Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 101 - التوبَة - Page - Juz 11
﴿وَمِمَّنۡ حَوۡلَكُم مِّنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مُنَٰفِقُونَۖ وَمِنۡ أَهۡلِ ٱلۡمَدِينَةِ مَرَدُواْ عَلَى ٱلنِّفَاقِ لَا تَعۡلَمُهُمۡۖ نَحۡنُ نَعۡلَمُهُمۡۚ سَنُعَذِّبُهُم مَّرَّتَيۡنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٖ ﴾
[التوبَة: 101]
﴿وممن حولكم من الأعراب منافقون ومن أهل المدينة مردوا على النفاق لا﴾ [التوبَة: 101]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. O ò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì. Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá |