×

Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ki e 4:171 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah An-Nisa’ ⮕ (4:171) ayat 171 in Yoruba

4:171 Surah An-Nisa’ ayat 171 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 171 - النِّسَاء - Page - Juz 6

﴿يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا تَغۡلُواْ فِي دِينِكُمۡ وَلَا تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّۚ إِنَّمَا ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ رَسُولُ ٱللَّهِ وَكَلِمَتُهُۥٓ أَلۡقَىٰهَآ إِلَىٰ مَرۡيَمَ وَرُوحٞ مِّنۡهُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۖ وَلَا تَقُولُواْ ثَلَٰثَةٌۚ ٱنتَهُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ إِنَّمَا ٱللَّهُ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓ أَن يَكُونَ لَهُۥ وَلَدٞۘ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا ﴾
[النِّسَاء: 171]

Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ki e si ma so ohun kan nipa Allahu afi ododo. Ojise Allahu ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Oro Re (kun fayakun) ti O so ranse si Moryam l’O si fi seda re. Emi kan (ti Allahu seda) lati odo Re si ni (Mosih ‘Isa omo Moryam). Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. E ye so meta (lokan) mo. Ki e jawo nibe lo je oore fun yin. Allahu nikan ni Olohun, Okan soso (ti ijosin to si). O mo tayo ki O ni omo. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si to ni Alamojuuto

❮ Previous Next ❯

ترجمة: ياأهل الكتاب لا تغلوا في دينكم ولا تقولوا على الله إلا الحق, باللغة اليوربا

﴿ياأهل الكتاب لا تغلوا في دينكم ولا تقولوا على الله إلا الحق﴾ [النِّسَاء: 171]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Ẹ̀yin ahlul-kitāb, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-àlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fun yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo (tí ìjọ́sìn tọ́ sí). Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek