Quran with Yoruba translation - Surah Al-Anfal ayat 11 - الأنفَال - Page - Juz 9
﴿إِذۡ يُغَشِّيكُمُ ٱلنُّعَاسَ أَمَنَةٗ مِّنۡهُ وَيُنَزِّلُ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ لِّيُطَهِّرَكُم بِهِۦ وَيُذۡهِبَ عَنكُمۡ رِجۡزَ ٱلشَّيۡطَٰنِ وَلِيَرۡبِطَ عَلَىٰ قُلُوبِكُمۡ وَيُثَبِّتَ بِهِ ٱلۡأَقۡدَامَ ﴾
[الأنفَال: 11]
﴿إذ يغشيكم النعاس أمنة منه وينـزل عليكم من السماء ماء ليطهركم به﴾ [الأنفَال: 11]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Rántí) nígbà tí (Allāhu) ta yín ní òògbé lọ (kí ó lè jẹ́) ìfọ̀kànbalẹ̀ (fun yín) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó tún sọ omi kalẹ̀ fun yín láti sánmọ̀ nítorí kí Ó fi lè fọ̀ yín mọ́ (pẹ̀lú ìwẹ̀ ọ̀ran-anyàn), àti nítorí kí Ó fi lè mú èròkerò Èṣù (bí àlá ìbálòpò ojú oorun) kúrò fun yín àti nítorí kí Ó lè kì yín lọ́kàn àti nítorí kí Ó lè mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin |