Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ma’idah ayat 72 - المَائدة - Page - Juz 6
﴿لَقَدۡ كَفَرَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ مَرۡيَمَۖ وَقَالَ ٱلۡمَسِيحُ يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمۡۖ إِنَّهُۥ مَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ حَرَّمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ ٱلۡجَنَّةَ وَمَأۡوَىٰهُ ٱلنَّارُۖ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٖ ﴾
[المَائدة: 72]
﴿لقد كفر الذين قالوا إن الله هو المسيح ابن مريم وقال المسيح﴾ [المَائدة: 72]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t’ó wí pé: “Dájúdájú Allāhu, Òun ni Mọsīh ọmọ Mọryam.” Mọsīh sì sọ pé: "Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ jọ́sìn fún Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bá Allāhu wá akẹgbẹ́, Allāhu ti ṣe Ọgbà Ìdẹ̀ra ní èèwọ̀ fún un. Iná sì ni ibùgbé rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí |