Quran with Yoruba translation - Surah Al-An‘am ayat 14 - الأنعَام - Page - Juz 7
﴿قُلۡ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَتَّخِذُ وَلِيّٗا فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَهُوَ يُطۡعِمُ وَلَا يُطۡعَمُۗ قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَسۡلَمَۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴾
[الأنعَام: 14]
﴿قل أغير الله أتخذ وليا فاطر السموات والأرض وهو يطعم ولا يطعم﴾ [الأنعَام: 14]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).” Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ. òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Èyí ni àwọn kan mọ̀ sí “ṣíṣe ìfẹ́-Ọlọ́hun”. Èwo nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni kò juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ pátápátá fún àṣẹ Allāhu òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀? Èwo nínú wọn sẹ́ ni kò ṣe ìfẹ́-Ọlọ́hun? Kò sí. Ìdí nìyí ti gbogbo wọn fi jẹ́ mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bi Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe fi rinlẹ̀ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:128-141. òfin Rẹ̀ àti ìlànà Rẹ̀. Àmọ́ nínú ìjọ rẹ̀ òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ |