Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 22 - الأعرَاف - Page - Juz 8
﴿فَدَلَّىٰهُمَا بِغُرُورٖۚ فَلَمَّا ذَاقَا ٱلشَّجَرَةَ بَدَتۡ لَهُمَا سَوۡءَٰتُهُمَا وَطَفِقَا يَخۡصِفَانِ عَلَيۡهِمَا مِن وَرَقِ ٱلۡجَنَّةِۖ وَنَادَىٰهُمَا رَبُّهُمَآ أَلَمۡ أَنۡهَكُمَا عَن تِلۡكُمَا ٱلشَّجَرَةِ وَأَقُل لَّكُمَآ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لَكُمَا عَدُوّٞ مُّبِينٞ ﴾
[الأعرَاف: 22]
﴿فدلاهما بغرور فلما ذاقا الشجرة بدت لهما سوآتهما وطفقا يخصفان عليهما من﴾ [الأعرَاف: 22]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ó sì tan àwọn méjèèjì jẹ. Nígbà tí àwọn méjèèjì tọ́ igi náà wò, ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bora wọn. Olúwa àwọn méjèèjì sì pè wọ́n pé: "Ǹjẹ́ Èmi kò ti kọ igi náà fun ẹ̀yin méjèèjì? (Ṣé) Èmi kò sì ti sọ fún ẹ̀yin méjèèjì pé ọ̀tá pọ́nńbélé ni Èṣù jẹ́ fun yín |