Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 159 - النِّسَاء - Page - Juz 6
﴿وَإِن مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا لَيُؤۡمِنَنَّ بِهِۦ قَبۡلَ مَوۡتِهِۦۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكُونُ عَلَيۡهِمۡ شَهِيدٗا ﴾
[النِّسَاء: 159]
﴿وإن من أهل الكتاب إلا ليؤمنن به قبل موته ويوم القيامة يكون﴾ [النِّسَاء: 159]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn ahlul-kitāb (láyé nígbà tí ‘Īsā bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gbà á gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú rẹ̀. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, ó sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn. àgbéga ipò gẹ́gẹ́ bí èyí t’ó jẹyọ nínú sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:176 àti sūrah Mọryam; 19:57) tàbí kí ó túmọ̀ sí àgbéga tara (ìyẹn gbígbé ara kúrò láti àyè ìsàlẹ̀ sí àyè òkè gẹ́gẹ́ bí èyí t’ó jẹyọ nínú sūrah Fātir; 35:10). Àmọ́ kò ní tàbí-ṣùgbọ́n nínú mọ́ pé nígbàkígbà tí harafi “إلى” bá ti tẹ̀lé “رفع” òkè sánmọ̀ keje ni Allahu wà nítorí pé inú sánmọ̀ yìí náà ni Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gùn lọ láti lọ gba ìrun wákàtí márùn-ún wá lọ́dọ̀ Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) lásìkò ìrìn òru àti ìgun-sánmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi rinlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ sūrah al-’Isrọ̄’. Kódà tòhun ti bí àìgbàgbọ́ Fir‘aon ṣe gbópọn tó ó kúkú gbà pé sánmọ̀ ni Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) wà. Ó sì bẹ Hāmọ̄n ní ilé gíga fíofío kọ́. Ó fẹ́ yọjú wo Allāhu! (sūrah al-Ƙọsọs; 28:38). Nítorí náà |