Quran with Yoruba translation - Surah Al-hashr ayat 2 - الحَشر - Page - Juz 28
﴿هُوَ ٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن دِيَٰرِهِمۡ لِأَوَّلِ ٱلۡحَشۡرِۚ مَا ظَنَنتُمۡ أَن يَخۡرُجُواْۖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مَّانِعَتُهُمۡ حُصُونُهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَأَتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِنۡ حَيۡثُ لَمۡ يَحۡتَسِبُواْۖ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَۚ يُخۡرِبُونَ بُيُوتَهُم بِأَيۡدِيهِمۡ وَأَيۡدِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ فَٱعۡتَبِرُواْ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ ﴾
[الحَشر: 2]
﴿هو الذي أخرج الذين كفروا من أهل الكتاب من ديارهم لأول الحشر﴾ [الحَشر: 2]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlu-l-kitāb jáde kúrò nínú ilé wọn fún ìkójọ àkọ́kọ́. Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran |