×

(Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O 42:13 Yoruba translation

Quran infoYorubaSurah Ash-Shura ⮕ (42:13) ayat 13 in Yoruba

42:13 Surah Ash-Shura ayat 13 in Yoruba (اليوربا)

Quran with Yoruba translation - Surah Ash-Shura ayat 13 - الشُّوري - Page - Juz 25

﴿۞ شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحٗا وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَمَا وَصَّيۡنَا بِهِۦٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓۖ أَنۡ أَقِيمُواْ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُواْ فِيهِۚ كَبُرَ عَلَى ٱلۡمُشۡرِكِينَ مَا تَدۡعُوهُمۡ إِلَيۡهِۚ ٱللَّهُ يَجۡتَبِيٓ إِلَيۡهِ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَن يُنِيبُ ﴾
[الشُّوري: 13]

(Allahu) se ni ofin fun yin ninu esin (’Islam) ohun ti O pa ni ase fun (Anabi) Nuh ati eyi ti O fi ranse si o, ati ohun ti A pa lase fun (Anabi) ’Ibrohim, (Anabi) Musa ati (Anabi) ‘Isa pe ki e gbe esin naa duro. Ki e si ma se pin si ijo otooto ninu re. Wahala l’o je fun awon osebo nipa nnkan ti o n pe won si (nibi mimu Allahu ni okan soso). Allahu l’O n sesa eni ti O ba fe sinu esin Re (ti o n pe won si). O si n fi ona mo eni ti o ba n seri pada si odo Re (nipase ironupiwada)

❮ Previous Next ❯

ترجمة: شرع لكم من الدين ما وصى به نوحا والذي أوحينا إليك وما, باللغة اليوربا

﴿شرع لكم من الدين ما وصى به نوحا والذي أوحينا إليك وما﴾ [الشُّوري: 13]

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni
(Allāhu) ṣe ní òfin fun yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà)
❮ Previous Next ❯

Verse in more languages

Transliteration Bangla Bosnian German English Persian French Hindi Indonesian Kazakh Dutch Russian Spanish Turkish Urdu Uzbek