Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 70 - التوبَة - Page - Juz 10
﴿أَلَمۡ يَأۡتِهِمۡ نَبَأُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَقَوۡمِ إِبۡرَٰهِيمَ وَأَصۡحَٰبِ مَدۡيَنَ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتِۚ أَتَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ فَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ﴾
[التوبَة: 70]
﴿ألم يأتهم نبأ الذين من قبلهم قوم نوح وعاد وثمود وقوم إبراهيم﴾ [التوبَة: 70]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣé ìròyìn àwọn t’ó ṣíwájú wọn kò tì í dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí t’ó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí |