Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ma’idah ayat 95 - المَائدة - Page - Juz 7
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡتُلُواْ ٱلصَّيۡدَ وَأَنتُمۡ حُرُمٞۚ وَمَن قَتَلَهُۥ مِنكُم مُّتَعَمِّدٗا فَجَزَآءٞ مِّثۡلُ مَا قَتَلَ مِنَ ٱلنَّعَمِ يَحۡكُمُ بِهِۦ ذَوَا عَدۡلٖ مِّنكُمۡ هَدۡيَۢا بَٰلِغَ ٱلۡكَعۡبَةِ أَوۡ كَفَّٰرَةٞ طَعَامُ مَسَٰكِينَ أَوۡ عَدۡلُ ذَٰلِكَ صِيَامٗا لِّيَذُوقَ وَبَالَ أَمۡرِهِۦۗ عَفَا ٱللَّهُ عَمَّا سَلَفَۚ وَمَنۡ عَادَ فَيَنتَقِمُ ٱللَّهُ مِنۡهُۚ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ ﴾
[المَائدة: 95]
﴿ياأيها الذين آمنوا لا تقتلوا الصيد وأنتم حرم ومن قتله منكم متعمدا﴾ [المَائدة: 95]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ìtánràn rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l’ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó jẹ́) ẹran ìtánràn tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí ààrọ̀ ìyẹn ni ààwẹ̀, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun t’ó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ hurumi), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san |