٰ إِسْحَاقَ ۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحْسِنٌ وَظَالِمٌ لِّنَفْسِهِ مُبِينٌ (113) Ati pe A fun oun ati ’Ishaƙ ni ibukun. Eni rere ati alabosi ponnbele (t’o n sabosi si) emi ara re wa ninu aromodomo awon mejeeji |
وَلَقَدْ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ (114) Dajudaju A soore fun (Anabi) Musa ati Harun |
وَنَجَّيْنَاهُمَا وَقَوْمَهُمَا مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ (115) A gba awon mejeeji ati ijo awon mejeeji la kuro ninu ibanuje nla |
وَنَصَرْنَاهُمْ فَكَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ (116) A tun saranse fun won. Awon ni won je olubori (ota won) |
وَآتَيْنَاهُمَا الْكِتَابَ الْمُسْتَبِينَ (117) A si fun awon mejeeji ni Tira t’o yanju |
وَهَدَيْنَاهُمَا الصِّرَاطَ الْمُسْتَقِيمَ (118) A tun fi awon mejeeji mona taara |
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِمَا فِي الْآخِرِينَ (119) A fun awon mejeeji ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
سَلَامٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَارُونَ (120) Alaafia ki o maa ba (Anabi) Musa ati Harun |
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (121) Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
إِنَّهُمَا مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ (122) Dajudaju awon mejeeji wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
وَإِنَّ إِلْيَاسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ (123) Dajudaju (Anabi) ’Ilyas wa ninu awon Ojise |
إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ أَلَا تَتَّقُونَ (124) (E ranti) nigba ti o so fun ijo re pe: "Se e o nii beru Allahu ni |
أَتَدْعُونَ بَعْلًا وَتَذَرُونَ أَحْسَنَ الْخَالِقِينَ (125) Se e oo maa pe orisa kan, e si maa fi Eni t’O dara julo ninu awon eledaa sile, وَهُوَ خَيْرُ ٱلْحَٰكِمِينَ Oun l’O si dara julo ninu awon oludajo. (surah al-’A‘rof 7:87) وَهُوَ أَسْرَعُ ٱلْحَٰسِبِينَ Oun si yara julo ninu awon onisiro. (surah al-’Ani‘am 6:62) oludajo alaaanu ibaa mo bii omo ina igun afi ki Allahu je Eledaa re. Koda adamo owo ati okowo ti won so di “oro-Aje. Awon t’o n bo elomiiran naa n sora won di olupese. Yato si pe Allahu ti fi rinle pe Oun nikan ni Olupese fun gbogbo eda Re. Ti eyi ko ba ti i da awon kan loju bee ti won si fe gbe gbogbo ipese olukuluku lori iwon ninu aanu ti Allahu fi si awon eda kan lokan ni won fi di alaaanu. Nitori naa Allahu ni Alaaanu julo ninu awon alaaanu |
اللَّهَ رَبَّكُمْ وَرَبَّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ (126) (e n fi) Allahu (sile), Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko |
فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ (127) Won si pe e ni opuro. Nitori naa, won maa mu won wa sinu Ina |
إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ (128) Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
وَتَرَكْنَا عَلَيْهِ فِي الْآخِرِينَ (129) A fun un ni oruko rere laaarin awon eni ikeyin |
سَلَامٌ عَلَىٰ إِلْ يَاسِينَ (130) Alaafia ki o maa ba (Anabi) ’Ilyas |
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (131) Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere) |
إِنَّهُ مِنْ عِبَادِنَا الْمُؤْمِنِينَ (132) Dajudaju o wa ninu awon erusin Wa, awon onigbagbo ododo |
وَإِنَّ لُوطًا لَّمِنَ الْمُرْسَلِينَ (133) Dajudaju (Anabi) Lut wa ninu awon Ojise |
إِذْ نَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ (134) (E ranti) nigba ti A gba oun ati gbogbo awon ara ile re la |
إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ (135) Ayafi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare) |
ثُمَّ دَمَّرْنَا الْآخَرِينَ (136) Leyin naa, A pa awon yooku run |
وَإِنَّكُمْ لَتَمُرُّونَ عَلَيْهِم مُّصْبِحِينَ (137) Dajudaju eyin naa kuku n gba odo won koja laaaro-laaaro |
وَبِاللَّيْلِ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ (138) ati ni alaale. Se e o nii se laakaye ni |
وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ (139) Dajudaju (Anabi) Yunus kuku wa ninu awon Ojise |
إِذْ أَبَقَ إِلَى الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ (140) (E ranti) nigba ti o sa lo sinu oko oju-omi t’o kun keke |
فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ الْمُدْحَضِينَ (141) O si ba won muje po. O si wa ninu awon ti aje si mo lori |
فَالْتَقَمَهُ الْحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٌ (142) Nitori naa, eja gbe e mi; o si n da ara re lebi |
فَلَوْلَا أَنَّهُ كَانَ مِنَ الْمُسَبِّحِينَ (143) Nitori naa, ti ko ba je pe o wa ninu awon olusafomo fun Allahu |
لَلَبِثَ فِي بَطْنِهِ إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ (144) dajudaju iba wa ninu eja titi di ojo ti won yoo gbe eda dide |
۞ فَنَبَذْنَاهُ بِالْعَرَاءِ وَهُوَ سَقِيمٌ (145) Nitori naa, A ju u si ori ile gbansasa leti omi. O si je alailera |
وَأَنبَتْنَا عَلَيْهِ شَجَرَةً مِّن يَقْطِينٍ (146) A si mu igi Yeƙtin hu jade lati siji bo o |
وَأَرْسَلْنَاهُ إِلَىٰ مِائَةِ أَلْفٍ أَوْ يَزِيدُونَ (147) A tun ran an nise si oke marun-un (eniyan) tabi ki won lekun si i |
فَآمَنُوا فَمَتَّعْنَاهُمْ إِلَىٰ حِينٍ (148) Won gbagbo ni ododo. A si fun won ni igbadun titi di igba die |
فَاسْتَفْتِهِمْ أَلِرَبِّكَ الْبَنَاتُ وَلَهُمُ الْبَنُونَ (149) Bi won leere wo pe: "Se Oluwa re l’o ni awon omobinrin, tiwon si ni omokunrin |
أَمْ خَلَقْنَا الْمَلَائِكَةَ إِنَاثًا وَهُمْ شَاهِدُونَ (150) Tabi A da awon molaika ni obinrin, ti awon si je elerii |
أَلَا إِنَّهُم مِّنْ إِفْكِهِمْ لَيَقُولُونَ (151) Gbo, ninu iro won ni pe dajudaju won n wi pe |
وَلَدَ اللَّهُ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ (152) Allahu bimo." Dajudaju opuro ni won |
أَصْطَفَى الْبَنَاتِ عَلَى الْبَنِينَ (153) Se (Allahu) sesa awon omobinrin lori awon omokunrin ni |
مَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ (154) Ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii |
أَفَلَا تَذَكَّرُونَ (155) Se e o nii lo iranti ni |
أَمْ لَكُمْ سُلْطَانٌ مُّبِينٌ (156) Tabi e ni eri t’o yanju lowo ni |
فَأْتُوا بِكِتَابِكُمْ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (157) E mu tira yin wa nigba naa ti e ba je olododo |
وَجَعَلُوا بَيْنَهُ وَبَيْنَ الْجِنَّةِ نَسَبًا ۚ وَلَقَدْ عَلِمَتِ الْجِنَّةُ إِنَّهُمْ لَمُحْضَرُونَ (158) Won tun fi ibatan saaarin (Allahu) ati alujannu! Awon alujannu si ti mo pe dajudaju won kuku maa mu awon wa sinu Ina ni |
سُبْحَانَ اللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ (159) Mimo ni fun Allahu tayo ohun ti won n fi royin (Re) |
إِلَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ (160) Afi awon erusin Allahu, awon eni esa |
فَإِنَّكُمْ وَمَا تَعْبُدُونَ (161) Dajudaju eyin ati nnkan ti e n josin fun (leyin Allahu) |
مَا أَنتُمْ عَلَيْهِ بِفَاتِنِينَ (162) e o le fi si eni kan kan lona |
إِلَّا مَنْ هُوَ صَالِ الْجَحِيمِ (163) afi eni ti o ba fe wo inu ina Jehim |
وَمَا مِنَّا إِلَّا لَهُ مَقَامٌ مَّعْلُومٌ (164) Ko si eni kan ninu awa (molaika) afi ki o ni ibuduro ti won ti mo |
وَإِنَّا لَنَحْنُ الصَّافُّونَ (165) Dajudaju awa, a kuku wa ni owoowo |
وَإِنَّا لَنَحْنُ الْمُسَبِّحُونَ (166) Ati pe dajudaju awa, awa kuku ni olusafomo (fun Allahu) |
وَإِن كَانُوا لَيَقُولُونَ (167) Won kuku n wi pe |
لَوْ أَنَّ عِندَنَا ذِكْرًا مِّنَ الْأَوَّلِينَ (168) Ti o ba je pe dajudaju a ba ni (tira) iranti kan ninu (awon tira) awon eni akoko |
لَكُنَّا عِبَادَ اللَّهِ الْمُخْلَصِينَ (169) dajudaju awa iba je erusin Allahu, awon eni esa |
فَكَفَرُوا بِهِ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ (170) Sugbon won sai gbagbo ninu (Allahu). Laipe won maa mo |
وَلَقَدْ سَبَقَتْ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا الْمُرْسَلِينَ (171) Dajudaju oro Wa ti siwaju fun awon erusin Wa, awon Ojise |
إِنَّهُمْ لَهُمُ الْمَنصُورُونَ (172) Dajudaju awon, awon l’a kuku maa saranse fun |
وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ الْغَالِبُونَ (173) Ati pe dajudaju awon omo ogun Wa, awon kuku ni olubori |
فَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ (174) Nitori naa, seri kuro lodo won fun igba die |
وَأَبْصِرْهُمْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ (175) Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo |
أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ (176) Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju |
فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمْ فَسَاءَ صَبَاحُ الْمُنذَرِينَ (177) Nigba ti o ba sokale si agboole won, owuro ojo naa yo si buru fun awon eni-akilo-fun |
وَتَوَلَّ عَنْهُمْ حَتَّىٰ حِينٍ (178) Kuro lodo won titi di igba kan na |
وَأَبْصِرْ فَسَوْفَ يُبْصِرُونَ (179) Ati pe maa wo won niran na, awon naa n bo wa riran wo |
سُبْحَانَ رَبِّكَ رَبِّ الْعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ (180) Mimo ni fun Oluwa re, Oluwa agbara, tayo ohun ti won n fi royin (Re) |
وَسَلَامٌ عَلَى الْمُرْسَلِينَ (181) Ki alaafia maa ba awon Ojise |
وَالْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ (182) Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda |