Quran with Yoruba translation - Surah Al-Mujadilah ayat 11 - المُجَادلة - Page - Juz 28
﴿يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَكُمۡ تَفَسَّحُواْ فِي ٱلۡمَجَٰلِسِ فَٱفۡسَحُواْ يَفۡسَحِ ٱللَّهُ لَكُمۡۖ وَإِذَا قِيلَ ٱنشُزُواْ فَٱنشُزُواْ يَرۡفَعِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡ وَٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ دَرَجَٰتٖۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ ﴾
[المُجَادلة: 11]
﴿ياأيها الذين آمنوا إذا قيل لكم تفسحوا في المجالس فافسحوا يفسح الله﴾ [المُجَادلة: 11]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá sọ fun yín pé kí ẹ gbara yín láyè nínú àwọn ibùjókòó, ẹ gbara yín láyè. Allāhu yóò f’àyè gbà yín. Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: "Ẹ dìde (síbi iṣẹ́ rere)." Ẹ dìde (sí i). Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ |