Quran with Yoruba translation - Surah An-Nahl ayat 125 - النَّحل - Page - Juz 14
﴿ٱدۡعُ إِلَىٰ سَبِيلِ رَبِّكَ بِٱلۡحِكۡمَةِ وَٱلۡمَوۡعِظَةِ ٱلۡحَسَنَةِۖ وَجَٰدِلۡهُم بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَن ضَلَّ عَن سَبِيلِهِۦ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ ﴾
[النَّحل: 125]
﴿ادع إلى سبيل ربك بالحكمة والموعظة الحسنة وجادلهم بالتي هي أحسن إن﴾ [النَّحل: 125]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Pèpè sí ojú ọ̀nà Olúwa rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì s.a.w.) àti wáàsí rere. Kí o sì jà wọ́n níyàn pẹ̀lú èyí t’ó dára jùlọ. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà Rẹ̀ (’Islām). Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà (àwọn mùsùlùmí) |