Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 40 - التوبَة - Page - Juz 10
﴿إِلَّا تَنصُرُوهُ فَقَدۡ نَصَرَهُ ٱللَّهُ إِذۡ أَخۡرَجَهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ثَانِيَ ٱثۡنَيۡنِ إِذۡ هُمَا فِي ٱلۡغَارِ إِذۡ يَقُولُ لِصَٰحِبِهِۦ لَا تَحۡزَنۡ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَنَاۖ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَيۡهِ وَأَيَّدَهُۥ بِجُنُودٖ لَّمۡ تَرَوۡهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلسُّفۡلَىٰۗ وَكَلِمَةُ ٱللَّهِ هِيَ ٱلۡعُلۡيَاۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ ﴾
[التوبَة: 40]
﴿إلا تنصروه فقد نصره الله إذ أخرجه الذين كفروا ثاني اثنين إذ﴾ [التوبَة: 40]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.1 Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa."2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ ò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun l’ó sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n |