Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 69 - التوبَة - Page - Juz 10
﴿كَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ كَانُوٓاْ أَشَدَّ مِنكُمۡ قُوَّةٗ وَأَكۡثَرَ أَمۡوَٰلٗا وَأَوۡلَٰدٗا فَٱسۡتَمۡتَعُواْ بِخَلَٰقِهِمۡ فَٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِخَلَٰقِكُمۡ كَمَا ٱسۡتَمۡتَعَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُم بِخَلَٰقِهِمۡ وَخُضۡتُمۡ كَٱلَّذِي خَاضُوٓاْۚ أُوْلَٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ ﴾
[التوبَة: 69]
﴿كالذين من قبلكم كانوا أشد منكم قوة وأكثر أموالا وأولادا فاستمتعوا بخلاقهم﴾ [التوبَة: 69]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí dà) gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín; wọ́n le jù yín lọ ní agbára, wọ́n sì pọ̀ (jù yín lọ) ní àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Nígbà náà, wọ́n jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn (nínú oore ayé). Ẹ̀yin (ṣọ̀bẹ-ṣèlu wọ̀nyìí náà yóò) jẹ ìgbádùn ìpín tiyín gẹ́gẹ́ bí àwọn t’ó ṣíwájú yín ṣe jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn. Ẹ̀yin náà sì sọ̀sọkúsọ bí èyí tí àwọn náà sọ ní ìsọkúsọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni ẹni òfò |