Quran with Yoruba translation - Surah At-Taghabun ayat 9 - التغَابُن - Page - Juz 28
﴿يَوۡمَ يَجۡمَعُكُمۡ لِيَوۡمِ ٱلۡجَمۡعِۖ ذَٰلِكَ يَوۡمُ ٱلتَّغَابُنِۗ وَمَن يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ وَيَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا يُكَفِّرۡ عَنۡهُ سَيِّـَٔاتِهِۦ وَيُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ﴾
[التغَابُن: 9]
﴿يوم يجمعكم ليوم الجمع ذلك يوم التغابن ومن يؤمن بالله ويعمل صالحا﴾ [التغَابُن: 9]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ní ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá |