Quran with Yoruba translation - Surah Ibrahim ayat 21 - إبراهِيم - Page - Juz 13
﴿وَبَرَزُواْ لِلَّهِ جَمِيعٗا فَقَالَ ٱلضُّعَفَٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعٗا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا مِنۡ عَذَابِ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۚ قَالُواْ لَوۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُ لَهَدَيۡنَٰكُمۡۖ سَوَآءٌ عَلَيۡنَآ أَجَزِعۡنَآ أَمۡ صَبَرۡنَا مَا لَنَا مِن مَّحِيصٖ ﴾
[إبراهِيم: 21]
﴿وبرزوا لله جميعا فقال الضعفاء للذين استكبروا إنا كنا لكم تبعا فهل﴾ [إبراهِيم: 21]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Gbogbo ẹ̀dá sì máa jáde sọ́dọ̀ Allāhu (lọ́jọ́ Àjíǹde). Nígbà náà, àwọn aláìlágbára yóò wí fún àwọn t’ó ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fun yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé n̄ǹkan kan kúrò fún wa nínú ìyà Allāhu?” Wọn yóò wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tọ́ wa sọ́nà ni, àwa ìbá tọ yín sọ́nà. Bákan náà sì ni fún wa, yálà a káyà sókè tàbí a ṣàtẹ̀mọ́ra (ìyà); kò sí ibùsásí kan fún wa.” |