×

Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Toro aforijin fun 40:55 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah Ghafir ⮕ (40:55) ayat 55 in Yoruba

40:55 Surah Ghafir ayat 55 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah Ghafir ayat 55 - غَافِر - Page - Juz 24

﴿فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ ﴾
[غَافِر: 55]

Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Toro aforijin fun ese re. Ki o si se afomo pelu idupe fun Oluwa re ni asale ati ni owuro kutukutu. awon ti Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) tu sile wonyi awon ni olori awon osebo ninu ilu Mokkah. Won si ti pa awon musulumi kan nipakupa siwaju ki owo to te awon naa loju ogun Badr. Amo ohun ti Anabi Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) ro t’o fi tu won sile ni pe ‘O gba iyawo lowo omo re o si fi saya!’. Oro ko si ri bee nitori pe a o gbodo foju bin-intin wo eyikeyii asise tabi ese. A gbodo kun fun titoro aforijin ni lodo Allahu Alaforijin. Ko si ohun t’o dara to riri aforijin gba lodo Allahu lori gbogbo asise wa siwaju ojo iku wa

❮ Previous Next ❯

ترجمة: فاصبر إن وعد الله حق واستغفر لذنبك وسبح بحمد ربك بالعشي والإبكار, باللغة اليوربا

﴿فاصبر إن وعد الله حق واستغفر لذنبك وسبح بحمد ربك بالعشي والإبكار﴾ [غَافِر: 55]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa rẹ ní àṣálẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. àwọn tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) tú sílẹ̀ wọ̀nyí àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) rò t’ó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé ‘Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀ ó sì fi ṣaya!’. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé a ò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu Aláforíjìn. Kò sí ohun t’ó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek